Àbọ̀ ìpàdé Tinubu, àwọn gómìnà, ọba alayé àtàwọn olórí ẹ̀sìn rèé lórí ìwọ́de tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency/X
Bi ọjọ ṣe n sun mọ diẹ diẹ si ọjọ kinni oṣu kẹjọ tawọn eeyan kan n gbero láti ṣe ifẹhonuhan 'ebi n pa wa' kaakiri orilẹede Naijiria ni Aarẹ Bola Tinubu n ṣe oniruuru ipade pẹlu awọn gomina, ọba alaye, awọn olori ẹsin at'awọn mii tọrọ kan.
Oniruuru ipade yii tun waye lana Ọjọ́bọ̀ niluu Abuja.
Aarẹ ṣe ipade pọ pẹlu awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC, awọn ọba alaye, at'awọn olori ẹsin.
Awọn lọbalọba sọrọ nipa iwọde to n bọ nibi ipade pẹlu Tinubu
Awọn ọba alaye ti parọwa fawọn to n gbero lati ṣe ifẹhonuhan lori bi nnkan o se fararọ ni Naijiria bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu kẹjọ to n bọ wi pe ki wọn jeburẹ.
Awọn ọba alaye sọrọ yii lẹyin ipade wọn pẹlu Aarẹ Tinubu l'Ọjọbọ niluu Abuja.
Dein ilu Agbor, Alayeluwa Benjamin Keagborwkuzi okun ati agbara orile-ede Naijiria wa lọwọ rẹ ọdọ.
"A mọ nipa inira ti ẹ n la kọja, tori ọdọ ni emi naa.
O ti to ọdun mẹrinlelogun ti mo ti woye pe nnkan ti n daru lorilẹede yii.
Ṣugbọn ẹ ma jẹ ka fi iwọde yii ba orilẹede wa jẹ."
Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi toun naa wa nibi Ipade ọhun rọ awọn to fẹ ṣe iwọde wi pe ki wọn kiyesara k'awọn janduku ma baa já iwọde naa gba mọ wọn lọwọ.
"Awa ọba sun mọ awọn eeyan daadaa.
A tun ma tẹsiwaju lati maa b'awọn sọrọ tori ko rọrun lati kọ nnkan, amọ, o rọrun lati ba nnkan jẹ.
Gbogbo lọrọ Naijiria kan, gbogbo wa si ni a ni ipa kan tabi omiran lati ko ni idagbasoke rẹ," Ooni lo sọ bẹẹ.
Ipade Tinubu pẹlu awọn olori ẹsin
Aarẹ Tinubu sọ fáwọn olori ẹsin to ṣe ipade pọ pẹlu lana Ọjọbọ niluu Abuja pe oun ṣe ijọba lati ṣegbe lẹyin awọn eeyan kan ti wọn ṣe atilẹyin foun lati wọle ibo.
Tinubu fidi rẹ mulẹ fun wọn pe owo oun loun lo fun ipolongo ibo, ati pe ko si ẹnikan toun maa jabọ fun tabi ti oun jẹ nigbese.
Aarẹ ni iwọde to n bọ yii le da rogbodiyan silẹ eyi to le mu ifasẹyin ba orilẹede Naijiria.
Tinubu ni awọn to n ṣagbatẹru iwọde yii ko ni ifẹ orilẹede Naijiria lọkan.
"Imọtara ẹnikan lo dawon to fẹ ṣe iwọde yii laamu.
Ọpọ ninu wọn lo jẹ ọmọbibi orilẹede mii yatọ si Naijiria.
Awọn eeyan yii wa kaakiri orilẹede agbaye ti wọn si n se ipade lori ayelujara.
A o fẹ ki Naijiria dabi orilẹede Sudan.
A le maa sọ nipa ebi ni tootọ, amọ, kii ṣe nipa bibo oku awọn eeyan mọlẹ.
A ni lati ṣọra gidi gan an ki iwọde yii maa
ba di nnkan mii.
A ti n ṣiṣẹ lori eto bi iranwọ yóò ṣe de ọdọ gbogbo ọmọ Naijiria ni wọọdu kookan.
Ẹ ma gbagbe pe ijọba tun ṣẹṣẹ ṣe ẹkunwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ pẹlu ida ọgọrun un.
Nitori naa, ọrọ ọhun gba suuru," Tinubu lo sọ bẹẹ.
Tinubu ṣe ipade pẹlu awọn gomina APC

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/X
Aarẹ orilẹede Naijiria tun ṣe ipade pọ pẹlu awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC naa ni Ọjọbọ.
Nile iṣẹ ijọba ni ipade ohun ti waye niluu Abuja.
Gomina ipinle Imo, Hope Uzodimma, to jẹ alaga awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ati Gomina AbdulRazaq AbdulRahman ipinlẹ Kwara to jẹ alaga awọn gomina ni Naijiria lo ṣaaju awọn gomina lọ sibi ipade ọhun pẹlu aarẹ.
Gomina Uba Sani ipinlẹ Kaduna, Francis Nwifuru ti Ebonyi ati Hyacinth Alia ti ipinlẹ Benue naa wa lara awọn gomina to nibi ipade ọhun.
Aarẹ lo ipade ọhun pẹlu awọn gomina lati le b'awọn to n gbero lati ṣe ifẹhonuhan sọrọ ki wọn le wọgile iwọde ọhun.















