Ẹ yé ná owó náírà lójú agbo mọ́ kí ẹ má baà dèrò ẹ̀wọ̀n, Bobrisky kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/X
Bobrisky gba awọn ololufẹ rẹ nimọran lati maṣe tapa si ofin owo nina loju agbo.
O ni “ẹ ni lati tẹle ofin o, ẹ ma na owo loju agbo mọ, bi bẹẹ kọ, ẹ maa lọ di onile ninu ọgba ẹwọn ni o.
“Kii ṣe ipaniyan tabi iwa ọdaran nikan lo maa n sọ eeyan di ero ẹwọn, nnkan kekere ti ko jọ eeyan loju le sọ ẹni dero ẹwọn.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ awọn ọrẹ ati ololufẹ to duro tii lasiko to lọ ṣẹwọn.
Wo bí ayẹyẹ ìpadàbọ̀ Bobrisky láti ọgbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri ṣe lọ nínú ọkọ̀ ojú omi l’Eko

Oríṣun àwòrán, @Olamide0fficial/X
Oniruuru awọn alẹnulọrọ ati ilumọọka lo peju pesẹ sibi ayẹyẹ ipadabọ Idris Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky niluu Eko lẹyin to gbominira lọgba ẹwọn Kirikiri niluu Eko lana ọjọ Aje.
Ni ikan bii wakati diẹ lẹyin to gbominira tan ni fidio kan lu ori itakun ayelujara X pa eyi to ṣafihan Bobrisky, ati oṣere tiata, Eniola Ajao ati ẹnikan ninu ọkọ nibi ti Bobrisky ti n kawọn ololufẹ rẹ.
Ni ọwọ irọlẹ ọjọ Aje ni fidio mii tu lu ori ayelujara pa ninu eyi ti Bobrisky atawọn ọrẹ rẹ ti n ṣe ajayọ ninu ọkọ oju omi.
Lara awọn gbajumọ to wa pẹlu Bobrisky ninu ọkọ oju omi ọhun ni oṣere tiata, Eniola ati Moyo Lawal.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bobrisky gba ìtúsílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ohun tó sọ bó ṣe ń jáde rèé

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Gbajumọ ọkunrin to maa n mura bii obirin, Idris ‘Bobrisky’ Okuneye, ti gba itusillẹ lọgba ẹwọn lẹyin oṣu mẹfa.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni adajọ Abimbola Awogboro sọ Bobrisky sọgba ẹwọn lẹyin to jẹbi ẹsun ṣiṣe owo naira baṣubaṣu.
Fidio kan to ti milẹ titi lori ayelujara ṣafihan bi ọkunrin ọhun ṣe n dunnu lẹyin to gba itusilẹ tan.
Ọrọ to kọkọ jade lẹnu rẹ bo ṣe ti ẹwọn de ni “bawo ni o ẹyin temi, iya Eko lo n ba yi sọrọ o... mo ti saaro yin gidi... mo nifẹ yin gidi.”
Ṣe lóòtọ́ọ́ ni Bobrisky ti kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, @zxenergyy/X
Ṣe lóòtọ́ọ́ ni Bobrisky ti kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri? Ohun tí a mọ̀ rèé
Iroyin to tẹ wa lọwọ lo sọ pe gbajumọ ori itakun ayelujara, Idris Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky ti gbominira lọgba ẹwọn.
Adajọ Abimbola Awogboro ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Eko lo sọ Bobrisky si ẹwọn oṣu mẹfa laisi anfani faini sisan lori ẹsun pe o ṣe owo naira ni iṣekuṣe.
Ajọ EFCC to gbe Bobrisky lọ ile ẹjọ sọ pe o tabuku owo naira nibi ti o ti n fi owo mọri loju agbo.
Amọ, laarọ ọjọ Aje ni fidio kan eyi ti Bobrisky ati Eniola Ajao wa ninu rẹ lu ori ayelujara pa paapa julọ oju opo X.
Bobrisky sọ ninu fidio naa pe ‘’mo ti ṣafẹri ẹyin eeyan mi gan an.
Mi o le duro lati ri pade gbogbo yin ki n si bẹrẹ si fun yin ni awọn nkan ti mo maa n fun yin tẹlẹ.
"Ile ẹjọ fun mi ni ijiya to pọ julọ fun ẹsẹ ti mo ṣẹ tori n ko ni akọsilẹ kankan tẹ́lẹ̀ bii arufin"

Oríṣun àwòrán, @zxenergyy/X
Ṣaaju idajọ yii lọjọ karun un, oṣu Kẹrin ọdun yii naa ni ọda Bobrisky ti kọkọ sọ pe oun jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan oun.
Ninu iwe ipẹjọ kotẹmilọrun rẹ, ọdaran naa sọ pe ile ẹjọ fun oun ni ijiya to pọ julọ fun ẹsẹ ti oun ṣẹ bo tilẹ jẹ pe oun ko ni akọsilẹ kankan ṣaaju iṣelẹ naa gẹgẹ bii arufin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, idajọ ọhun waye lai si oju aanu kankan fun oun, eyii ti ko si ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin Administration of Criminal Justice, ACJA, ti orilẹede Naijiria.
O fi kun pe adajọ naa ko tun wo ti pe oun ko fi akoko ile ẹjọ ṣofo latari bi oun ṣe tete sọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.















