Wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọwa ìlú Idanre Ọba Adegunle Aroloye sọ sílẹ̀ kí ó tó wàjà

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọwa ìlú Idanre Ọba Adegunle Aroloye sọ sílẹ̀ kí ó tó wàjà
Wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọwa ìlú Idanre Ọba Adegunle Aroloye sọ sílẹ̀ kí ó tó wàjà

Awaye ma ku kan ko si, ọrun nikan ni aremabọ.

Ọwa ilu Idanre Ọba Adegunle Aroloye sọ awọn ọrọ kan silẹ silẹ ki ọlọjọ to de.

Ori ade naa sọ fun BBC Yoruba nigba aye rẹ wi pe ''mo mọ pe ti mo ba waja, awọn eeyan maa ranti mi pe ọba daadaa ni mi.''

Kabiyesi naa sọ nigba aye rẹ pẹ nnkan toun fẹ kawọn eeyan maa ranti oun fun ni iwa rere.

‘’Mi kii gbe ẹbi fun alare, mo maa n ṣe iwadii fini fini lori ẹjọ ti wọn ba ti gbe wa sọdọ mi ki n to dajọ.''

Ọba Adegunle sọ fun BBC Yoruba pe oun bori iku nigba ewe oun.

‘’Aisan ṣe mi nigba ti mo wa ni kekere, koda mo ti ku tan ti wọn si ti lọ gbe iho lati sin mi si.

Nigba naa ni iya mi sọ pe ki wọn duro na wi pe o si ku aṣọ aṣọ kan toun maa fi sin mi nitori a kii ku si aafin.

Wọn ti gbe mi wa si ode aafin nigba ti aisan ti n ṣe mi, bayii ni wọn gbe mi ju silẹ fun mama mi.

Mama mi sọ fun mi pe lẹyin naa ni oun bẹrẹ si tu mi.

O ni nigba to ya ni mo sin eyi to mu inu oun dun ti oun si fun mi ni ọmu titi ti mi o fi ṣe aisan mọ.

Kabiyesi Ọwa ilu Idanre ni oun ti dagba ki oun to bẹrẹ ile ẹkọ,''Ọwa Idanre lo sọ bẹẹ.

Ori ade naa ni lẹyin toun pari ile ẹkọ girama tan loun lọ si ilu oyinbo.

Kabiyesi ni lara ohun to dun oun julọ laye ni pe oun o ni anfaani lati ri oku iya oun ki wọn to sin in.

Ilu oyinbo naa si tun ni Ọba Aroloye wa nigba ti baba rẹ ranṣẹ si i pe oun ti n dagba.

O ni ‘’mi o fẹ kuro niluu oyinbo, amọ ṣe ni wọn bẹrẹ si kọ iwe si i ni gbogbo igba pe ki n wale tori baba mi fẹ ri mi.''

Iyẹn lo jẹ ki kabiyesi naa pada wale lati ilu oyinbo, ṣugbọn awuyewuye bẹ silẹ lori ọrọ oye lẹyin ti baba rẹ waja tan.

Kabiyesi naa ṣalaye pe ọdun meje lawọn fi ja lori ọrọ oye Owa Idanre koun to de ipo ọba.