''Ogún ọdún ni mo fi wá ọmọ, IVF mẹ́jọ ni mo ṣe tó kùnà, 'surrogacy' ni mo fi padà bí ìbejì''

Àkọlé fídíò, ''Ogún ọdún ni mo fi wá ọmọ, IVF mẹ́jọ ni mo ṣe tó kùnà,
''Ogún ọdún ni mo fi wá ọmọ, IVF mẹ́jọ ni mo ṣe tó kùnà, 'surrogacy' ni mo fi padà bí ìbejì''

Arabinrin Emily Francis Ejiovi ti ṣalaye oun ti oju rẹ ri ninu irinajo ati lọmọ laye.

Arabinrin Ejoivi sọ fun BBC Yoruba pe ‘’ogun ọdun sẹyin ni mo bẹrẹ irinajo wiwa ọmọ, mo si ti le ni ẹni aadọta ọdun.

Awọn eeyan ti pe mi ni ajẹ ri, wọn ni mo ti pa gbogbo ọmọ mi jẹ.

Ṣugbọn irinajo naa pada jasi ayọ fun mi, tori ibeji lanti lanti ni mo bi pẹlu bi obinrin mii ṣe bami gbe oyun ti o si bami bi awọn ọmọ naa.

Ọkunrin ati obinrin ni awọn ibeji ti Eleduwa fi rẹmi lẹkun naa.''

Arabinrin Emily sọ pe oun nikan loun o lọmọ ninu gbogbo awọn ọmọ iya oun.

O ni igba mẹjọ ni oyin bajẹ lara oun, bakan naa loun ṣe eto IVF lati bimọ nigba mẹjọ eyi to kuna.

O tun fikun ọrọ rẹ pe ni igba mẹjọ ni oyin bajẹ lara oun.

O ni ‘’eyi gan an lo mu mi wa awọn ti wọn n ṣe ‘’surrogacy’’ ki n le ri ẹni ti yoo bami gbe oyun ati bimọ.

Iya ọkọ mi ti beere lọwọ mi ri pe ṣe ọkunrin ni mi ni ti n ko fi bimọ.

Mo da a loun pe mo si n woju Ọlọrun, amọ, iya ọkọ mi dami lohun pe agan ni mi.’’

Arabinrin Ejiovi sọ pe awọn eeyan lawujọ o ran awọn obinrin ti oju ọmọ pọn lọwọ.

Obinrin yii ni ọkọ oun kọkọ gbaruku ti oun ni ibẹrẹ, ṣugbọn o ṣalaye pe ọkọ oun yipada nigba tawọn ọrẹ ati ẹbi ko si i ninu.

Awọn eeyan n tabuku mii tori mo bimọ nipa eto ‘’surrogacy’’

Arabinrin Ejiovi tun sọ fun BBC Yoruba wi pe ọpọ eeyan lo ti tabuku oun nitori oun ṣe ‘surrogacy.’’

O ni ‘’eleyii ṣẹlẹ tori ọpọ eeyan ni ko mọ nipa fifi eto ‘surrogacy’ bimọ.

Awọn ẹbi ati ọrẹ ọkọ mi gan an tabuku mi tori obinrin mii bami gbe oyun ati bimọ.

Lakọkọ, awọn eeyan kọkọ dunnu fun mi, ṣugbọn ọpọ eeyan lo maa fẹ ri pe obinrin gbe oyun fun ra rẹ ki o to le bimọ.

Ọpọ ọdun ni mo ti gbe niluu oyinbo, mo si wa lati idile awọn to kawe daadaa.

Ṣugbọn awọn eeyan bẹrẹ si beere wi pe nibo ni mo ti ri ọmọ, bayii ni mo bẹrẹ si ṣalaye fun wọn nipa ‘surrogacy’.

Fun idi eyi o ṣe pataki ki awọn eeyan mọ nipa fifi eto ‘surrogacy’ loyun ati bimọ ni Naijiria.

Amọ, idunnu mi ni pe emi naa ti di iya ọlọmọ pẹlu gbogbo ohun ti mo ti la kọja.

Ni bayii, inu mi dun tori mi kii ṣe ajẹ mọ bayii