Wo ìdí tí ìyàwó fi ráńṣẹ́ pe àwọn Amotekun láti dáná ìyá jẹ fún ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ọrọ pesi jẹ fun Afeez Olayemi, ẹni to dero ile iwosan nigba ti awọn ikọ Amotekun kan dana iya jẹ fun nipinlẹ Osun.
Agbegbe Fakunle niluu Osogbo ni Afeez Olayemi ati Kehinde Aroyehun to jẹ iyawo rẹ ati oṣiṣẹ Amotekun n gbe .
Ọjọ Karundinlogbon osu Kẹfà ọdun 2024 ni isẹlẹ naa waye ti Olayemi ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi eyi to jẹ mọni gbagbe nitori o jẹ ohun to ka laya pupọ.
O ṣalaye fun BBC pe oun ati iyawo rẹ ni ede ayede laarin ara wọn, eyi to mu ki iyawo mi pe iya rẹ wa.
“Iyawo mi lo pe iya rẹ wa sile mi, ti iya iyawo mi fi fi eyin dara si mi lara gidigidi nitori mo ba ọmọ rẹ to jẹ iyawo mi wi.
Kaka ki iya iyawo ko bere oun to sẹlẹ laaarin emi ati iyawo mi sugbọn wọn ko se bẹ eyin ni wọn gbe pade mi ti wọn si bu mi jẹ yannayanna lara.
Afeez tun fi ku ọrọ wi pe, ọjọ Keji isẹlẹ naa ni ọkan lara ẹgbọn iyawo rẹ ti oruko rẹ n jẹ Omolara lo pe awọn ẹbi oun, to si fi ohun silẹ wi pe awọn ma ri wahala.
Ki lo fa ti awọn Amotekun se fi iya jẹ Olayemi?
Olayemi ni ọga oun lo ran oun lọ si ile ifowopamọ kan, to jẹ pe ṣadede ni ọkọ awọn Amotekun duro si ẹgbẹ rẹ, ti wọn si ni ko wọ inu ọkọ wọn.
O sọ fun BBC pe oun bẹrẹ pe kinni ẹsẹ oun ati wi pe ki wọn gba oun laya lati sọ fun awọn akẹgbẹ oun pe Amotekun lo gbe oun lọ tabi ki wọn jẹ ka ki awọn lọ si ofisi wọn to wa ni tosi.
Olayemi ni oun o ti sọrọ tan ti awọn Amotekun se bẹrẹ si ni naa oun ti wọn gba oun leti ati oju titi oun ko fi le sọrọ mọ. O ni koda, apa iya naa wa lara oun bayi.
“Awọn iya lọja to wa ni agbegbe naa pe awọn Ọlọpaa, to si jẹ pe awọn Ọlọpaa lo gbe mi kuro lọ si ofisi wọn lati ofisi wọn ni wọn ti gbe oun lọ si ile Iwosan kan nibẹ ni oun tí gba itọju. “
Olayemi tẹsiwaju pe, awọn Amotekun ko ṣẹṣẹ ma fi iya jẹ oun.
“Lati aye Ọga wọn Shittu Amitolu ni wọn ti fi iya jẹ mi nitori iyawo mi to jẹ ọkan lara wọn.
“Awọn Amotekun ti sa mi lada, wọn tun fi ogun na mi, ko da gbogbo apa iya naa wa lara mi titi di asiko yi.”
Olayemi ni oun fẹ iyawo oun nisu lọka, koda o ni oun pe elere lọjọ igbeyawo.
O ni ọrọ ija oun ati iyawo mi ti wa ni ile Ẹjọ bayi.
Ki ni iyawo sọ lori iṣẹlẹ yii?
Kehinde Aroyehun iyawo Afeez Olayemi ni ọkọ oun ni oun ko fẹ ri mi nile tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ko lọ.
Iyawo ni ọjọ Karundinlogbon osu Kẹfa jẹ ọjọ buruku fun oun pupọ.
“O ti pẹ ti ọkọ mi ti ma lumi bi bara. Ko da o ti lumi toyun toyun titi oyun naa fi ba jẹ mọ mi lara.
“Iya ni Ọkọ mi Afeez Olayemi ma n fi jẹ mi ni gbogbo igba. Ko tọju ọmọ kan ti mo tun bi fun.
“Ọkọ mi Afeez lo kọkọ gba iya mi leti ti iya mi ko si se ìkankan fun lọjọ ti wahala naa bẹrẹ.”
Kehinde tun fi da wa loju wi pe, ọkọ oun lo ma n pe awọn Amotekun to ba ti lu oun tan lati pe ki wọn maa ba oun bẹẹbẹẹ.
Kehinde sọ wipe oun fẹ ki ile ẹjọ ko ba oun tu igbeyawo oun ka pẹlu Afeez nitori iya naa ti pọju fun oun.
“Oyun Meji ni Ọkọ oun ti bajẹ mọ oun lara nipasẹ lulu.
Ki ni iya iyawo ti Olayemi ni lati sọ?
Florence Aroyehun to iya fun iyawo Afeez Olayemi ni lati ibẹẹrẹ irinajo ifẹ Opeymi ati Kehinde ni inu o ti dun si irinajo ifẹ naa
“Inu mi ko dun bi ọmọ mi Kehinde se fẹ Afeez Olayemi lati ibẹrẹ irinajo naa.
“Ọjọ ti Isẹlẹ to sẹlẹ waye bi ọsẹ Meji sẹyin, sa dede ni ọmọ mi Kehinde to jẹ iyawo Afeez pe mi lori foonu wi pe, ọkọ oun tun ti bẹrẹ si ma lu oun. Ere ni mo sa de ile wọn lọjọ naa.
“Bi mo se dele wọn ni mo pade ọkọ ọmọ mi, mo si bere oun to sẹlẹ lọwọ rẹ, bi Afeez ọkọ ọmọ mi se gba oju mi nu. Eyi lo mu ki emi naa buu laṣọ mu ti mo si gbe eyin le laya.”
Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ yii?
BBC news Yoruba kan si Arabinrin Yemisi Opalola ẹni to jẹ agbenuso fun awọn Ọlọpaa ipinlẹ ọsun lori Isẹlẹ naa.
Arabinrin Yemisi Opalola naa fi idi Isẹlẹ naa mulẹ wi pe, iwa to ku diẹ kato ni iyawo Afeez Olayemi wu si ọkọ rẹ lati pe awọn akẹgbẹ rẹ Amotekun ki wọn lọ gbe ọkọ rẹ lati fii iya jẹ.
Yemisi Opalola wi pe, ko si ninu ofin ki ọkọ tabi iyawo ma lo agbara wi pe o jẹ oṣiṣẹ agbofinro le iyawo tabi ọkọ rẹ lori rara.
Yemisi Opalola tun wa fi kun wi pe awọn si wa lori Isẹlẹ naa ati wi pe, ile ẹjọ n to rí sì ọrọ idile ti wa lori ọrọ pẹlu.
Akitiyan BBC News Yoruba lati le gbọ ọrọ lẹnu ikọ Amotekun lo jasi pabo nitori wí pe, wọn ko fẹ sọ ohunkohun rara lori Isẹlẹ naa.
BBC News Yoruba wa kan si Shittu Amitolu ẹni to ti fi igba kan ri jẹ Ọga awọn Amotekun nipinlẹ Ọsun.
Shittu Amitolu salaye wi pe, ko si ninu ofin tabi ilana Amotekun lati ran obinrin to wa ninu oyun lọ si ita lati lọ sisẹ abo rara.
“Lakooko igba ti mo jẹ Ọga Amotekun nipinlẹ Ọsun. Ko si obinrin to le wa ninu oyun ko tun sisẹ abo nita. Ki se Amotekun nikan ni, sugbọn fun gbogbo awọn ẹsọ alabo patapata ni.
Shittu Amitolu tun wa fi kun ọrọ wi pe. Ọrọ Afeez Olayemi ati iyawo rẹ Kehinde Aroyehun ki se oun to sokunkun si oun rara.
“Lotitọ ni wi pe mo ti fi igba kan dasi ọrọ naa, ko daa, mo ti fi igba kan ti Afeez Olayemi ọkọ Kehinde Aroyehun mọlẹ fun ọjọ Meji gbako nitori ọrọ ija naa.
Shittu Amitolu wa gba gbogbo awọn ẹsọ alabo nImọran wi pe, ki wọn ma se lo agbara ti wọn ni le iyawo tabi ọkọ wọn lori.















