Irọ́ ni pé obìnrin ló fa ìpínyà láàárín èmí àti Arugbá àmọ́... - Damola Olatunji

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajugbaja oṣerekunrin nni, Damola Olatunji ti sọ pe oun ko le gbagbe ọjọ ti iyawo afẹsọna oun nigba kan ri loyun fun ọkunrin miiran.
O ni ọjọ naa jẹ manigbaegbe fun nitori o bu omi tutu soun lọkan.
Damola Olatunji lo sọ eyi lasiko to kopa lori eto kan ti oṣerebinrin, Biola Bayo pe ni ‘Talk to B’ n ṣe agbatẹru rẹ.
Olatunji gba awọn ọdọ lamọran nipa iriri lori ọrọ ibadọrẹ laarin ọkunrin ati obinrin.
O sọ pe o ku bi ọsẹ diẹ ki eto mọmi-n-mọ ẹ laaarin awọn ẹbi oun pẹlu ololufẹ oun igba naa ni oun ṣakiyesi pe ọmọbinrin naa ti loyun fun ọkunrin miiran.
“Mo le fi ọrọ aye mi ṣe apẹẹrẹ to ba di ọrọ ibadọrẹ, nitori pe mo ti ni iriri to pọ. Ninu ibadọrẹ kan ti mo ni sẹyin, ololufẹ ti mo n fẹ nigba naa loyun fun ọkunrin miiran nigba to ku bi ọsẹ meloo kan ka ṣeto mọmi-n-mọẹ.
“Mo dakẹ, mi o sọrọ, iyẹn si lọ bẹẹ. Mo ti ni oriṣiriṣi iriri bẹẹ, koda lẹnu iṣẹ ti mo yan laayo. Gẹgẹ bi ọkunrin to n la kaka lati jẹ eeyan, mo ti ni irirri to pọ, bẹẹ si ni gẹgẹ bi baba, mo ti ni iriri.”
Bakan naa nigba to n sọrọ nipa boya oun pẹlu Bukọla Awoyẹmi ti ọpọ mọ si Arugba yoo tun pada di lọkọ-laya lẹyin ti wọn pinya, o sọ pe Ọlọrun nikan lo le dahun ibeere naa.
Olatunji sọ pe oun ko le sọ, ṣugbọn to ni ohun to ṣe pataki julọ soun ni igbesi aye awọn ọmọ oun to wa lọwọ Bukọla, to si ni gbogbo igba loun n ṣe gbogbo ẹtọ to yẹ gẹgẹ bii baba lori wọn.
O tun fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ igba loun ti gbe awọn ọmọ naa jade lati ra nnkan fun wọn, koda pẹlu Bukọla funra rẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu karun-un, ọdun 2023 ni Damola Olatunji ati Bukola Awoyemi to bi ibeji fun un pinya gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo, ti awọn mejeeji ko si sọ ohun to fa ija tabi aawọ laarin wọn.
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi iroyin lo jade nipa awọn mejeeji, paapaa nipa Damola, leyii ti wọn n sọ pe o ti ba obinrin miiran lọ, ọkunrin naa sọ pe irọ to jinna si otitọ ni.
O sọ pe iwoye awọn ti ko mọ nipa wọn, ṣugbọn ti wọn n fẹ mọ dandan ni ayederu iroyin ti wọn n gbe kaakiri nipa oun.
O wa fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ayederu iroyin naa ni wọn n wa koun sọrọ si, lati le sọ tẹnu oun, ṣugbọn to sọ pe oun ko jẹ ẹnikẹni ni ọrọ tabi alaye nipa igbesi aye oun.















