SERAP gbé banki àpapọ̀ Nàìjíríà CBN lọ ilé ẹjọ́ lórí N100bn tó dọ̀tí 'tí CBN ò lè sọ ibi tó wà'

Oríṣun àwòrán, Central Bank of Nigeria/Instagram
Ajọ ajafẹtọọ ati abojuto iṣẹ akanṣe, SERAP ti wọ banki agba ilẹ Naijiria, CBN lọ sile ẹjọ lori ẹsun wi pe wọn ko le ṣakọsilẹ bi awọn owo aloku to to ọgọrun kan biliọnu naira ṣe poora.
SERAP sọ pe CBN kọ lati ṣalaye bi owo ọgọrun kan biliọnu naira naa ṣe di awati lakolo wọn, ti wọn si ni eyi ko bojumu to.
Ile-ẹjọ giga to wa nipinlẹ Eko ni ajọ SERAP wọ CBN lọ ninu iwe ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ FHC/L/MSC/441/2024, nibi ti wọn ti n rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun CBN lati sọ bi awọn owo aloku ti ko dara mọ, ati awọn eyi to ti dọti ṣe ṣe e.
Bakan naa ni SERAP tun n beere fun awọn owo nla miran ti wọn n duro lati ṣayẹwo wọn, eyi ti wọn ko pamọ sawọn ẹka ile ifowopamọ agba kaakiri Naijiria lati ọdun 2017 titi di asiko yii.
Siwaju sii ni CBN tun rọ ile-ẹjọ naa lati paṣẹ fun CBN, ki wọn ṣalaye bi biliọnu meje le diẹ (N7.2bn) naira to fun kikọ ẹka banki naa niluu Dutse lọdun 2010, ati biliọdun marun din diẹ (N4.8bn) naira to yẹ fun atunṣe ni ẹka to wa niluu Abẹokuta lọdun 2009, ati pe wọn ni lati fi orukọ awọn agbaṣẹṣe ti wọn gbe iṣẹ fun sita.
SERAP nigba ti wọn n tẹsiwaju ninu iwe ẹsun naa tun ṣalaye pe awọn fẹ ki ile-ẹjọ paṣẹ fun CBN lati ṣalaye bi biliọnu kan le nigba (N1.2bn) naira ti wọn ya ijọba ipinlẹ Enugu lọdun 2015 ṣe poora, ati biliọnu meji din diẹ (N1.9bn) naira ti wọn ya ipinlẹ Anambra laarin ọdun 2015 ati 2016 ṣe rin in.
Wọn sọ pe bi CBN ba le ṣalaye ibi ti awọn owo ilu wọnyi wa, ti wọn si forukọ awọn ti wọn fura si lori iwa jẹgudujẹra yii sita lati fi wọn jofin, yoo fopin si gbogbo awọn to n ko owo ilu jẹ, ti wọn si n ro pe ko sẹni to le bi wọn leere.
Bakan naa ni wọn tun jẹ ko di mimọ pe iwa titapa si igbagbọ araalu ninu awọn ti wọn n yan sipo jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ, ati pe ijiya gbọdọ wa.















