Sunday Igboho tún ti pàṣẹ fáwọn Fulani láti kúrò nínú igbó ìjọba l'Oyo, ìjọba fèsì

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram
Ajijagbara n ni nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho tun ti ṣe ikilọ fawọn Fulani darandaran lati fi igbo ijọba silẹ ni ipinlẹ Oyo ni kiakia.
Igboho fẹsun kan awọn Fulani darandaran pe awọn lo wa nidi iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan kaakiri ipinlẹ Oyo.
Amọ, Ọgbẹni Sulaimon Olanrewaju to jẹ akọwe iroyin fun Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ fun BBC Yoruba pe Igboho ko laṣẹ labẹ ofin lati le ẹnikẹni kuro nibi ti wọn n gbe.
Olayemi Koiki to jẹ agbẹnusọ Igboho lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu fidio kan to fi soju opo Facebook rẹ.
Koiki ni Igboho ti paṣẹ fun awọn ikọ rẹ lati lọ sawọn inu igbo to wa lagbegbe Oke-Ogun, ni ipinlẹ Oyo lati le gbogbo awọn Fulani darandaran ti wọn n gbe nibẹ kuro.
Koiki ni olori ajijagbara naa sọ pe oniruuru ipaniyan ati ijinigbe lo ti ṣẹlẹ lagbegbe Oke-Ogun, to si ni bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe ni agbegbe naa ko dun mọ oun ninu.
“Lonii, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keje, ọdun 2024, iroyin yajoyajo yii la a gbe sita ni agogo mẹfa.
Gbogbo Fulani to n gbe ni Oke-Ogun, ti wọn n gbe ninu awọn igbo to wa nibẹ, ti wọn jẹ ajinigbe, ti wọn n pa awọn eeyan, la n paṣẹ fun pe ki wọn kuro nibẹ bayii.
“Sunday Igboho loun yoo tẹsiwaju iṣẹ oun ni Oke-Ogun, Kishi ati awọn agbegbe mii ni Oke-Ogun. O sọ pe gbogbo agbegbe yooku loun yoo de.
“Ki gbogbo Fulani fi inu igbo Oke-Ogun silẹ. Igbo naa kii ṣe ti yin, awa la ni ilẹ wa.
O tun sọ pe oun n duro de awọn ọba to wa nilẹ Yoruba lati jẹ ki oun mọ, bi wọn ba n koju iṣoro awọn Fulani.
Igboho ko ṣai sọ pe oun o ba gomina kankan ja lori ọrọ yii, bi ko ṣe awọn Fulani darandaran to ni wọn n da omi alaafia ilẹ Yoruba ru.
Sunday Igboho ko laṣẹ lati le awọn Fulani kuro l'Oke Ogun - Ijọba Oyo
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe Sunday Ighoho ko laṣẹ labẹ ofin lati le ẹnikẹni kuro nibi ibi ti wọn n gbe.
Ọgbẹni Sulaimon Olanrewaju to jẹ akọwe iroyin fun Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo sọ fun BBC Yoruba pe ‘’Oloye Sunday Ighoho kọ ni ijọba, ki i ṣi i ṣe ọlọpaa, Oloye Sunday Igboho kọ ni awọn ologun.
Awọn ti wọn le paṣẹ nipa ọrọ abo ilu niyẹn, ero ti Oloye Igboho lo sọ sita kii ṣe ohun ti ijọba fẹ ṣe.’’
Akọwe iroyin gomina ipinlẹ Oyo ni nnkan ti ijọba n ṣe ni lati daabo bo gbogbo eeyan to wa nipinlẹ Oyo.
O ni ijọba n lo awọn ọlọpaa, ologun, Amotekun atawọn fijilante lati daabo awọn araalu nipinlẹ Oyo.
Ọgbẹni Olanrewaju ni ofin orilẹede Naijiria faye gba ẹnikẹni to ba jẹ ọmọbibi orilẹede naa lati gbe nibi kibi ni Naijiria.
‘’Gomina ipinlẹ Oyo ko sọ pe ki ẹnikẹni kuro nibi ti wọn n gbe e o, ohun ti ijọba ipinlẹ n ṣe ni pe ki o daabo bo araalu.
Gomina Makinde ko ba Oloye Igboho ja, amọ, ofin lo n ṣakoso iṣesi ati ihuwasi wa ni Naijiria.
Ofin Naijiria ko fun ẹnikẹni lagbara lati sọ pe ki ẹnikan kuro nibi to ba n gbe.
Nitori naa, kii ṣe ọrọ ija, bi Oloye Igboho ṣe ni oun o ba gomina ja, gomina naa ko bawọn ja,’’ akọwe iroyin Gomina ipinlẹ Oyo lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Olanrewaju sọ pe nnkan ti ijọba ipinlẹ Oyo n fẹ ni pe ki onikaluku bọwọ fun ofin Naijiria.
Ọlọrun lọwọ si bi mo ṣe lọ doju kọ awọn Fulani to n ṣọṣẹ ni Ibarapa - Sunday Igboho
Ṣaaju lọdun 2021 ni ajijgbara Igboho sọ pe Eledua gan an lọwọ si bi oun ṣe doju ija kọ awọn Fulani to ni wọn pa awọn eeyan nipinlẹ Oyo.
Igboho ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa kede nigba naa pe oun yoo le awọn onisẹ ibi Fulani jinna rere nipinlẹ Ogun.
O ni ariwo isẹ ibi awọn ọdaran darandarn nipinlẹ Ogun ti de etigbọ oun, oun si ti setan lati dahun si igbe ẹbẹ awọn ọmọ Yoruba to wa nipinlẹ naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ariwo sọ nigba ti awọn sọja lọ na awọn agbẹ lawọn abule kan nipinlẹ Ogun lori ẹsun pe wọn ko gba awọn darandaran laaye lati da ẹran jẹ ni agbegbe naa.
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Igboho ni asiko ti to ti Ọlọrun fẹ tu awọn Yoruba silẹ lọwọ ide awọn onisẹ laabi laarin awọn darandaran.
O si jẹ ko ye awọn eeyan pe Ọlọrun lọwọ si lilọ toun lọ si agbegbe Ibarapa lati lọ kilọ fawọn onisẹ ibi Fulani.
Igboho ni ''iya to n jẹ awọn eeyan ni agbegbe Ibarapa naa ti pọ ju, eyi to le gongo pẹlu iku Ọmọwe Aborode, isẹlẹ yii si lo tu asiri awọn isẹlẹ buruku to n waye nibẹ."
Igboho tẹsiwaju pe "pẹlu aṣẹ Ọlọrun ọba, awọn isoro Fulani nipinlẹ Ogun naa yoo yanju.
Gbogbo awọn ọdaran Fulani to ba wa loke Ogun ni ko maa mura mi silẹ, mo n bọ kankan."
Ajafẹtọ ẹni naa wa gbarata lori bi awọn oloselu se n pagi dina akitiyan rẹ lati gba awọn iran Yoruba silẹ lọwọ inira, eyi to ni oun n se pẹlu ootọ inu.
Ẹni ba mọ Sunday Igboho ko ba wa bẹ ẹ o, a o mọ ibi ti a le ko lọ, Seriki Fulani pariwo sita

Ṣaaju loṣu Kinni ọdun 2021 ni Sẹriki Fulani ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abdulkadir to n gbe ilu Igangan nipinlẹ Oyo ke gbajare sita pe ẹnikẹni to ba mọ Oloye Sunday Igboho ko ba awọn rawọ ẹbẹ sii ni nitori pe ko si ibi ti awọn lee ko lọ bayii mọ lẹyin aadọta ọdun.
Seriki Fulani sọrọ yii lẹyin ti Igboho sọ pe kawọn Fulani kuro niluu Igangan ati ni gbogbo Ibarapa nipinlẹ Oyo, bi bẹẹ kọọ, oun n bọ lati le wọn kuro.
Alhaji Abdulkadir to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe gbogbo ibi to yẹ lawọn n sa kaakiri lọ bayii lati wa ọna abayọ si ọrọ naa.
O ni lootọ ijọba n fi awọn lọkan balẹ pe Igboho ko ni lee ṣe ohun to wi, sibẹ gbogbo awọn eeyan to ba mọ ọ lawọn n bẹ bayii ki wọn ba awọn pẹtu si i ninu ki wọn si le joko sọrọ naa ni itubi inubi.
Alhaji Abdulkadir to ni bi awọn aletilapa darandaran to sọ ara wọn di darandaran naa ṣe n ṣọṣẹ fun awọn ọmọ onilẹ lagbegbe naa ni wọn n ṣọṣẹ fun awọn gan an pẹlu to jẹ Fulani to tẹdo si agbegbe naa.
Seriki ni awọn ti kan sawọn agbofinro, awọn si ti kan sawọn ọbalaye lagbegbe Ibarapa lati lee wojutu si ọrọ naa to si jẹ pe wọn n fi awọn lọkan balẹ ni pe yoo lojutu laipẹ.
O ni awọn ko palẹ ẹru kankan mọ nibẹ nitori awọn ko tilẹ mọ ibi ti awọn lee dorikọ nitori pe agbegbe naa ni gbogbo awọn mọ ni ile lẹyin ti ọpọ wọn ti gbe nibẹ fun ọpọlọpọ ọdun.















