Kí ló ń fa èdè àìyedè láàrín Dangote àti NNPC lórí ọ̀rọ̀ epo?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si n jẹ ọrọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo ni Naijiria, NNPC lẹnu.
Bi ẹnu ṣe n kun NNPC, naa lo n kun alaga ileeṣẹ Dangote Group, Aliko Dangote.
Fakinfa naa ko ṣẹyin ọrọ epo bẹntiro to di ọwọngogo ni Naijiria ati akitiyan ileeṣẹ Dangote lati bẹrẹ si n ta epo naa laipẹ yii.
Ṣaaju ni dangote ti kọkọ sọ pe ileeṣẹ oun yoo bẹrẹ si n ta epo ko to di idaji ọdun 2024 ti a wa yii amọ erongba rẹ ko bọ si.
Oniruru ipenija ni Dangote koju lọna ati ṣaṣeyọri lati bẹrẹ si n ta epo naa, lara rẹ ni bo ṣe sun ọjọ ti yoo bẹrẹ si ni ta epo siwaju ati bi ijamba ina kan se sọ nileeṣẹ naa.
Amọ ipenija to ga ju ni ariyanjiyan kan to n waye laarin rẹ ati ilee to n se akoso epo bi ni wa, NNPC lọwọ yii.
Bakan naa ni ọrọ kan to n lọ nigboro pe epo ti ileeṣẹ Dangote n fọ ko dara to eyi ti wọn n ko wọle lati oke okun.
Iye ipin idokowo meloo ni ajọ NNPC ni nileeṣẹ Dangote?
Lọjọ ti wọn ṣi ileeṣẹ ifọpo adani naa ni Dangote kede pe ida ogun ninu ọgọrun (20%) ipin idokowo ileesẹ naa ni ajọ NNPC ni.
Amọ iyalẹnu lo tun jẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria nigba ti iroyin kan tun jade pe iye ipin idokowo ti ajọ NNPC ni nileeṣẹ naa ti dinku bayii lati ida ogun ninu ọgọrun si ida meje ati diẹ ninu ọgọrun 7.2%.
Nibi ipade awọn akọroyin kan ni Dangote funra rẹ ti sọ ọrọ naa nibi to ti sọ pe eyii waye latari pe NNPC ko san iye owo to yẹ ko san lasiko lati ni iye ipin idokowo ti wọn fẹnuko si tẹlẹ.
Ṣaaju ni NNPC ti kọkọ ra ipin idokowo ida ogun ninu ọgọrun 20% ileeṣẹ naa pẹlu owo ti iye rẹ to $2.76b.
"Ojulowo epo lo n wa lati ileeṣẹ mi, ọpọ epo ti ko dara ni wọn n ko wọ Naijiria lati oke okun"
Lara awọn iroyin mii to n ja rainrain ni pe epo ti Dangote yoo ta faralu ko dara, ati pe tita epo naa jẹ ọna lati jẹ gaba lori gbogbo awọn to n ta epo, ni Dangote n wa.
Ṣugbọn lasiko ti awọn aṣaaju ile aṣojuṣofin ṣabẹwo sileeṣẹ naa to wa lagbegbe Lekki Free Trade Zone, niluu Eko, Dangote ni ọrọ naa ko ri bẹẹ rara.
Lọna ati fidi rẹ mulẹ pe epo ileeṣẹ naa jẹ olulowo, Dangote ṣayẹwo epo diesel ti wọn ra nile epo meji ọtọtọ ati eyii ti wọn fọ nileeṣẹ rẹ ninu laabu, lati ṣafihan pe oun ko ni ta ayederu epo faraalu.
Lẹyin ayẹwo epo mejeji, o ni ojulowo epo ni yoo wa lati ileeṣẹ oun ati pe ọpọ epo ti ko dara ni wọn n ko wọ Naijiria lati oke okun.
“Mo ṣetan lati ta ileesẹ mi fun NNPC lati maa dari”
Wayi o, iroyin to n tẹ wa lọwọ ti sọ pe Dangote ti ni oun ti ṣetan lati ta ileesẹ naa fun NNPC lẹyin awọn awuyewuye to n waye laarin awọn mejeji.
leeṣẹ iroyin Premium Times jabọ pe Dangote lo sọ ọrọ naa fun oun ninu ifọrọwerọ kan.
Iroyin naa ni Dangote sọ pe “jẹ ki wọn kuku ra ileeṣẹ naa ki wọn maa dari rẹ bi wọn ba ṣe fẹ.
“Wọn kuku ti pe mi ni ẹni to fẹ jẹ gaba le gbogbo ileeṣẹ epo mii lori, ko si wahala....”
“Lati ibẹrẹ ọdun 1970 lati n dojukọ kọ iṣoro epo, ileeṣẹ ifọpo wa le ran ijọba lọwọ lati yanju isoro naa ṣugbọn o da bii pe inu awọn kan ko dun bo ṣe jẹ pe emi ni mo wa ni ipo lati yanju rẹ.
“Mo ṣetan lati fi gbogbo rẹ silẹ, ki NNPC kuku ra ileeṣẹ naa ki wọn si maa dari rẹ bi wọn ṣe fẹ.
Ta ni Aliko Dangote, to kọ ileesẹ afọpo aladani?
Ọmọ Naijiria lati iha ariwa ni Dangote, o si jẹ oniṣowo to gbajumọ kaakiri agbaye.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 1957 ni wọn bi ni ipinlẹ Kano.
Dangote ni ọpọlọpọ ileeṣẹ to n ta nnkan jijẹ ati nnkan ikọle bii spaghetti, ṣuga, simẹnti, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Yatọ si pe o jẹ oniṣowo, Dangote tun jẹ oloju aanu to maa n fi owo rẹ ran awọn alaini lọwọ.
Ọkunrin ọhun jẹ ọkan lara awọn ọmọ ilẹ adulawọ to lowo julọ lagbaye.














