Wo ìdí tí kò fi lè sí òṣìṣẹ́ ìjọba kankan tí yó gba ₦70,000 tí Ààrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ búwọ́lù
Taani yóò jẹ ànfààní owó oṣù tuntun?
Laipẹ yii, ni ile Igbimo aṣofin agba buwọ lu iwe ofin owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ lati ori ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira to wa tẹlẹ lati 2019 si ẹgbẹrun lọna aadọrin naira.
Eyi lo n waye lẹyin adehun ti ijọba apapọ ṣe pẹlu apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC leyin ọpọlọpọ ifẹhonuhan ati idunadura.
Wo idahun si ohun ti awọn eeyan n beere nipa rẹ bayii!.......
Ki ni owo oṣu to kere julọ?
Ki ni owo oṣu to kere julọ?
Owo oṣu to kere julọ ni owo oṣu ti oṣiṣẹ kan gbọdọ mu dele ni ipari oṣu, lẹyin to ba ti ṣiṣẹ.
Bẹẹ, ko gbọdọ ja kọja iye ti ijọba fọwọ si, gẹgẹ bi onimọ nipa iṣẹ ati ẹtọ awọn oṣiṣẹ Ulari Nwaogazie ṣe ṣalaye.
Owo yii naa ni ajọ International Labour Organisation tun ṣapejuwe gẹgẹ bi iye to kere ju ti olugbanisiṣẹ gbọdọ san fun oṣiṣẹ rẹ lasiko ti wọn jọ ṣe adehun, eyi ti ko ṣee dinku.
Ki ni oṣiṣẹ ijọba yoo gba bayii?
Ki ni oṣiṣẹ ijọba yoo gba bayii?
Ninu iṣẹ ijọba, ẹgbẹrun lọna aadọrin naira ni owo ti oṣiṣẹ to wa ni ipele kinni, akasọ kinni yoo gba nigba ti wọn ba ti gba a siṣẹ.
Ṣugbọn Akin Alabi to jẹ aṣofin nipinlẹ Oyo sọ pe “ko si ẹnikankan ni ipele naa mọ.” Eyi lo si tumọ si pe gbogbo oṣiṣẹ yoo gba ju iye owo yii lọ.
Olukọni ni fasiti ipinlẹ Port-Harcourt, Ọmọwe Stephen Anurudu sọ pe owo oṣu tuntun yii yoo kan fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira kun owo oṣu t’oun n gba bayii ni. Bẹẹ, ko to ra nkan lọja lasiko yii.
Awọn wo ni yoo jẹ anfaani owo oṣu to kere julọ yii?
Gbogbo oṣiṣẹ ni ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ ni wọn ni anfaani lati gba owo oṣu tuntun to kere julọ yii.
Muhammad Mansur Aliyu, agbẹjọro ati olukọni ni ẹka ikẹkọọ imọ ofin ni fasiti Usman Danfodio ni ipinlẹ Sokoto ṣalaye pe, “awọn ẹka iṣẹ bii ijọba apapọ, ile ifowopamọ, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ ni wọn wa labẹ ofin yii, gẹgẹ bi aṣẹ to wa lọwọ ile igbimọ aṣofin agba nipa iwe ofin.”
Awọn wo ni ko ni lanfaani si ẹkunwo owo oṣu tuntun?
Awọn ẹka iṣẹ kan leṣalai janfani owo oṣu tuntun yii.
Alabi, agbẹjọro tun tọka si abala ofin tuntun pe:
Awon bii awọn oṣiṣẹ ti wọn n gba owo nipa iṣẹ ti wọn ba ṣe, awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ati okoowo kerejekereje ati awon Ileeṣẹ ti wọn ko ni to oṣiṣẹ marundinlọgbọn.”
Ju gbogbo rẹ lọ, Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ti sọ pe owo oṣu tuntun naa kan awọn ọmọ ọdọ, ati awakọ aladani.
Njẹ owo oṣu tuntun yii yoo ṣe ipalara fun awọn ileeṣẹ aladani?
Bẹẹni ati bẹẹkọ.
O ṣee ṣe ki awọn ileeṣẹ nlanla to n san owo to kere si owo oṣu to kere julọ ṣe afikun lori owo oṣu wọn nigba ti ofin naa ba bẹrẹ sii fẹsẹ mulẹ.
Ṣugbọn awọn to ti fowo kun owo oṣu wọn kọja iye ti jọba gbe e si ko tun nilo lati ṣe bẹẹ mọ.
Bawo ni owo ọya awọn agunbanirọ yoo ṣe wa ri?
Lawọn ọdun to kọja, awọn agunbanirọ n ba owo oṣu to kerejulọ pẹlu idamẹwaa owo naa. Nigba ti owo oṣu to kere julọ wa ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, awọn agunbanirọ n gba ẹgbẹrun lọna ọgun din nigba (N19,800) naira.
Nigba ti owo oṣu to kere julọ wa ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn, ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn naira ni wọn n gba. Bi eyi ba ṣi n lọ bẹẹ, o ṣee ṣe ki awọn agunbanirọ gba ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin naira gẹgẹ bi owo oṣu tuntun ṣe jẹ ẹgbẹrun lọna aadọrin naira.
Oṣiṣẹ kan nileeṣẹ to n ri sọrọ awọn agunbanirọ, ẹni to fẹ ka fi orukọ bo oun laṣiri sọ fun BBC pe ilana owo awọn agunbanirọ nipa eto owo oṣu tuntun wa lọwọ Aarẹ.
Awọn ipinlẹ wo ni wọn ko tii bẹrẹ sii san ẹgbẹrun lọna ọgbọn, owo oṣu to kereju tẹlẹ?
Gẹgẹ bi abajade iwadii ti ajọ BudgiT gbe jade ni akasọ kẹrin ninu ọdun 2023, wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ipinlẹ mẹrinla ni wọn ko san owo oṣu to kere julọ ti ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lati ọdun 2019.
Awọn ipinlẹ naa ni: Abia, Bayelsa, Delta, Enugu, Nasarawa, Adamawa, Gombe, Niger, Borno, Sokoto, Anambra, Imo, Benue, ati Taraba.
Amofin Aliyu sọ pe itapasofin nla ni iwa yii to si yẹ ki awọn aṣofin pe fun iyọnipo awọn gomina ọhun.
“Awọn ajọ araalu naa le gbe igbesẹ ofin lati fẹsun kan awọn gomina, pẹlu aṣẹ lati bẹrẹ sii tẹle iwe ofin,” Aliyu sọ bẹẹ.
O tun sọ pe awọn oṣiṣẹ ti wọn ba n gba owo to kere si owo oṣu to kere julọ le gba ile-ẹjọ lọ lati sọ ẹdun ọkan wọn.
















