‘Wọ́n ti pa mí lọ́mọ’- Àwọn òbí ń ṣọ̀fọ̀ àwọn ọmọ wọn tí ilé ẹ̀kọ́ wó pa ní Jos láìpẹ́ yìí

Oríṣun àwòrán, Lati ọwọ ẹbi Chidera Onovo
Aworan itan ti ẹ n wo ti wọn kọ si oju ewe to wa loke eyi to da lori Kiniun kan to ya ọlẹ alapa ma ṣiṣẹyii jẹ ohun iranti ti ọmọde kan fi silẹ lẹyin iku rẹ.
Ọmọ ọdun marundinlogun ni Chidera Onovo jẹ ọmọ to nifẹ awọn to yii kan lọkan pupọ, bẹẹ lo si fẹran lati maa ya aworan, to bẹẹ gẹ to fi jẹ pe oun ni ayo iya rẹ.
Blessing Onovo to jẹ iya Chidera ṣalaye fun BBC pe, “igba kan wa to jẹ pe o fi re awọn owo ounjẹ rẹ pamọ lati fi ra ipapanu bisikiti fun awọn aburo rẹ.” O fi kun un pe ọpọ igba naa lo maa n mọ ipo ti oun ba wa ti yoo tilẹ tun maa bere pe “Maami ṣe ko si nnkankan to n ṣeyin?”
Ni ọjọ Ẹti to kọja lọ ni Chidera lọ si ile ẹkọ girama pẹlu aburo rẹ obinrin ti orukọ rẹ n jẹ Chisom, amọṣa ẹni kan pere ninu wọn lo pada wale laaye.
Ijọba orilẹede Naijiria ni akẹkọọ mejilelogun lo ku sinu iṣẹlẹ ijamba ile didawo to waye ni ile ẹkọ girama Saints Academy, ile ẹkọ aladani kan to wa ni ilu Jos; amọṣa awọn olugbe agbegbe naa ni iye awọn akẹkọọ to ku sun mọ aadọta.
Pẹlu ṣọbiri ati ọwọ lasan lawọn obi fi n wa awoku ile to dawo lati wa awọn to ṣi wa laaye lara awọn akẹkọọ ti ile wo lu naa lati tu awọn akẹkọọ to ha si abẹ awọn awoku ogiri.
Chike Micheal Onovo to jẹ baba Chidera sọ pe “Nnkan bii wakati kan gbako lo gba ki wọn to ko awọn katakata de fun idoola ẹmi”
“Mo n wo o bi wọn ṣe n wọ ọmọ mi obinrin, Chisom jade. Ọkan mi tilẹ balẹ diẹ: bẹẹ ni mo n pariwo ‘Nibo ni Chidera ọmọ mi ọkunrin?’.”
Wọn ri okun ọmọdekunrin naa nigba to ya nibi ti kọnkere ti wo lu u mọlẹ ni kilasi rẹ to wa ni aja kini ile naa.
'Awọn eeyan n gba ọna ẹburu’
Bakan naa ni Ọgbẹni Victor Dennis ẹni ọdun mẹtalelogoji pẹlu naa n wa ọmọ rẹ ti oun pẹlu jẹ akẹkọọ ni ile ẹkọ Saints Academy. Amọṣa ohun ti ko fẹ ko ṣẹlẹ ṣẹlẹ nigba ti wọn fi idi rẹ mulẹ fun un lẹyin ọjọ kan ti iṣẹlẹ naa ṣẹ nigba to ri oku ọmọ rẹ ni ile igbokusi kan lagbegbe naa.
“Ọmọ daadaa ni ọmọ mi. Ko yẹ ko tii ku. Wọn pa ọmọ mi ni. Ko si ẹṣẹ kan to ṣẹ. O kan lọ si ile ẹkọ lati kẹkọọ ni.”

Oríṣun àwòrán, Chris Ewokor/ BBC
Pẹlu omije loju ni Ọgbẹni Denni fi ba BBC sọrọ bi awọn eeyan ṣe n kọrin idagbere nibi eto isinku ọmọ rẹ. Iyawo rẹ to jẹ iya Emmanuel ko si nibi eto isinku naa, nitori ile lo wa nibi ti o ti n ṣọfọ ọmọ rẹ.
Awọn eeyan ni ilu Jos ti gbaruku ti ara wọn, bẹẹ ni ọpọ si ti fi ẹjẹ silẹ lati doola pupọ lara awọn akẹkọọ naa to wa nile iwosan.
“Awọn ohun elo ikọlu ti ko kun oju iwọn ni wọn lo – o ṣeṣe ko jẹ pe eyi lo ṣokunfa bi ile naa ṣe dawo.” Eyi lọrọ Onimọ nipa aworan ile yiya, Oluṣẹgun Godwin Olukọya to jẹ adari ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ ayaworan ile ni ipinlẹ Plateau.
“Awọn abọ iwadii akọkọ ti a ṣi ṣe fihan pe o ṣeeṣe ko jẹ pe aitẹle ilana to de ile kikọ wa lara awọn ohun to ṣokunfa rẹ.”

Oríṣun àwòrán, AFP
Lẹyin ti iṣẹlẹ ile didawo waye ni ile ẹkọ girama Saints Academy waye, gomina ipinlẹ Plateau ti paṣẹ pe ki ayẹwo waye lori gbogbo awọn ile ikẹkọọ lawọn ile ẹkọ gbogbo jakejado ipinlẹ naa.
Awọn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ Plateau ni ko daju boya ẹni to ni ile ẹkọ naa, bi o tilẹ jẹ pe o ti ku ṣaaju akoko yii, gbe iwe aṣẹ fun kikọ ile ẹkọ naa.
BBC ko lanfani lati gbọ lẹnu awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa.
Awọn kan tun n funra si awọn igbesẹ iwakusa to n waye nitosi ile ẹkọ naa gẹgẹ bi ara ohun to le ba awọn ile to wa ni ile ẹkọ naa jẹ, niorti rẹ, gomina ipinlẹ naa si ti paṣẹ ki awọn agbofinro mu gbogbo awọn awakusa alarobọ ti wọn ba mu to n wa kusa lagbegbe naa.
Amọṣa, ohun ti ọpọ awọn alẹnulọrọ n sọ ni pe wahala naa nii ṣe pẹlu bi wọn ṣe kọ ile ẹkọ naa.
Amọṣa, iwọnba itunu ni eyi ni fun ọpọlọpọ awọn mọlẹbi ti ọmọ wọn, bi i ti Chinecherem Joy Emeka, wa lara awọn to ku sinu iṣẹlẹ buruku yii.
Ọmọ ọdun mẹtala naa wa lara awọn akẹkọọ to mọọ jo julọ ni ile ẹkọ naa, to si jẹ pe ala rere to ni ni lati di dokita lọjọ iwaju.
Blessing Nwabuchi to jẹ iya Chinecherem, tabi Chi Chi gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe e ṣalaye fun BBC pe idanwo opin saa lo n ṣe lọwọ ki o to jade laye.
Awọn fọto bi i ti isalẹ yii, eyi ti wọn ya lasiko ayẹyẹ ikẹkọjade ipele akọkọ ile ẹkọ girama lọdun to kọja wa lara awọn ohun ti wọn fi n ranti awọn nnkan to gbe ile aye ṣe, tabi awọn ohun ti i ba gbele aye ṣe ka ni ko ku laito ọjọ.

Oríṣun àwòrán, Lati ọwọ ẹbi Chinecherem Joy Emeka















