Olaitan Adam Olaore: Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó ń kópa nínú èré ìdárayá Olympics, tó fi Anthony Joshua ṣe àwòkọ́ṣe

Aworan Adam Olaore
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gẹgẹ bi akikanju abẹsẹkubiojo to jantọ ni ilẹ Afirika, Olaitan Adam Olaore yoo ma kopa ninu idije Olympic fun igba akọkọ, ẹni ọdun mejilelogun ni o ti yan Anthony Joshua, ẹni to ti gba ife ẹyẹ ni igba meji gẹgẹ bi awokọse rẹ.

Bi o ti lẹ jẹ pe o jẹ eeyan to ni orisun pẹlu Naijiria ati Ilẹ Gẹẹsi,.

Ọpọ eeyan lo gba goolu ninu idije Olumpic niluu London ni ọdun 2012.

Wọn bi ni ilu Eko ni ọdun 2002, Olaore kuro pẹlu ẹbi rẹ ni ọmọ ọdun mẹfa lọ si Ile Gẹẹsi, o jawe olu bori ninu idije Amateur ti orilẹ-ede Gẹẹsi ni ọdun to kọja - gẹgẹ bi Joshua, ẹni to bẹrẹ ile- ẹkọ akọkọ rẹ ni Naijiria ṣe ṣaaju rẹ.

Lẹyin ọdun mẹdogun ni Ilu UK - idile rẹ duro si Ilu London ṣaaju ki wọn to gbera lọ si lọ si Newcastle ni ọdun 2014 – jijẹ ipe Naijiria fun Olaore ba irọrun de lọdun to kọja.

“N ko ni iwe igbelu Ilẹ Gẹẹsi, nitori alejo ni mi, ti n kii ṣe ọmọ ilu Gẹẹsi,” o sọ fun BBC Grassroots to Glory.

“Lati kan ẹsẹ fun ilu Gẹẹsi, mo ni lati duro fun igba diẹ - ṣugbọn kikan ẹsẹ jẹ ere idaraya fun ọdọmọkunrin, nitori n ko mọ bi yoo ṣe pẹ to.

“A ni anfani lati ṣoju Naijiria, eyiti gbogbo ẹgbẹ ro pe ọna to tọ lati tọ ni.”

Olaore jawe olubori ni ile Afirika ninu idije agbaye akọkọ rẹ.

Ko si abẹsẹkubioju ọmọ Naijria kankan ti o dije ni Tokyo 2020, Olaore ni lati bori kopa ni idije Paris 2024 ni Oṣu Kẹsan ọdun to kọja, to si tun kopa nini idije ilẹ Adulawọ ni ibẹrẹ ọdun yii.

Aṣeyọri rẹ paapaa jẹ iwunilori nigba ti o pinnu lati jẹ abẹsẹkubioju ipele heavyweight lẹyin ti igbimọ to n risi idije Olympic wọgile ipele to ni fẹ si.

Iriri nla

Aworan Adam Olaore ninu aṣọ pupa

Oríṣun àwòrán, NEIGHBOURHOOD | NBHD GROUP

Odun 1964 ni orilẹede Naijiria kọkọ gba ami ẹyẹ goolu ni idije Olympic ni di ere abẹsẹkubiojo. Marun un mi tun tẹlẹ ni ọdun 1996 ti wọn si sarajọ ni apapọ. Olaore ni oju rẹ wa lara goolu, ti o si n gbaradi fun.

O ṣalabapade ere idaraya yii ni ọmọ ọdun mẹrinla nigba ti ọrẹ rẹ ri ibi ere idaraya kan ti wọn ti n gbe irin nigba ti wọn jọ n rin kiri ni ilu rẹ, to si bẹrẹ si ni ma nifẹ si, to si n gba ami ẹyẹ..

“Mo ni idaniloju pupọ - arọwọto mi, iyara mi, idakẹjẹ mi ninu irin. Mo gbagbọ nigba gbogbo pe onija idakẹjẹ pe gbogbo ogun lo le ṣẹ. Pupọ ninu awọn onija ma ja ija gboro sugbọn ti o ba ni suuru to, ko si wahala.”

Olaore gba ami ẹyẹ rẹ akọkọ nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun, oṣu mẹfa lẹyin ti o bẹrẹ si ma gbaradi ni ile-idaraya ni to si Newcastle.

Olaore ṣalabapade Richard Stoneham ni Ile-ẹkọ giga Howdon Boxing ni Newcastle, nibiti o ti dije ninu ija mejila ati aṣekagba national meji ni saa akoko gẹgẹ bi akẹkọ to ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Lẹyin naa ni Olaore gbera lọ si Ile-ẹkọ Empire Boxing ni Blyth, ilu eti okun ọgbọn kilomita ni ariwa Newcastle nibi ti o ti gba ẹkọ labẹ Stoneham ati olukọni Les Welsh.

“Mo ni idaniloju pe gbogbo eniyan ni Howdon ati Blyth yoo pariwo si ẹrọ momaworan wọn,” Welsh sọ asọtẹlẹ fun Olaore.

“Awọn agbegbe mejeeji nilo igbega, nitori naa inu wa dun. Itan nla ni. Lati jẹ ki Adam sisẹ pọ pẹlu Naijira, yoo ni lati jẹ ẹbun lati ọrun.”

Asa ilẹ Afirika

Boxing champion Anthony Joshua in Nigeria

Oríṣun àwòrán, AJ BOXING FAN CLUB

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Titi di Oṣu Kẹrin ọdun 2023, Olaore tẹsiwaju lati ma moke to si n gba ami ẹyẹ abẹsẹkubioju ilẹ adulawọ, paapa ni Yaounde, to jẹ olu ilu Cameroon.

Lẹyin oṣu kan ,Olaore koju akẹgbẹ rẹ lati orilẹede Ivory Coast , Senegal, Morocco ati Algeria lati ri pe abẹsẹkubiojo ọkunrin lati orilẹede Naijiria kopa ninu idije African Games lati ọdun 2016.

Ni Oṣu Kẹta, Olaore gba ami ẹyẹ fun igba kẹta ni idije Afirika kẹta ni Ghana, nibiti o ti lo iriri rẹ nidi ija lati bori awọn akẹgbẹ ni agbegbe Accra's Bukom.

Awọn idije yii ti fun un ni anfani lati pada si ibi to n pe ni ile tẹlẹ.

Olaore sọ pe “Mo ti pada wa ni ọpọ gba ni aarin ọdun kan, ti mo si ti ri awọn mọlẹbi - o jẹ nnkan to wuwọn lori pupọ.”

Olaore, ẹni to n pe ara rẹ ni "ọdẹ", sọrọ nipa ero rẹ lati gba goolu to si fẹ fi kun awọn ami ẹyẹ ti Nijiria ti gba saaju

“N ko fẹ ni ero pupọ nitori o le dawo. Mo n gbajumọ lilọ idije Olympic, lati mọ nipa nnkan to n bọ, ki n to wa mu iṣẹ abẹsẹkubiojo ni ọkunkundun

“Mo ni iṣẹ lati se , ti mo n gbaradi fun idije Olympic, ti n kọ ni je ki inu mi dun ju.