Iré dé n'Ile Ife, Ọọ̀ni pàṣẹ iye táwọn ọlọ́jà gbọ́dọ̀ ta ata, fagilé ẹgbẹ́ ọlọ́jà

Oríṣun àwòrán, other/screenshot
Ọọni ilu Ile-Ifẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọba Ẹnitan Adeyeye Ogunwusi, ti paṣẹ pe ko si ohun to n jẹ ẹgbẹ ọlọja mọ niluu Ile-Ifẹ, bẹẹ ni ata ile kan ko gbọdọ kọja ọgọrun-un kan si igba naira (100/200 Naira).
Ninu fidio kan to jade sori ayelujara lọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu keje ọdun 2024 yii ni awọn oloye lati aafin Ọọni Ogunwusi ti jẹ iṣẹ naa laarin ọja niluu Ile-Ifẹ.
Bakan naa ni BBC Yoruba fidi iroyin mulẹ lati ẹnu ọkan lara awọn oṣiṣẹ Ọọni l’aafin.
Agbẹnusọ lorukọ Kabiyesi naa sọ pe, lẹyin ti ata ti wọn kọja to si ti walẹ pada, ko si idi kan fun ẹnikẹni lati maa le ata ni ẹẹdẹgbẹta naira (500) mọ.
Bakan naa lo sọ pe Kabiyesi ti fagile ohunkohun to ba jẹ mọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ laarin ọja Ifẹ.
‘’Ni orukọ Kabiyesi Ọọni Enitan Adeyeye Ogunwusi ati gbogbo awọn ijoye mẹrindinlogun to n ba Olufẹẹ gbimọran, wọn ni ki awọn Babalọja ati Iyalọja lọ jẹ iṣẹ yii fun gbogbo olutaja ni Ile-Ifẹ ati ibi ti Ifẹ de duro, pe lati oni lọ, awọn o fẹ ọrọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ kan, boya ẹgbẹ oniraisi, alata, elepo titi debi to le kere mọ, pe awọn fagile e lati oni lọ’’
O fi kun un pe bi ẹnikẹni ba fẹẹ ta ọja rẹ ni iye to wu u, ti olori ọja kan waa fẹẹ dunkokoko mọ ọn, gbogbo ohun ti oju olori ọja naa ba ri, ko fara mọ ọn.
‘’ Bi ara ita ba fẹẹ waa ba wa naja n’Ile-Ifẹ, bi ẹnikẹni ba fẹẹ di i lọwọ, ti wọn ba fi le fi ẹjọ iru ẹni bẹẹ sun, ẹni naa yoo fi Ile-Ifẹ silẹ ni.’’

Oríṣun àwòrán, screenshot
‘Àwọn tí kobíowú wọn ń jẹ́ méje náà ti wọ gàù’
Nibi ti ajẹpa ere ti wọ awọn mi-in lẹwu de nipinlẹ Ọṣun, kongo ti wọn n pe ni kobiowu ti wọn fi n ṣe odiwọn nnkan wíwọ̀n ko pe mọ.
Gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe wi, agolo mẹwaa lo yẹ ko wa ninu kongo kan ẹwa, irẹsi abi ohun yoowu ko jẹ.
Ṣugbọn awọn ọlọja kan ti dọgbọn si i to bẹẹ ti tiwọn ki i ju meje lọ.
Fun awọn wọnyi, Ọọni Ogunwusi ti paṣẹ pe ẹni tọwọ ba tẹ nidii iwa ibajẹ naa yoo kuro ni Ile-Ifẹ patapata ni.
Ọba paṣẹ pe wọn yoo le ẹni bẹẹ jade kuro n’Ifẹ ni.
Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu karun-un ọdun 2024 yii ni Ọwa Obokun Ilẹ Ijẹsa, Ọba Ọmọwe
Gabriel Aromolaran, naa gbe igbesẹ yii nipa fifi ofin de ẹgbẹ ọlọja ati tawọn ọlọkọ ero n’Ileṣa.
Eyi waye pẹlu bi Kabiyesi ṣe ṣo pe awọn olori wọnyi lo wa nidii bi nnkan ṣe wọn, ti ara si n ni araalu.
Ọpọ eeyan ni igbesẹ awọn ọba meji yii dun mọ ninu, wọn ni bi nnkan tiẹ le ni Naijiria, ti ipinlẹ Ọṣun kọja sisọ.
O si yẹ ki wọn kapa awọn to n fi ọja ni ilu lara naa.














