Ó lé ní aláwọ̀ dúdú 39 tí mo ti pa, fúnra mi ni mo sì ń sọ fún ọlọ́pàá pé mo ti pààyàn

Àkọlé fídíò, Louis van Schoor: Apààyàn ọmọ ilẹ̀ South Africa tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ṣọ nípa àtubọ̀tán rẹ̀
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Ọmọ orilẹ-ede South Africa kan, Louis van Schoor, ẹni to pa ọpọ eeyan dudu lasiko ogun ẹlẹyamẹya ni South Africa(apartheid), ti jẹwọ pe awọn ọlọpaa kun oun lọwọ lasiko naa toun fi pa eeyan dudu rẹpẹtẹ.

Louis van Schoor, ṣalaye fun BBC Africa Eye pe oun nikan kọ loun jẹbi ipaniyan ọhun, eyi to waye lasiko toun n ṣiṣẹ ọlọdẹ. Ọkunrin naa tu awọn aṣiri ikọkọ nipa ohun to ṣelẹ si i lati bii ọdun mẹrin sẹyin, ati bi wọn ṣe tete tu u silẹ lọgba ẹwọn.

Nigba to n ṣalaye ipaniyan naa fun akọroyin BBC ninu yara rẹ, ibusun Van mọ tonitoni, aṣọ to tẹ le e lori si wuyi bii pe wọn fi aayọọnu lọ ọ ni. Oorun siga gba gbogbo yara naa kan.

Apaayan ti wọn n pe ni “Apartheid Killer” yii ko ni eyin lẹnu mọ, alaafia rẹ si ti n di fiafia. Lẹyin aisan ọkan to ṣe e,aipẹ yii ni wọn ge ẹsẹ rẹ mejeeji, o si di eni to n jokoo lori aga awọn eeyan ti ko le fi ẹsẹ rin mọ, àpá oriṣiiriṣii si kun ara rẹ pẹlu.

Nigba ti wọn n ge ẹsẹ Van, o ni oun fẹẹ maa ri i bi wọn ṣe n ge ẹsẹ ọhun, ki wọn ma lo ilana mi-in foun.

“ Mo fẹẹ wo bi wọn ṣe n ṣe, mo ri i bi wọn ṣe n ge, wọn ge e gba inu egungun ni.”

Bo ṣe n ba BBC sọrọ, Van Schoor n rọ wa, pe ka jẹ kaye mọ pe oun ki i se ẹhanna tawọn eeyan ro pe oun jẹ.

Van Schoor
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O kere tan, eeyan mọkandinlogoji (39) ni Van Schoor pa lasiko apartheid ni nnkan bii 1980 sisalẹ. Apartheid ni ofin kan to gbe awọn alawọ funfun ọmọ South Africa bori awọn dudu, eeyan dudu si ni gbogbo awọn to pa.

Ọmọ to kere ju ninu awọn to pa nigba naa jẹ ọmọ ọdun mejila. Ila-Oorun London lo ti pa ọmọ naa, iyẹn ni ilu kan to wa lagbegbe Eastern Cape, ni South Africa.

Iṣẹ ọlọdẹ ni Van Schoor n ṣe nigba naa, wọn si ti fun un laṣẹ lati da aabo bo ida aadọrin (70% ) ileeṣẹ awọn eeyan funfun ni South Africa. Awọn bii ile ounjẹ wọn,ile itaja , ileewe ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Fun ọdun pipẹ lo ti maa n sọ pe ọdaran ni awọn eeyan toun n pa naa. Van yoo sọ pe oun mu awọn eeyan naa ṣinkun nibi ti wọn ti n fọ ṣọọbu itaja tabi ieeṣẹ awọn eeyan funfun loun ṣe mu wọn balẹ.

“ Ka ṣaa sọ pe apaayan fijilante ni, iwa rẹ ko mọ rara’’ Bẹẹ ni akọroyin South Africa kan, Isa Jacobson, to ti fi ogun ọdun wadii Van sọ nipa apaayan naa.

“ Awọn ole kee-kee-ke ti wọn n wa ohun ti wọn maa jẹ nibi ile-ilẹ kaakiri, to ṣee ṣe ki wọn ji ounjẹ diẹ lawọn wọnyi. Alafọwọra pẹẹ-pẹẹ-pẹ ni Van sọ di ọdaran to n pa’’

Louis van Schoo, ọmọ orilẹede South Africa ti wọn lo jẹbi ẹsun ipaniyan rẹpẹtẹ.
Àkọlé àwòrán, Louis Van Schoo, ọmọ orilẹede South Africa ti wọn lo jẹbi ẹsun ipaniyan rẹpẹtẹ.

Van funra rẹ̀ lo maa n lọọ sọ fun awọn ọlọpaa pe oun ti paayan

Ipaniyan Van Schoor: Ẹru jẹjẹ ti i ba ọmọ adugbo ni ọkunrin yii, torutoru ni iroyin sọ pe o fi maa n mu awọn eeyan balẹ. Asiko kan wa ni East London, ti wọn maa n bẹru ọkunrin kan ti wọn n pe “whiskers”, oru ni wọn lo maa n gbe awọn eeyan lọ ti wọn yoo di awati. Ṣugbọn ibọn yinyint tiẹ ki i ṣe bonkẹlẹ, yoo yinbọn ti gbogbo ilu yoo gbọ ni.

Gbogbo ipaniyam ti Van ṣe laarin ọdun 1986 si 1989, funra rẹ ni yoo gba agọ ọlọpaa lọ ti yoo sọ fun wọn pe oun ti paayan bii iṣe oun.

Ṣugbọn bi wọn ṣe fi ajijagbara nni, Nelson Mandela to korira apatheid silẹ lẹwọn lo gba agbara lọwọ Van to n paayan kiri.

Atẹgun alaafia bẹrẹ si i fẹ pada kaakiri South Africa, pẹlu igbiyaju awọn ajijagbara ati awọn oniroyin ti wọn ko fi apaayan naa lọrun silẹ, wọn mu Van Schoor lọdun 1999.

Igbẹjọ Van Schoor ni kootu jẹ ọkan lara awọn ẹjọ to le ju lori ipaniyan ni South Africa, ijẹrii tako pọ lọtun-un- losi pẹlu awọn ẹri imọ ijinlẹ to n tọka bo ṣe pa awọn eeyan naa.

Ṣugbọn o, ẹjọ rẹ naa pada fori ṣanpọn ni. Eyi ri bẹẹ nitori ọwọ awọn alagbara Aparthied ṣi wa ninu eto idajọ orilẹede naa. Bi Van ṣe ti pa to eeyan 39 to, meje pere ni wọn lo jẹbi ẹ ninu ipaniyan naa.

Ọdun mejila pere ni wọn si paṣẹ pe ko lọọ lo lẹwọn.

Ẹsun ipaniyan mejilelọgbọn to ku nkọ, awọn ọlọpaa sọ pe ko jẹbi awọn iyẹn labẹ ofin. Ofin Apartheid igba naa faaye silẹ fawọn eeyan lati lo nnkan ija fun arufin to ba fẹẹ sa lọ, tabi eyi ti ko fẹẹ gba ki wọn mu oun.

Ori ohun ti Van Schoor naa si duro le ree, o ni awọn toun pa fẹẹ sa lọ loun ṣe fibọn mu wọn balẹ lori ere.

Iwadii BBC lori ọrọ Van Schoor, tan imọlẹ si ohun ti awọn ọlọpaa wi, pe o le yinbọn si afurasi to ba fẹẹ sa lọ.

Iṣẹ iwadii waye lorii bi wọn ṣe yinbọn, awọn ẹsun iru ẹ to ti pẹ lọdọ awọn ọlọpaa, ayẹwo oku ati ẹri awọn ẹlẹrii.

Isa Jacobson, akọroyin lo lewaju iwadii yii, ọpọ ọdun ni wọn fi ṣe e kaakiri awọn ilu ni Eastern Cape. Ọpọlọpọ awọn iwe ati akọsilẹ to le tuṣu aṣiri yii de isalẹ koko ni wọn ko pamọ sinu awọn pako ati sawọn ajaalẹ kaakiri.

Louis van Schoor lẹyin ọkọ.

Lara awọn ẹri to pa ni lẹkun ti akọroyin Isa Jacobson yii ri, ni ti ọrọ ti awọn eeyan ti Van kọlu sọ,iyẹn awọn to gbiyanju lati pa ṣugbọn ti wọn ko ku.

Awọn akọsilẹ yii tako ohun ti Van sọ, pe wọn fẹẹ maa sa lọ loun ṣe yinbọn fun wọn.

Ọpọ eeyan lo sọ pe lasiko tawọn ti kawọsoke, tawọn ko janpata rara ni Van yinbọn fawọn.

Awọn kan sọ pe niṣe lo tiẹ n mu awọn ṣere, to n beere pe ṣe koun yinbọn pa wọn lẹsẹkẹsẹ ni abi koun mu wọn ṣinkun, ko too yinbọn mọ wọn laya.

Ẹlomi-in ti Van yinbọn mọ nibi idodo, ṣalaye pe oun bẹ ẹ pe ko fun oun lomi mu. Ẹni naa sọ pe niṣe lo gba oun nipa nibi ikun naa.

Ibọn ilewọ to gun niwọn mẹsan-an ni Van Schoor ni, atamatase to le yin nigbakigba ni. Gbogbo igba ni ọta maa n wa ninu rẹ, eyi to maa n fa a to fi maa n fa eeyan ya to ba wọle si ara ẹnikẹni.

Igba kan wa ti Van yin ibọn yii lẹẹmẹjọ si ọkunrin kan ti ko ni nnkan aabo kankan lara.

Lọjọ kọkanla, oṣu keje ọdun 1988, ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹrinla kan wọ ile ounjẹ lati tọrọ owo, Van yinbọn lu u, ọmọ naa sare wọ ile igbọnsẹ lọ ni, bo ṣe ṣalaye .

O ni Van pe oun jade, o paṣẹ pe koun duro si ẹgbẹ ogiri, o si yinbọn lu oun leralera.

“O ni ki n dide, ṣugbọn mi o le dide. Nigba ti mo dubulẹ yẹn, o gba mi ni ipa lẹnu. O gbe mi soke, o jan mi mọ tabili to wa nitosi, o si yinbọn fun mi lẹẹkan si i” Bẹẹ ni ọmọdekunrin naa ṣalaye ninu akọsilẹ rẹ to ṣe fawọn ọlọpaa.

Akọroyin South Africa, Isa Jacobson ree nibi to ti n tu awọn iwe to n tọpinpin Van Schoor. O ti lo ọpọlọlọpọ ọdun lati wadii apaaya naa
Àkọlé àwòrán, Akọroyin South Africa, Isa Jacobson ree nibi to ti n tu awọn iwe to n tọpinpin Van Schoor. O ti lo ọpọlọlọpọ ọdun lati wadii apaaya naa

Ọmọ naa ye, ṣugbọn wọn ko gba a gbọ. Wọn fẹsun ole jija kan an. Pupọ awọn ọdọkunrin bii eyi ni wọn koju iru iṣoro yii lọwọ Van Schoor.

Bi wọn ba gbe ẹjọ de kootu, adajọ yoo da ẹri awọn ẹlẹrii nu, yoo ni oju wọn dudu, wọn o mọ ohun to n lọ. Adajọ miran yoo sọ pe ẹri naa ko fẹsẹ mulẹ, yoo si da ẹjọ naa nu.

Ko si igbẹjọ ni South Africa nigba naa, ohun ti adajọ ba sọ ni abẹ ge.

Lasiko igbẹjọ Van Schoor, ọpọ eeyan ni East London lo wa lẹyin rẹ. Koda, ọkunrin oniṣowo kan tẹ iwe pelebe to ya Van si, to si kọ ọ sibẹ pe oun nifẹẹ rẹ. O o ya ọkan kan ti wọn ti fibọn lu iho si, si ara iwe pelebe naa.

“ Patrick Goodenough, akọroyin South Africa kan to lewaju igbẹjọ Van Schoor laarin 1980, sọ pe, “ Awọn eeyan wa lẹyin rẹ bajẹ, ko ba ma mu awọn iwa rẹ yii jẹ bi ko ba si ero rẹpẹtẹ to n ti i lẹyin ni.”

Ko sohun to n da awọn ọlọpaa duro bayii ti wọn o fi le bẹrẹ ẹjọ Van yii pada, to ba jẹ pe ofin fẹsẹ mulẹ ni South Africa ni.

“Louis Van Schoor pa awọn eeyan fun pe wọn n lọọ wo ere idaraya’’ Dominic Jones, akọroyin kan lo sọ bẹẹ lasiko ti ipaniya Van kọja bẹẹ .

Van funra ẹ ti ṣe awọn ifọrọwanilẹnuwo kan ri to fidi ẹ mulẹ pe o gbadun ipaniyan. Iwadii BBC fidi eyi mulẹ lati ara awọn ifọrọwerọ naa.

“ Alẹ kan, àrà kan ni,’’ Van Schoor lo sọ bẹẹ fun BBC.

Apartheid jẹ asiko ẹlẹyamẹya ni South Africa

'Òórùn ara èèyàn ni mo fi máa n mú wọn'

Akawe ohun to ṣẹlẹ

Pupọ ninu awọn ieeṣẹ ti Van n ṣọ ni wọn fi agogo ikede sinu ile itaja wọn. Bi ẹnikan ba wọle, olobo yoo ta Van pẹlu aago naa ti yoo dun, yoo si le yọju si ole naa, yoo si tun mọ ibi ti ẹni ọhun duro si gan-an.

“ Mi o wọ bata, gbogbo agbegbe si pa lọlọ, eeyan ki i wọ bata ko waa maa pariwo. Bi eeyan kan ba wọle, mo maa gbọ oorun ara rẹ, mo si le gbabẹ mu un’’ Van Schoor lo ṣalaye ara rẹ bẹẹ.

Ki i tan ina, kaka bẹẹ, oorun lo maa n gbọ to fi maa n mu ẹni to ba fẹẹ mu.

Van ni ki i ṣe pe oun maa n ni aniyan lati pa awọn eeyan dudu, oun ko si ki i kopa ninu ẹlẹyamẹya.O ni ṣugbọn oun fẹran lati maa fi okunkun boju mu wọn balẹ.

Ko too di ọlọdẹ, ọlọpaa ni Van Schoor fọdun mejila ni East London. Iṣẹ kan to pe ni “attacker dogs”, lo ni oun maa n ṣe, eyi to fi maa n pa awọn to ba n fi ẹhonu han, ọpọ awọn to si n pa naa ni wọn jẹ eeyan dudu.

Ọlọpaaa to n lo aja ni Van n ṣe tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Louis van Schoor

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaaa to n lo aja ni Van n ṣe tẹlẹ

Awọn ọlọpaa mọ ohun to n ṣẹlẹ, ṣugbọn wọ ko mu Van

Tetinene “Joe” Jordan, ajafẹtọọ ọmọniyan nigba kan ni South Africa to n gbiyanju lasiko ti Van n ṣoro bii aggbọn, sọ pe oun ranti ipaniyan rẹ gidi.

“ O n ṣọdẹ ni, ka ṣaa sọ pe ọdẹ eeyan lo n ṣe ni tiẹ.’’ Tetine lo sọ bẹẹ.

Ṣugbọn Van Schoor funra rẹ loun ki i ṣe apaayan bẹẹ yen naa, o ni gbogbo ohun toun ṣe lo wa ni ibamu ‘labẹ ofin’.

Bi wọn yoo ba ba ẹnikẹni wi lori iwa ti Van hu, Tetinene sọ pe awon ọlọpaa South Africa lo yẹ ki wọn ba wi. O ni awọn ọlọpaa ko ba a wi ri, wọn ko si mu un, ṣugbọn wọn n ti i lẹyin, wọn si n ni ko maa jo lọ, awọn n wo ẹyin rẹ.

.

“ Gbogbo ọlọpaa East London lo mọ ohun to n ṣẹle nigba naa, ko sẹnikan bayii to ni ’Louis, o ti n kọja aaye rẹ o, abi ṣe jẹjẹ o.’’ Tetinene lo sọ bẹẹ nipa iwa awọn ọlopaa ibẹ.

Ọpọ igba ni awọn ọlọpaa ko ya foto awọn ti Van pa, wọn ko ya fọto ibi iṣẹlẹ naa, wọn ko si ṣe ayewo oku wọn. Van nikan naa lo maa n jẹ ẹlẹrii nibi ipaniyan rẹ.

“ Apaayan to ti sọ ọ di iṣẹ ni Van Schoor, nitori awujọ gba a laye lati ṣe bẹẹ” Isa Jacobson lo sọ eyi di mimọ.

Fun awọn ẹbi awon eeyan ti Van Schoor pa, bi wọn ko ṣe fiya jẹ ẹ labẹ ofin jẹ nnkan ibanujẹ

.

“ O ba wa lọkan jẹ, o dun wa, o bi wa ninu” obinrin kan, Marlene Mvumbi, ti Van pa ẹgbọn rẹ ọkunrin lo sọrọ yii. Van Schoor lo pa ọkunrin naa, Edward, ni 1987.

O ju oku rẹ sinu iboji kan lai si aṣẹ ijoba abi ti ẹbi rẹ.Ọpọlọpọ eeyan la ṣi n wa, wọn o si si ninu saaree, ko sibi ti a le wa wọn si.’’

Van funra ẹ jewọ pe oun gbadun iwa to n hu naa, o ti waa pada di eni ti ko le rin mo bayii
Àkọlé àwòrán, Van funra ẹ jewọ pe oun gbadun iwa toun n hu naa, o ti waa pada di eni ti ko le rin mo bayii

''Mi o kabamọ ipaniyan gbogbo to ti ọwọ mi wa''

Ẹwọn to le ni aadọrun-un (90) ọdun ni wọn ju Van Schoor si nibi idajọ rẹ to waye ni 1992, ṣugbọn adajọ ni ẹẹkan naa ni yoo ṣe gbogbo ẹwọn naa. Ọdun 2004 ni wọn fi i silẹ pẹlu awọn adehun ati ọrọ ajọsọ kan.

Ki won maa tete fi awọn eeyan to pa eeyan rẹpẹtẹ lasiko Aparthied silẹ bayii ni South Africa jẹ nnkan ti wọn ti n sọrọ lori rẹ tipẹ.

Ni 2022, iwọde kan waye ni Johannesburg, nipa bi wọn ṣe yọnda Janusz Walus, to pa oloṣelu kan to n korira Apartheid, iyẹn Chris Hani.

Bakan naa ni wọn ṣe yọnda Eugene de Kock, ẹni ti wọn lo mọ nipa iku ọpọ eeyan ati ijinigbe, to tun maa n fiya jẹ wọn, ṣugbọn kootu yọnda rẹ pe ko maa lọ.

Lasiko yii, Van Schoor ni tiẹ ko ni ohun to n fi asiko rẹ ṣe ju ko maa wo ere idaraya rugby, ko maa mu siga ko si maa ba aja rẹ ṣere. O loun ko ranti pupọ ipaniyan to ti ọwọ oun wa mọ.

Awọn akọsilẹ kan ti ko ṣee fidi rẹ mulẹ, sọ pe o yinbọn fun eeyan to to ọgọrun-un. Bo tile jẹ pe Van sọ pe irọ ni eyi, o gba pe awọn toun pa ju mọkandinlogoji to wa lakọsile lọ.

“ Ni tododo, mi o ranti iye eeyan ti mo yinbọn fun mọ. Awọn kan sọ pe o ju ọgọrun-un lọ, awọn kan sọ pe o ju ogoji lọ. Ṣugbon ka ṣaa sọ pe mo yinbọn fun eeyan aadọta (50). Van lo sọ bẹẹ fun BBC.

O ni iwuri ni iwa oun atijọ naa ṣi n jẹ foun.

“ Mi o ri ara mi bii eni to jẹbi, ko si idalẹbi tabi abamọ kankan ninu ọkan mi”

BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaaa South Africa lati gbọ ti ẹnu wọn lori ọrọ yii, ṣugbọn wọn ko da wa lohun.

Awon alaṣẹ ko sọ idi kan lori idi ti wọn ko ṣe gbe ejọ ipaniyan Van Schoor’ dide pada.

“ Inira pọ lọkan mi, mi o si ro pe wọn ṣe ohunkohun to le mu ọgbẹ ọkan wa jinna mọ” Marlene Mvumbi ti Van pa ẹgbọn rẹ lo sọ bayii.

“Ki i ṣe awọn ti Van Schoor pa nikan niṣẹlẹ yii da le lori, pelu awon mi-in naa ti wọn ku iru iku yii lasiko Apartheid, lasiko ti ẹlẹyamẹya gbokun ni South Africa.”

Isa Jacobson ati Charlie Northcott ni wọn ṣe iwadii yii.