Èèyàn 103 ni Kọ́lẹ́rà ti pa ní ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ní Naijiria - NCDC

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ajọ NCDC to n gbogun ti aisan ati idena rẹ ni Naijiria ti kede pe eeyan mẹtalelọgọrun-un ni wọn ti di oloogbe bayii nipinlẹ mẹrinlelọgbọn ni Naijiria, aisan Kọlẹra lo si pa wọn.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2024 ni NCDC sọ eyi di mimọ, nigba ti ọga agba ajọ naa, Dokita Jide Idris, n ba awọn akọroyin sọrọ l’Abuja.
O ni onka yii lawọn ri ka titi di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keje, 2024.
Dokita Idris sọ pe arun Onigba meji ta a mọ si Kọlẹra ti wa nijọba ibilẹ 187 ni Naijiria, eyi to fa a ti ida 2.8% eeyan ṣe ti di oloogbe lati ibẹrẹ ọdun yii.
Ọga awọn NCDC yii sọ pe iṣẹlẹ to le lẹgbẹrun mẹta (3,623) ti awọn fura si pe Kọlẹra ni lo wa lakọsilẹ ajọ naa bayii.
O ni awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju marun-un lọ ni Kọlẹra naa kọlu ju, ida mejilelaaadọta (52%) wọn si lo jẹ ọmọkunrin.
Ọga awọn NCDC naa ṣalaye pe asiko ti ojo ba n rọ pupọ ni aisan Onigbameji maa n lagbara si i.
O fi kun un pe awọn ipinlẹ kan lapa Ariwa ti wọn maa n saaba koju Kọlẹra ko fi bẹẹ lugbadi ẹ lọdun yii. O ni o ṣee ṣe ko jẹ ojo ti ko ti i bẹrẹ nibẹ lo fa a.
‘’Bo tilẹ jẹ pe Kọlẹra ti kan ipinlẹ pupọ ni Naijiria, o da bii pe iroyin ko to nipa rẹ latari aisi ohun eelo iwadii ati eyi ti wọn yoo fi mọ bi arun naa ba ṣẹyọ nibi kan. ‘’ Idris lo sọ bẹẹ.
Dokita Idris sọ pe awọn mi-in ti ki ọrọ oṣelu bọ Kọlẹra yii, ero awọn ẹlomi-in si ni pe aisi omi to ṣee mu ati awọn nnkan amayedẹrun lo n fa Kọlẹra.’’
‘Ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀, Lassa àti àìsàn yínrùn-yínrìn ló tún mú Kọ́lẹ́rà le sí i

Oríṣun àwòrán, NCDC
“Ọrọ Kọlẹra yii lagbara si i nitori awọn aisan miran bii iba pọnju-pọntọ, Lassa ati aisan yinrun-yinrun to n pọ si i.” Dokita Idris lo ṣafikun bẹẹ.
O ni pẹlu gbogbo iṣoro wọnyi ṣaa, ijọba n dahun si ibeere awọn araalu lorii Kọlẹra, ki aisan naa ma baa ṣọṣẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
Nipasẹ NCDC lo ni wọn ti n ṣe eyi.
Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn igbesẹ bii itọpinpin, ilanilọyẹ nipa ilera ati fifun awọn agbegbe to nilo itọju lohun ti wọn fẹ ni ijọba n ṣe.
Bakan naa lo ni ọwọja Kọlẹra lọ silẹ ni ida marun-un aabọ (5.6%), bẹẹ ni iku paapaa ja walẹ lati ida 2.9% si 2.8%).















