Wo bí Tobi Amusan ṣe gba ipò kínni nínú eré 100m hurdles tó kọ́kọ́ sá ní ìdíje Olympics 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajumọ asare ori ọdan, Tobi Amusan, ti jẹwọ ara gẹgẹ bi ogbontarigi ninu ere ọdan sisa lẹyin to bẹrẹ irinajo ati gba goolu ninu idije Olympics 2024 to n lọ lọwọ niluu Paris lorilẹede France.
Amusan lo sẹ ipo kinni ninu ere to kọkọ sa laarọ Ọjọru lẹyin to pari ere naa ni akoko iṣẹju aaya 12.49.
Ti ẹ o ba gbagbe, Tobi lo gbe asia orilẹede Naijiria lọwọ lasiko ayẹyẹ ibẹrẹ idije Olympics niluu Paris.
Oju wa lara Tobi gẹgẹ bi ọkan gboogi lara awọn elere idaraya to le gba ami ẹyẹ fun orilẹede Naijiria ninu idije Olympics ni Paris.
Tobi naa si ni elere ori ọdan to jẹ ayara bi aṣa julọ lagbaaye lọwọ yii.
O fi akoko tuntun 12.30 lelẹ lati fi gba ami ẹyẹ wura lorukọ Naijiria lowurọ ọjọ Aiku.
Tobi fi akoko tuntun iṣẹju aya12.30 lelẹ eyi ti o fi di elere ori ọdan to yara julọ lagbaaye.











