Kíni ojúṣe ìgbìmọ̀ tí Makinde yàn lórí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tílé ẹjọ́ 'sọ di òmìnira'?

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo ti sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko nilo aṣẹ lati ọdọ ijọba apapọ orileede Naijiria ki wọn to gbe igbesẹ kankan lati tukọ ipinlẹ wọn.

Makinde sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko tii ri iwe idajọ ti ile-ẹjọ to ga julọ ni Naijiria gbe kalẹ l’Ọjọbọ, ọsẹ to kọja, ṣibẹ o ni awọn yoo tubọ maa ṣe ohun to tọ lati rii pe idagbasoke ipinlẹ Ọyọ n lọ bo ṣe yẹ.

Gomina sọrọ yii nibi ipade to ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ ninu eto iṣejọba ibilẹ ipinlẹ Ọyọ lọjọ Aje, nibi to ti gbe igbimọ ti yoo ṣagbeyẹwo awọn ohun to wa ninu iwe idajọ naa.

Makinde sọ pe pẹlu awọn nnkan ti oun gbọ nipa idajọ naa, iṣini lọna lo jẹ, nitori pe yatọ si ijọba ibilẹ to wa, awọn tun ṣi ni ijọba ibilẹ idagbasoke ti ile-ẹjọ ko mẹnuba, to si ni awọn yoo wa ọna abayọ sii.

O ni oun ko ni jẹ ki iya jẹ awọn araalu nitori idajọ ti ile-ẹjọ agba gbe kalẹ nipa pe ki awọn ijọba ibilẹ maa ṣakoso owo wọn.

“Mo pe ipade awọn agbaagbaa ati alẹnulọrọ ninu eto ijọba ibilẹ nipinlẹ lonii, bo tilẹ jẹ pe a ko tii ri awọn ohun to wa ninu iwe idajọ (CTC) ile ẹjọ agba orileede yii. Adajọ agba ipinlẹ yii wa nibi, nitori pe oun naa wa nile-ẹjọ l’Ọjọbọ, ọsẹ to kọja.

“Adajọ agba ni yoo ṣalaye ohun ti wọn ba bọ nibẹ fun wa, ṣugbọn mo rọ pe o yẹ ki n sọrọ. O n bọ, o n bọ, awọn la n dẹ de. Mo tiẹ tun ti ka ọpọlọpọ akọle ninu awọn iwe iroyin nipa idajọ naa.

“Wọn n sọ pe ‘apa awọn gomina ti kan, ohun to dara julọ to ti ṣẹlẹ si Naijiria ree’, koda laarọ oni, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ sọ pe awọn ti gba ominira.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Mo dupẹ lọwọ yin wi pe ẹ wa sibi, bẹẹ si ni mo fẹ ka jọ jiroro lori idajọ naa to sọ pe ki ijọba ibilẹ maa ṣakoso owo wọn. Pẹlu ohun ti iwe ofin Naijiria sọ, emi naa bura gẹgẹ bii gomina, ti a ko si gbọdọ tako ofin.”

Ni ti eto idibo ijọba ibilẹ, Makinde tẹsiwaju pe eto idibo meji ọtọọtọ loun ti ṣe lai ni wahala kankan, to si loun korira lati ma da awọn eeyan lẹbi nipa igbesẹ ti wọn ba n gbe, eyi ti kii tọ.

“Ile-ẹjọ sọ pe gomina ko laṣẹ mọ lori eto idibo ijọba ibilẹ, ṣugbọn sibẹ, a tun ni ijọba ibilẹ idagbasoke. Ṣe ẹ wa rii pe idajọ naa ko yẹ wa mọ.

“A maa tọka si awọn ipenija ti a n ni lawọn ijọba ibilẹ, ti a si maa gbe awọn ọna abayọ ti wa naa sita, ati ọna lati jẹ ka maa ṣakoso ipinlẹ wa daadaa.

"Mo ni igbagbọ pe ipinlẹ Ọyọ yoo bori daadaa, nitori pe a mọ ohun to dara fun awọn eeyan wa.

“Ijọba apapọ ko lagbara ju ipinlẹ lọ labẹ ofin, bo tilẹ jẹ pe wọn ni awọn ohun amuṣọrọ rẹpẹtẹ ju ipinlẹ lọ. Fun idi eyi, a le ṣe ohun tọ nipinlẹ Oyo, ati pe a tiẹ ti n ṣe ohun to tọ.”

Gbese biliọnu mejidinlogun ti mo ba nilẹ ni mo ti san

Bakan naa lo sọ pe gbogbo gbese owo oṣu, ajẹẹlẹ ati ti oṣiṣẹ fẹyinti lawọn ijọba ibilẹ toun ba nilẹ loun ti san, to si biliọnu mejilelogun loun fi san gbese ti wọn ti jẹ lati ọdun 2017.

“Ka to de ori ipo, ọdun 2017 ni wọn ti gba owo ajẹmọnu ti isinmi lẹnu iṣẹ gbẹyin. Iṣakoso wa yii lo san gbogbo gbese naa, ti a si tun san-an wọ ọdun 2023.

“Gbogbo ẹyin ti ẹ wa lori iṣakoso ijọba ibilẹ bayii, paapaa ẹyin ti ẹ ṣe saa keji lọwọ la jọ n ṣiṣẹ papọ lati rii pe awọn araalu jẹ mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa. Biliọnu mejilelogun naira la fi san gbese.

“Awọn ilewosan alabọde mẹsanlenigba la mu idagbasoke ba, a si tun ra irinṣẹ si awọn ile iwosan alabọde naa ti ko din ni ẹrinlelọgọtalenigba (264), a tun pari ile-ẹkọ ọgọta, bẹẹ al tun ṣatunṣe ile-ẹkọ alakọbẹrẹ to le ni ọgọrun kan, ti a tun ṣe atunṣe awọn ọna igberiko.

“Ṣugbọn sibẹ, a ṣi tun ni awọn ipenija ti a ni lati gbe yẹwo. A ni awọn gbese owo ajẹẹlẹ ti a ko tii san, mo si sọ ninu ipade ti mo ṣe pẹlu igbimọ NUP lọsẹ to kọja. A ṣagbeyẹwo iye owo yẹn, a si rii pe o maa gba wa to ogun ọdun ka to le san gbese yẹn, paapaa eyi to tun ṣi wa nilẹ bayii.

“Biliọnu marundinlọgọta naira la ri ninu ipade naa ti a jẹ silẹ, to jẹ gbese ati ajẹẹlẹ. Nigba ti a n dagba, mo gbọ pe iṣoro wa kii ṣe owo, bi ko ṣe ọna ti a fẹ gba na owo.”

Iṣoro ti a ni kii ṣe ti owo

Bakan naa ni Makinde fi kun ọrọ rẹ pe iṣoro ti orileede Naijiria n koju kii ṣe ti ọrọ owo, bi ko ṣe ọna lati pin owo to wa nilẹ, ati bi wọn ṣe le ṣamulo rẹ.

O ni oun ti wa rii pe iṣoro to wa nilẹ gan-an, lẹyin ti ile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ kii ṣe bi wọn ṣe fẹẹ pin owo ọhun, bi ko ṣe bi wọn ṣe fẹ na owo lati rii pe o dele-doko.

“Mo gbọ pe olori ilẹ wa nigba kan lọ san gbese awọn orileede miran bii Uganda, nigba ti awọn orileede miran n mu idagbasoke ba ilẹ wọn lọpna ti yoo fun eto ọrọ aje wọn lagbara.

“Ohun ti mo si n gbọ bayii nipa idajọ ile-ẹjọ naa ni pe iṣoro wa kii ṣe ti owo, bi ko ṣe bi a ṣe fẹẹ pin in. Ṣugbọn emi ti wa rii pe iṣoro wa kii ṣe bi a ṣe fẹẹ pin owo, bi ko ṣe bi a ṣe fẹẹ akara oyinbo nla ti yoo mu awọn eeyan wa kuro ninu iṣẹ ati oṣi.”

Nigba to n sọrọ nipa ojuṣe laarin ilu, gomina sọ pe awọn araalu ko bikita lati mọ boya ijọba apapọ lo ṣe opopona kan, tabi ijọba ipinlẹ tabi ti ibilẹ, o ni ohun ti wọn n fẹ ni lati ri opopona to dara wa nilu.

Bẹẹ lo sọ pe “Lai nii wo ti ohun ti ijọba apapọ n ṣe, awa ko nii fi ọrọ oṣelu si ọrọ awọn eeyan wa. Idi ree ti mo fi wo o pe ka pe ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ ti ọrọ kan.

“Awọn kan n sọ pe ikun mi ti tobi nitori pe mo ti n ko owo ijọba ibilẹ ati ti ipinlẹ jẹ, ṣugbọn mi o ro bẹẹ, mo lero pe bi wọn ba fẹẹ ṣe oṣelu, awa ko nii darapọ mọ wọn lati fi igbesi aye awọn eeyan wa ṣe oṣelu.”