Ooni gbé ìgbésẹ̀ ọ̀tun lórí ẹ̀sùn jìbìtì owó àti ti ìgbéyàwó tí wọ́n fi kàn-án

Ooni Ile-Ife

Oríṣun àwòrán, Ooni Ile-Ife/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aafin Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi Ojaja Keji, ti fa ọrọ awọn eeyan to wa nidi awọn iroyin ibanilorukọjẹ to n lọ nipa rẹ lori ayelujara, sun awọn agbofinro.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Ooni Adeyeye, Oloye Moses Olafare, fi sita l'Ọjọru ni Ooni ti ṣapejuwe awọn eeyan naa gẹgẹ bii oniwa ọdaran.

Atẹjade yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti Ooni ti kọkọ sọ ninu ikede kan pe ayederu iroyin lati ta ẹrọfọ si aṣọ aala ati iyi oun ni.

Oloye Olafare sọ pe yatọ si pe Ooni sọ pe ẹsun naa kii se otitọ, o ni oun kii ni ibaṣepọ pẹlu ẹnikẹni lori ayelujara tabi ran ẹnikẹni lati ṣoju oun ninu iru ibaṣepọ bẹẹ.

"Gẹgẹ bi a ṣe ṣe ileri ninu atẹjade akọkọ, Aafin ti fi ẹjọ naa to foju han pe ibanilorukọjẹ ati idunkooko, sun awọn oṣiṣẹ eleto aabo fun iwadii ati fifi iya jẹ awọn to wa nidi rẹ labẹ ofin."

"Aaye wa fun ẹnikẹni lati ṣe iranlọwọ lori bi ọwọ yoo se tẹ Arabinrin Fagbuyi ti wọn ni Ooni lu ni jibiti"

Aafin Ooni tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ẹri eke ni ayederu iwe ti wọn n pin kiri lori ayelujara, eyi to ni agbelẹrọ ibuwọlu Ori Ade naa lati gbe 'irọ buruku' wọn lẹsẹ.

" Eyi kọja awada, a si ni idaniloju pe aṣiri awọn ọdaran naa fun ijiya labẹ ofin."

Yatọ si eyi, Olafare sọ pe aafin tabi Ooni, ko bẹ ẹnikẹ́ni lọ́wẹ̀ lati maa ṣe alarina laarin rẹ ati awọn abanilorukọjẹ naa.

O ni wọn o fa ẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n ṣe bẹẹ le awọn agbofinro lọwọ, gẹgẹ bi agbodegba iwa ọdaran.

Ṣugbọn ṣa, 'aaye wa fun ẹnikẹni to ba ṣe iranlọwọ lori bi ọwọ yoo se tẹ Arabinrin Fagbuyi ti wọn ni Ooni lu ni jibiti, ati alatilẹyin rẹ, to n lo oju opo ayelujara "99% OPPRESSED" lori X, lati fi to aafin tabi ileeṣẹ alaabo leti'.

@PIDONIFERIA 99% OPPRESSED lo sọ lori itakun ayelujara X ni Ọjọru pe, Ooni lu obinrin kan, Fagbule, to jẹ dokita to ti n ṣiṣẹ lorilẹede Amẹrika fun bi ọdun mẹrindinlogun ni jibiti $180,000 lori idokowo, dukia ati ileri lati fi ṣe aya.

Obinrin ọhun ti wọn ni o wa lati Ile-Ife,ipinlẹ Osun ni a gbọ pe o n gbero lati da ile iwosan silẹ kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ lati ipinlẹ Osun to jẹ orirun rẹ.

Eyi ni 99% OPPRESSED ni o fẹ bẹrẹ nipa pipese iwosan ọfẹ fawọn obinrin atawọn ọmọde niluu Ile-Ife ki o to pada da ile iwosan silẹ nibẹ.

Bawo ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ gan an?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin iwadii rẹ nipa bi o ṣe le ṣe agbekalẹ eto yii ni wọn sọ fun un wi pe ko kan si Ooni lọri ọrọ naa.

99% OPPRESSED ni bayii ni obinrin yii kan si Ooni lori Facebook ti o ṣi ṣalaye ohun to fẹẹ ṣe fun kabiesi.

Iroyin sọ pe Kabiesi naa ni gbolohun pẹlu rẹ wi pe oun ṣetan lati ṣe iranwọ fun un lori ohun to fẹ ṣe niluu Ile-Ife.

Koda, wọn ni Kabiesi gba a ni imọran pe ko da ile iwosan naa silẹ lopopona ilu Ibadan si Eko tori bi ijamba ọkọ ṣe maa n ṣẹlẹ nibẹ ni gbogbo igba.

"Bayii ni arabinrin yii bẹrẹ sii fi owo ranṣẹ si Ooni pẹlu igbagbọ wi pe Kabiesi ti n ba iṣẹ lọ lori ọrọ ti wọn jọ sọ.

Ooni ṣe oriṣiriṣi ayederu iwe dukia to fi mọ risiiti lati le maa ri owo gba lọwọ obinrin yii.

Obinrin yii ko tii yọju si Naijiria pẹlu bi o ṣe n fi owo ranṣẹ si kabiesi to" ẹni to loju opo 99% OPPRESSED lo ṣalaye bẹẹ lori itakun ayelujara X.

Iwe kan ti wọn ni Fagbule sọ pe Ooni kọ lati ṣeleri fun un pe oun ṣetan lati fẹ ẹ gẹgẹ bi iyawo naa wa lori ayelujara.

Koda, lẹta ọhun ni ibuwọlu eyi ti orukọ Ooni wa nibẹ ninu.