Ọmọkùnrin méjìdínlàádóta gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó jí wọn gbé fún abẹ́ dídá

Oríṣun àwòrán, Daily Mail
O kere tan, awọn ọmọkunrin mejidinlaadọta (48) ti ọjọ ori wọn ko ju mẹwaa si mẹtadinlogun lọ ni wọn lugbadi ijinigbe lọwọ awọn kan to fẹẹ dabẹ fun wọn tipatipa lorilẹede Zambia.
Koda, ọkan ninu awọn ọmọkunrin naa to ni aisan HIV to si gbọdọ maa lo oogun rẹ, ko ri oogun ọhun lo fun ọsẹ meji nigba ti wọn ji i gbe.
Bakan naa ni ọmọkunrin kan to ni aisan ‘bilharzia’, aisan kan to maa n tan kalẹ latari omi ẹgbin to si maa n fa ki ọmọde ma dagba, wa lara awọn ti wọn ji gbe.
Awọn alaṣẹ Zambia to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC, ṣalaye pe awọn obi awọn ọmọkunrin naa ko mọ nipa bi wọn ṣe fipa dabẹ fun awọn ọmọ wọn.
Wọn ni awọn onikọla tipatipa yii maa n lọọ ko awọn ọmọkunrin nileewe, wọn yoo dunkooko mọ awọn tiṣa, wọn yoo si ko awọn ọmọ naa wọgbo lọ.
Ẹka iroyin Zambia National Broadcasting Corporation (ZNBC), ṣalaye pe nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni awọn to n fipa dabẹ naa gbe agọ kan kalẹ si ẹyin odi ibi kan ti wọn n pe ni Livingstone, ninu igbo kan ti ko jinna si igbo ọba Zambia.
Wọn fi kun un pe agbegbe ọhun ko jinna sibi ti wọn n sin oku si, ibẹ ni wọn ti n dabẹ lai gba aṣẹ lọwọ obi tabi ijọba.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n gbe pamọ́?

Oríṣun àwòrán, Daily Mail
‘Mukanda’ ni wọn n pe eto dida abẹ fun ọmọkunrin ni Zambia.
Eyi ti wọn da silẹ yii ko ba ofin mu gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ilana ti ko ba imọtoto mu ni wọn si fi gbe e kalẹ pẹlu.
Ni ti awọn ọmọkunrin yii, Mainga Kabika,ọga agba lẹka to n ri si ọrọ akọ atabo ni Zambia, sọ pe wọn ti gba awọn ọmọ naa kuro loko ajinigbe.
Kabika ati awọn alaṣẹ yooku ti wọn jọ ṣabẹwo si ibudo abẹdida naa,ṣalaye pe ọjọ Aje, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keje yii ni ọwọ ba ẹni to kọ agọ naa.
O fi kun un pe wọn ti dana sun ibudo naa pẹlu.
Ileewosan ni wọn sare gbe mẹta ninu awọn ọmọkunrin naa lọ lẹyin ti wọn gba itusilẹ.
Eyi ri bẹẹ latari iṣoro ti wọn koju nibi ti wọn ti fi abẹfẹlẹ lasan sọ wọn di ọkunrin.
Iwa ọdaran ni awọn to da ibudo naa silẹ hu gẹgẹ bi awọn alaṣẹ Zambia ṣe wi, paapaa bo ṣe jẹ pe wọn tun n pe awọn obi awọn ọmọ naa lorii foonu pe ki wọn fowo ranṣẹ sawọn.
Owo bii $75 (£58) ni iroyin sọ pe wọn n beere lọwọ awọn obi, gẹgẹ bii owo itọju ti yoo sọ awọn ọmọ wọn di ọkunrin.
Gbogbo eyi ni wọn ni yoo dopin laipẹ, pẹlu idasi ofin ati fifi iya jẹ ẹni tọwọ ba tẹ.














