Àwọn agbébọn ṣekúpa àgùnbánirọ̀, awakọ̀, jí èèyàn márùn-ún míì gbé lọ l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ajinigbe ti gbẹmi agunbanirọ kan ati awakọ ọkọ ero kan ninu ikọlu ti o waye ni opopona marose Ifon si Ilu Owo nipinlẹ Ondo.
Agbegbe yi jẹ ọkan lara ibi ti awọn ajinigbe ti maa n sọsẹ ju nipinlẹ Ondo.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, SP Fumilayo Odunlami-Omisanya lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun akọroyin BBC, to si tun fikun pe awọn ajinigbe naa tun ko awọn ero ọkọ marun un lọ.
Odunlami-Omisanya ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ko tii le sọ ni pato iye awọn eeyan ti awọn agbebon naa ji gbe lọ lapapọ.
Alukoro ọlọpaa fi kun pe awọn ọlọpaa ti kan lu igbo bayii lati ṣawari awọn eeyan ti wọn jigbe ni kia kia.
Iwadii BBC Yoruba ṣafihan rẹ pe awọn agbebọn yinbo pa ọdọmọbirin agunbanirọ kan ati awakọ lasiko ti wọn ṣakọlu si ọkọ ero naa
Iwadii mii tun fihan pe eeyan meji lara awọn ero ọkọ naa moribọ, ti wọn si sa asala fun ẹmi wọn pẹlu oniruru ọgbẹ lara wọn.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣalaye rẹ pe lati ipinlẹ Anambra ni ọkọ ero naa ti n bọ ti wọn si n lọ si ilu Owo ati Akure ki awọn agbebọn ọhun to kọlu wọn lalẹ ọjọ Ẹti.
Ijinigbe nipinlẹ Ondo
Isẹlẹ ijinigbe nipinlẹ Ondo lo ti di nnkan to n waye loorekoore lati bi ọdun melo kan sẹyin bayii.
Lọdun 2022, Ọba ilu atawọn mẹta kagbako ajinigbe, ti ibọn si tun ba awakọ wọn.
Bakan naa ni ọwọ tẹ ọdọkunrin kan ninu oṣu Kini ọdun 2024, Usman Bello, ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn, to mura bi ẹni to n ṣa ilẹ nibi to ti ji ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹjọ kan gbe nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.
Ọkunrin afurasi naa ni wọn wi pe o gbe ọmọdebinrin naa sinu apo to n ṣalẹ si to si fẹẹ maa gbe e lọ.
Ninu oṣu Karun un ni awọn ajinigbe kan kọlu ọkọ akero kan ni opopona Akoko/Imesi ti wọn si ji ọpọ eeyan gbe lọ nipinlẹ Ekiti to wa lẹba ipinlẹ Ondo yii kan naa.
Awọn ero ọkọ bọsi elero mejidinlogun yii lo n ti ode kan bọ ni ipinlẹ Ekiti ti wọn si n pada si Ikare nipinlẹ Ondo nigba ti awọn ajinigbe yii kọlu wọn.
Pupọ ninu awọn eeyan ti wọn ji gbe yii lo jẹ alase ti wọn lọ sode lati lọ dana.















