Wo eléré ìdárayá márùn ún tí yóò gbé ògo Nàíjíríà ga nínú ìdíje 2024 Olympics

Olympics

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2024 ni idije Olympics yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Naijiria wa lara awọn orilẹede agbaye ti yoo kopa ninu idije naa nibi ti wọn yoo ti maa figagbaga ninu oriṣiriṣi ere idaraya.

Ọdun 1964 ni Naijiria kọkọ gba ife ẹyẹ ni idije Olympics niluu Tokyo, ni Japan nigba ti Nojeem Mayegun gba idẹ ninu ẹṣẹ kikan.

Ninu ere bọọlu, Atlanta 1996 ni igba ti ikọ Super Eagles fi oju ikọ Brazil ati Argentina gbolẹ lati gba ife ẹyẹ wura.

Awọn ọmọ Njaijiria ti igbagbọ wa pe awọn naa yoo fakọyọ ninu idije Paris 2024 ree.

Tobi Amusan

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Asare ori ọdan ni Tobi Amusan lati ilu Ijebu Ode, nipinlẹ Ogun.

Amusan lo wa loke tente idije ere sisa ‘100m hurdles’ kaakiri agbaye.

Asisat Oshoala

Asisat Oshoala

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bọọlu afẹsẹgba ni Asisat n gba fun ikọ Super Falcons ti Naijiria.

Lọwọlọwọ, oun ni agbbọọlu obinrin to lamilaka julọ nilẹ adulawọ.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n fi ireti wọn sinu Asisat ninu idije Olympics ọdun yii.

Anuoluwapo Opeyori

Anuoluwapo Opeyeri

Oríṣun àwòrán, BADMINTON CONFEDERATION AFRICA

Anuoluwapo Opeyori, ọba ere idaraya ‘badminton’ nilẹ adulawọ yoo tun ṣoju Naijiria ninu idije Olympics niluu Paris, ni France.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ atapata dide ni lati ilu Eko, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa ti gba ife ẹyẹ mẹrin ọtọtọ, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ ni Afrika.

Ohun to mu ki aṣeyọri Opeyori ṣe pataki ni pe o wa lati Naijiiria, to jẹ orilẹede ti ko fi bẹẹ ka ere idaraya badminton si.

Ninu ifọwerọ pẹlu BBC, o ni “afojusun mi ni lati de ipele komẹsẹ-o-yọ ninu idije naa nitori mo mọ pe ti mo ba le bori ninu ifẹwọnseọ naa, mo ti di ẹrujẹjẹ si awọn to ti wa niwaju tẹlẹ lọrun, amọ mo gbagbọ pe mo le kọja ipele naa.

Ese Brume

Ese Brume

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni Brume to n dije ninu ifẹwọnsẹ ‘long jump.’

Lọwọ yii, ọwọ rẹ ni ade idije Commonwealth wa, o si ti gba ade nigba mẹta ọtọtọ gẹgẹ bii ẹni fakọyọ julọ nilẹ adulawọ.

Chukwuebuka Enekwech

Ọmọ Naijiria ni Chukwuebuka Enekwech bo tilẹ jẹ pe Queens, nilu New York l’Amẹrika ni wọn bi si.

O wa lara awọn to maa n ju irin ‘shot put’ ninu idije Olympics.

Lọdun 2018, o gba ife ẹyẹ fadaka ninu idije Commonwealth, oun si lo fakọyọ julọ ninu ‘shot put’ jiju nilẹ adulawọ.