Ǹjẹ́ Ladoja ṣetán láti dé 'adé páálí' ṣáàjú kí ipò Olubadan tó kàn-án?

Makinde ati Ladoja

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọrọ taani yoo jẹ Olubadan lẹyin Ọba Mahood Olalekan Balogun lo tun ti n fẹ da wahala miran silẹ bayii, pẹlu bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe gbe ilana tuntun kalẹ lori bi wọn yoo ṣe maa jẹ oye ọhun.

Gbogbo eeyan lo ti mọ pe gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rasidi Adewolu Ladoja ni ipo ọhun kan lẹyin Ọba to ṣẹṣẹ jẹ yii.

Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju asiko yii ni wahala ẹni ti ipo Olubadan kan ti kọkọ suyọ ni kete ti ọba ana, Oba Mahood Olalekan Balogun waja.

Wahala ọhun lo wa nigboro fun bii oṣu mẹta si mẹrin, ṣugbọn ti gbogbo rẹ wa pada dopin lọjọ Ẹti to kọja yii, ọjọ Kejila, oṣu Keje, ọdun 2024 nigba tijọba Ọyọ gbe ade fun Ọba Akinloye Owolabi Olakulehin, Ige Olakulehin akọkọ gẹgẹ bi Olubadan kẹtalelogoji.

Ninu iwe ilana eto ti wọn ṣe lọjọ naa, ijọba Ọyọ kọ ọ sibẹ wi pe Oloye to ba ni ade to ga julọ ninu awọn ti ipo ọhun to si ni yoo jẹ oye Olubadan.

Bi ẹ ko ba gbagbe, gomina ana, Ladoja ti sọ nigba diẹ sẹyin pe oun ko le de ade kankan, gẹgẹ bi ilana ti ijọba gbe kalẹ.

Ọna lati dena Ladoja lati ma ṣe di Olubadan ni ijọba gbe kalẹ ninu agbeyẹwo ilana ti wọn yoo fi maa jẹ oye ọhun ni Gomina Seyi Makinde ṣe lọdun 2023.

Abala kẹrin ninu akọsilẹ ilana jijẹ oye Olubadan ti ọdun 1957 sọ pe “ẹni wọn yoo maa wo gẹgẹ bi ọmọ oye ti ipo kan lati jẹ Olubadan ni oloye ti ipo rẹ ga ju ni ilana ọhun.”

Ṣugbọn ninu abala kẹrin agbeyẹwo ilana ti ijọba Seyi Makinde ṣe lọjọ Kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2023, o sọpe: “ẹni wọn yoo maa wo gẹgẹ bi ọmọ oye ti ipo kan lati jẹ Olubadan ni ọba ti ade rẹ ba ga julọ ni ilana ọhun.”

Ko sẹni meji ti ipo rẹ tun ga ju ti Ladoja lọ ninu awọn to n jẹ oye Olubadan, ṣugbọn ti baba naa ti kọ jalẹ wi pe oun ko le ba wọn de ade kankan.

Eyi si ṣee ṣe ki ilana tuntun naa ma fun Ladoja ni anfaani lati de ipo Olubadan.

Ki Gomina Makinde gbajumọ ọrọ idagbasoke Ọyọ, ko fi ipo Olubadan silẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ba BBC sọrọ lati sọ erongba rẹ lori ohun o ṣẹlẹ yii, agbẹnusọ Oloye Ladoja, Oloye Adeola Oloko sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ fun wọn nigba ti wọn ri ilana tuntun ti ijọba gbe sita, to si fa ariwo laarin ilu.

Oloye Oloko ni gbogbo eeyan lo mọ pe ọjọ ayọ lọjọ igbade ọba maa n jẹ, ṣugbọn to sọ pe niṣe Gomina Seyi Makinde sọ ọjọ igbade Ọba Olakulehin di ariwo, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Baba naa sọ pe ko si nnkan to kan gomina pẹlu ọrọ oye tabi ipo ọba, bi ko ṣe pe ọrọ eto iṣelu lo yẹ ko gbajumọ, iyẹn bi ilọsiwaju yoo ṣe ba eto ẹkọ, ilera ati awọn miran.

Ninu ọrọ rẹ, Oloko sọ pe: “Bi ijọba ba fẹẹ gbe igbesẹ, niṣe lo ṣe yẹ ki wọn beere lọwọ araalu lati mọ boya o tẹ wọn lọrun tabi ki ni wọn ri sii ni. Ti ẹ ba de ilu Ibadan lonii, ohun ti gbogbo eeyan bii babalọja, iyalọja, oniṣẹ-ọwọ, oni taisi ati awọn miran maa sọ fun un yin ni pe ko tẹ awọn lọrun, ki wọn fi si bo ṣe wa tẹlẹ.

“Eto bi a ṣe n jẹ oye Ibadan ko roju, awọn ọmọ Ibadan si ti fọwọ si lati ọdun 1957 ti wọn ṣe gazette. Ti eeyan ba wa fẹẹ yii pada, niṣe lo yẹ ka lọ sọdọ awọn ara Ibadan, ka si ṣe ipade gbogboogbo ti wọn n pe ni ‘referendom’ lati gbọ tẹnu wọn.

“Wọn ko le ṣa deedee yi ilana pada lojiji. Ọdun mẹrinlelaadọrin ti ilana yii ti n ṣiṣẹ fun wa bọ ree, koda titi de ori Olubadan to wa nibẹ lonii. Ẹ jẹ ka beere pe ṣe ipo gomina papọ mọ ipo Olubadan ni?

Rashidi Ladoja

Oríṣun àwòrán, Screenshot

“Mo sọ pe wọn ko pe ipade lati beere lọwọ awọn to ni ilu pe ṣe wọn nifẹẹ si ayipada yii. Ni ilẹ Yoruba ti Ibadan naa jẹ ọkan lara wọn, njẹ oloye naa ti n jẹ ọba ni, igba wo ni afọbajẹ bẹrẹ sii jọba nilẹ Yoruba?

“Nibi ti nnkan de duro bayii, ohun ti a n sọ fun Baba Ladoja ni pe bi Ọlọrun ba fẹ ki ipo ọhun kan wọn, ki wọn fi wọn silẹ maa woran.

“Ohun ti a ri ni pe ọjọ ayọ ni ọjọ igbade maa n jẹ fun gbogbo ọmọ Ibadan, ṣugbọn nigba ti wọn n joye Olubadan lọsẹ to kọja yii, ṣe ni Gomina Seyi Makinde fi gazette sinu iwa eto lọjọ naa. Ohun to si fa ibinu gbogbo ọmọ Ibadan ree.

“Eeyan ko le ba ọjọ ayọ jẹ fun ọlọjọ ayọ. Ohun ti awọn eeyan sọ ni pe awọn ko ran gomina niṣẹ, eyi la si n bẹ gomina fun.”

A maa sọ igbesẹ to kan sita laipẹ

Siwaju sii ni Oloye Oloko ṣalaye pe gomina Ọyọ ti yi ilana bi wọn ṣe n jẹ Olubadan pada, nitori pe ko yẹ ko pẹ to bo ṣe pẹ yii.

Oloko sọ pe Olubadan ana, Ọba Lekan Balogun waja lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2024, to si ni ọjọ kejila, oṣu keje, ọdun 2024 ni wọn ṣẹṣẹ jẹ Olubadan miran.

O ni jijẹ Olubadan lẹyin ti ọba to wa nibẹ tẹlẹ ba waja kii gba ju ọgbọn ọjọ si ogoji ọjọ lọ, ṣugbọn to ni o ti to ọgọfa ọjọ ki wọn to ṣẹṣẹ gbe ade le ọba lori, leyi to lo ku diẹ kaato.

“Eleyi ti fi han pe ohun ti gomina n ṣe ko dara to, awọn araalu si n binu lori rẹ.

Ohun ti a bẹ gomina le lori fun ni pe ki wọn tun ipinlẹ Ọyọ ṣe, ki wọn tun ẹka eto ẹkọ, ilera ati awọn miran ṣe, kii ṣe ki wọn maa da si ọrọ lọbalọba wa, ko kan gomina. O ni bi wọn ṣe n ṣe nnkan wọn lai ruju, ẹ ma ba wọn da si i.

“Ninu awọn oloye to wa ti ipo Olubadan kan, mọkanla ni wọn. Mẹwaa gba ade, ẹnikan yooku ko gba ade.

O tun ṣalaye siwaju pe: Ẹ wa duro de asiko ti ipo naa kan-an, ẹ wa ni bi ko ba ti gba ade, awọn ko nii jẹ ko jẹ ọba.

“Igbesẹ ti gomina Seyi Makinde gbe yii ko dara rara, ẹni to ba le ba wọn sọrọ, ko ba wọn sọrọ, wọn ko ṣe daadaa to. Otitọ ni awọn eeyan n sọ pe Baba wa Ladoja ni gomina n dojukọ.”

Bakan naa nigba to n sọrọ lori igbesẹ ti wọn yoo gbe, Oloye Adeola Oloko sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ le lori nitori pe ẹnikan kii jẹ awa de.

Wọn si pe baba sori redio, ti wọn n bẹ wọn lati fọwọ wọnu lati gba ade.

“Wọn ti n bẹ Baba Ladoju lati fọwọ wọnu, ki wọn si gba ade.

Bẹẹ lawọn kan sọ pe ki wọn duro loti otitọ ti wọn mọ wọn si, ki wọn lọ si kootu. O digba ti a ba jokoo lati jiroro lee lori.

“Ohun ti a ba fi ẹnu ko le lori la ma jẹ ki ẹ mọ nigba ti a ba pari ijiroro naa.”

Oloye Oloko sọ pe oun ko le sọ pato ohun to n fa aawọ laarin Gomina Makinde ati Oloye Ladoja, ṣugbọn to sọ pe nnkan toun mọ daju ni pe ọtun Olubadan ni Ladoja jẹ.

O lohun toun mọ daju ni pe Ladoja ti ṣe sẹnetọ nigba kan, bẹẹ si ni pe ninu awọn to ṣe gomina ilẹ yii ti Ọlọrun da si, o wa lara wọn, ati pe o ti sunmọ ogun ọdun to ti kuro lori ipo ọhun.