Kókó mẹ́fà tí o ní láti mọ̀ nípa owó orí oúnjẹ tí ìjọba Tinubu yọ kúrò

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook

Lẹyin ti ijọba Naijiria kede yiyọ owo ori to wa lori awọn eroja ounjẹ ti wọn n ko wọ orileede yii, o ti wa di ohun amuṣe bayii fun gbogbo awọn ti ọrọ kan lati bẹrẹ sii mulo.

Minisita fọrọ eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin, Abubakar Kyari lo kede eyi ninu atẹjade to fi sita loju opo ayelujara rẹ l’Ọjọru, ọsẹ ti a wa yii, nibi to ti sọ pe gbogbo awọn iwe aṣẹ ẹṣọ aṣọbode ati awọn owo ori miran lori ounjẹ ni awọn ti mu kuro.

Ijọba sọ pe igbesẹ akikanju yii lohun gbe lati bori gbogbo wahala ati iṣoro lori bi ọwọngogo ṣe ba gbogbo ounjẹ ati eroja ounjẹ patapata lorileede Naijiria.

Lọjọ Aje, ọsẹ yii, oluranranwọ Aarẹ Tinubu lori eto iroyin, Bayọ Ọnanuga fi ikede naa soju opo ayelujara rẹ, ṣugbọn to tun pada yọ ọ kuro lẹyin wakati meloo kan.

Igba wo ni awọn anfaani eto yii yoo bẹrẹ?

Atẹjade ti minisita ọhun fi sita ko ṣalaye ọjọ naa pato ti eto naa yoo bẹrẹ sii fẹsẹ mulẹ, ṣugbọn o sọ igba ti wọn yoo bẹrẹ sii ṣe e.

Abubakar ninu ọrọ rẹ sọ pe “Laarin ọjọ mẹrinla si asiko yii, a maa pade lati jẹ ki ifẹsẹmulẹ naa ya kiakia, nipa ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ pẹlu igbimọ aarẹ lori ọrọ ounjẹ, igbimọ aarẹ lori eto ọrọ aje ati awọn ileeṣẹ miran ti ọrọ kan.”

Igbesẹ naa ati awọn miran yoo di mimu lo laarin ọgọsan ọjọ lapapọ, gẹgẹ bi ijọba ṣe sọ.

Ṣe wọn yoo sọ iye ti owo ounjẹ yoo jẹ?

Ni afikun, ijọba sọ pe ohun naa mọ nipa aniyan lori bi awọn ounjẹ ti wọn fẹẹ ko wọle lati ilẹ okeere yoo ṣe jẹ ojulowo to.

Ju gbogbo rẹ lo, wọn yoo sọ iye ti awọn ẹka ounjẹ kan yoo jẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ: “Gbogbo awọn ohun ti wọn yoo ko wọle ni wọn yoo fi sinu ilana sisọ iye ti wọn yoo ta ọkọọkan, eto ti wọn pe ni Recommended Retail Price (RRP).

“Awa naa ti mọ nipa awọn aniyan ti awọn eeyan n ṣe lori awọn ohun ti wọn yoo ko wọle, paapaa julọ lori ọna ti wọn gba lati ṣe wọn. Ijọba ti ṣetan lati rii pe gbogbo ilana to yẹ ni wọn tẹle lati mọ nipa imọtoto ati ilera to wa lori ounjẹ ti wọn n ko bọ.”

Awọn owo ori wo ni wọn dunbu?

Ninu ọrọ Minisita Abba Kyari, ijọba gba gbogbo ohun ti awọn onifayawọ n sa fun bii iwe aṣẹ, owo ori ati awọn owo to wa lori nnkan miran.

Iwe aṣẹ ni owo ori ti wọn gba nigba ti eeyan ba ko awọn ẹru kan wọle lati orileede miran.

Owo ori ni eyikeyi owo ori ti ijọba n gba leyikeyi ẹka yala ni ijọba apapọ, ipinlẹ ati ijọba ibilẹ.

Owo sisan (Tariff) ni owo ori ti wọn n gba lọwọ eeyan lori okoowo to n ṣe lori awọn ọja kan.

“A maa ko ọpọ agbado ati ‘wiiti’ wọlẹ'

Ni itẹsiwaju ninu atẹjade lori igbesẹ ti ijọba ti gbe lati mu irọrun ba owo ounjẹ rira, ijọba apapọ yoo ko ẹgbẹrun lọna aadọta-le-nigba agbado ati ẹgbẹrun lọna aadọta-le-nigba wiiti wọle si Naijiria.

“Eyi ni awọn eroja ti wọn ti ṣeto rẹ, leyi ti wọn yoo pin si awọn ileeṣẹ to n ṣe wọn lati pari iṣẹ lori rẹ kaakiri orileede yii,” minisita lo sọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe “Ijọba yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn alẹnulọrọ mu idagbasoke ba eto ṣiṣẹ awọn nnkan jade (Good Manufacturing Practices), ati lati ra ọpọ ounjẹ pamọ gbọngan ti ijọba apapọ nko ounjẹ pamọ si.

Kyari fi kun ọrọ rẹ pe wọn yoo tubọ maa ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe awọn ileeṣẹ miran bii ologun naa yoo wa lori iṣẹ lati rii pe wọn n ṣamulo ilẹ ti wọn ni lati fi da oko.

“A maa jẹ ki iṣẹ ti a n ṣe pẹlu ileeṣẹ ologun Naijiria nipa di da oko labẹ eto ti a pe ni Defense Farms Scheme ya kankan, ka si ṣe koriya fun awọn ileeṣẹ miran lati ṣamulo anfaani yii nipa dida oko.”

Ipalara wo ni ipinnu yii yoo ko fun awọn agbẹ ni Naijiria?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn agbẹ ibilẹ gba pe igbesẹ yii ṣe ipalara fun iṣẹ wọn, iye owo nnkan ti wọn n ṣe, koda ire oko wọn lọdun to n bọ.

Muhammad Magaji, to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ awọn agbẹ ti wọn pe ni All Farmers Association of Nigeria (AFAN), sọ fun BBC pe awọn ọna miran wa to yẹ ki ijọba gba.

“Ni bayii, awọn ti ṣe idako asiko ọgbẹ ilẹ ni owo to gara, idi niyẹn ti owo ọunjẹ fi lọ soke.

“Ati pe ni bayii, asiko ojo la wa, ti eto dida oko yoo si gbe owo lori, gbogbo ohun ti wọn yoo da ni oko yoo gbe owo lori gidi. Ni bayii ti wọn ti wa sọ pe anfaani ti wa lati ko ounjẹ wọle lati ilẹ okeere.

“Fun idi eyi, bi owo ounjẹ ti wọn ba fẹẹ ko wọle ba ja wa silẹ ju iye owo ti awọn agbẹ, o maa ṣe ipalara fun ẹka eto iṣẹ agbẹ.”

Ju gbogbo rẹ lọ, o sọ pe bi ijọba ba le ni suuru, gbogbo ohun ti awọn agbẹ ti ṣe lasiko ọgbẹ ilẹ yoo to o jade, ati pe wọn yoo bẹrẹ sii ko ire oko naa.

“Idi ni pe wọn ko da oko ọgbẹ ilẹ bi wọn ṣe maa n da a tẹlẹ lo fa bi owo nkan ṣe lọ soke, awọn ti wọn si n ṣe e ni wọn n fi owo nla ṣe e. Ni bayii ti owo nnkan ti n lọ silẹ nitori pe awọn ire oko ti wọn n gbe jade ti n lọ saarin ọja.”