Ọba Olakuleyin gbọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Olubadan Kẹtàlélógójì

Nibi akanṣe eto ifinijoye to waye ni gbagede Mapo niluu Ibadan l'ọjọ Ẹti ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti gbe ọpa aṣẹ fun Olubadan tuntun.
Ninu ọrọ ti Makinde sọ nibi ipejọpọ naa, o ṣe alaye wi pe igbesẹ ti oun gbe lati fun Olubadan tuntun ni ọpa aṣẹ ati iwe ẹri iyanisipo wa ni ibamu pẹlu agbara ti a fun un gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ.
Lẹyin ti Olubadan tuntun Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, Ige Ọlakulẹhin 1 gba ọpa aṣẹ ni Kabiyesi naa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to wa si ibi ajọyọ naa, gẹgẹ bi o ṣe n gbadura pe ilu Ibadan yoo maa gun oke agba sii.
Awọn ladelade-loyeloye, aṣoju ijọba, awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu, awọn aṣiwaju ẹsin ati ọkanojọkan ẹgbẹ awujọ ko gbẹyin nibi akanṣẹ eto naa.


Lara wọn ni Minista fun akoso ina ọba, Adebayo Adelabu ti o ṣoju aarẹ orilẹede yii, Bọla Ahmed Tinubu, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde, Igbakeji rẹ, Adebayo Lawal, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Olaide Adelami, igbakeji Gomina Ọṣun, Kola Adewusi, Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adewusi Enitan Ogunwusi, Sultan Sokoto, Sa'ad Abubakar, Ewi Ado, Oba Rufus Adeyemo Adejugbe, Olugbon Orile Igbon, Oba Francis Olusola Alao Asẹyin ilu Isẹyin, Sefiu Oyebola Adeyeri III, Ajirotutu I, Olu Igboọra, Oba Jimoh Olajide Titiloye, Oloye Rashidi Ladọja ati awọn Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Aarẹ Musulumi ilẹ Yoruba, Edo ati Delta, Alhaji Dauda Akinola, Kọmisana Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ayọdele Ṣonubi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gbajugbaja olorin, Taye Currency lo kan ilu si awọn eeyan n'ibadi nibi ipejọpọ naa.
Olubadan ti dé sí Mapo láti gba ọ̀pá àṣẹ rẹ̀

Kabiyesi olubadan tuntun, Ọba Akinloye Ọlakulẹhin ti gunlẹ si gbagede Mapo fun ayẹyẹ igbọpa aṣẹ rẹ.
Lara awọn eekan to ti wa nikalẹ ni Gomina Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun minisita fun ohun amuṣagbara, Adebayọ Adelabu, gomina ipinlẹ Ọyọ nigbakanri, Oloye Rashidi Ladọja atawọn eekan oloṣelu pẹlu.
Lara awọn lọbalọba to ti wa nikalẹ naa ni Ọọni ti ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Sultan Sa’ad Abubakar III atawọn ọbalaye miran.


Oríṣun àwòrán, Others
Atẹgun tuntun yoo fẹ niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo nigba ti wọn gbe Ade Oba ati ọpa aṣẹ fun Olubadan tuntun ni gbọngan Mapo lonii.
Ọjọ kẹdogun oṣu kẹta ọdun 2024 ni Olubadan ana, Oba Olalekan Balogun waje lẹyin ọdun meji to bọ sori alefa.
Sugbọn, Ọba Owolabi Olakulehin, ẹni ti ipo ọba naa kan gẹgẹ bii ilana ọba jijẹ se gbe kalẹ nilẹ Ibadan yoo gba ade lonii.
Ọpọ awọn eekan ilu lorilẹede Naijiria ati nipinlẹ Oyo lapapọ ni yoo peju si gbọngan Mapo nigba ti Oba Owolabi ba b gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bii Olubadan.
Lati le jẹ ki awọn araalu peju si ayẹyẹ ifiọbajẹ naa, Babalọja ti ilu Ibadan, Alhaji Yekeen Abass ti palaṣẹ fun gbogbo ọja lati wa ni titi pa, bẹrẹ lati ago meje aarọ wọ ago meji ọsan.
Ọba Owolabi ni yoo jẹ Ọba keji niluu ti yoo ma paṣẹ lati ninu aafin tuntun ti ilu sẹsẹ kọ lẹyin Ọba Yesufu Oloyede Asanike, to jẹ Ọba akọkọ ti yoo gbe ni aafin to wa ni Ọja Ọba.
Lonii. Ọba Owolabi yoo se bi awọn aṣaju rẹ se se nigba to ba lọ si agboole Oluwo Labosinde ni Ọja’ba niluu Ibadan, ni bi ti yoo ti se gbogbo etutu to yẹ ati lilọ si di Oosa Ọsẹ meji nibi ti wọn yoo ti gbe ade fun gẹgẹ bii Olubadan tuntun ko to di pe o gba ọpa aṣẹ lọwọ Gomina Seyi Makinde ni gbọngan Mapo.
Ohun to yẹ ko mọ nipa Ọba Owolabi Olakulehin

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ karun un, oṣu keje, ọdun 1935 ni wọn bi Ọba Owolabi Ọlakulehin ni agbegbe Okugbaja ni ọna Akanran ni ijọba ibilẹ Ọna Ara.
Wọn bi si idile Pa Ishola- Okin Owolabi ati Iyaafin Adunola Aweni Ope Ajilaran Omoyoade Owolabi.
Ifinijẹoye Oba Owolabi jẹ ore nla fun agboole Ita=Baale Olugbode, nitori Oba Owolabi ni ẹni akọkọ ti yoo jẹ Olubadan lati gba ti Baale Ajayi Oyesile Olugbode ti waja.
Lasiko Baale Ajayi Oyesile Olugbode, Ibadan o ti ma jẹ Olubadan, Baalẹ ni wọn jẹ lasiko naa.
Fun Ọba Owolabi, irinajo Olubadan bẹrẹ ni ọdun mejidinlogoji sẹyin, bẹrẹ lati
Ọdun 1983 ti Oba Owolabi di Mogaji agboole Ige Olakulehin ni Ita Baale Olugbode niluu Ibadan, Jagun Balogun – Ajia – Bada – Aare Onibon – Gbonnka – Aare Egbe Omo-Oota – Lagunna – Aare Ago – Ayingun – Asaju – Ikolaba – Aare Alasa – Agba Akin – Ekefa – Maye – Abese – Ekaarun Balogun – Ekeerin Balogun – Ashipa Balogun – Osi Balogun – Otun Balogun, Balogun, ko to wa di Olubadan ti ilẹ Ibadan
Ọdun 1986 ni o di Jagun Balogun ilẹ Ibadan lasiko Ọba Asanike.
Ni ọdun 2016, Oba Owolabi di Balogun ti ilẹ Ibadan, to si wa nipo naa fun ọdun mẹjọ.















