Gbajúgbajà orí ayélujára Tiktok dèrò ẹ̀wọ̀n lóri pé ó sọ̀rọ̀ àbùkù sí ààrẹ

Aarẹ Uganda

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile-ẹjọ orileede Uganda ti ju ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan sẹwọn ọdun mẹfa gbako lori ẹsun wi pe o sọrọ abuku si aarẹ wọn.

Yatọ si aarẹ ti ọmọkunrin ọhun sọrọ abuku si, o tun sọrọ abuku si awọn mọlẹbi rẹ ninu fọnran kan to gbe sori ikanni Tiktok rẹ laipẹ yii.

Edward Awebwa ni orukọ ọmọkunrin ọhun ti wọn fi ẹsun kan wi pe o gbe ọrọ abuku sita nipa aarẹ, to si n ṣi awọn eeyan lọkan lati lodi si Aarẹ Yoweri Museveni, aya rẹ, Lady Janet Museveni ati ọmọ wọn ọkunrin, Muhoozi Kainerugaba, ẹni to jẹ olori awọn ologun.

Ile-ẹjọ naa tun gbọ pe Awebwa tun pin fọnran abuku si aarẹ ati mọlẹbi rẹ naa kaakiri ori ayelujara, pẹlu iroyin ẹlẹjẹ wi pe owo ori yoo tun lọ soke sii labẹ Aarẹ Museveni.

Ọmọkunrin yii wa rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ lati foju aanu wo oun, lẹyin to gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe oun ko tun jẹ ṣe iru nnkan bẹẹ mọ.

Onidajọ to gbọ ẹjọ naa, Stella Maris Amabilis sọ pe bo tilẹ jẹ pe Awebwa bẹbẹ fun oju aanu, sibẹ ko ṣebi ẹni ti ọrọ oun ka lara rara, ati pe awọn ọrọ to lo ninu fọnran ọhun lagbara gidi, o si tabuku gidi.

Onidajọ Amabilis ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe “Ẹni ti wọn fi ẹsun kan yii yẹ lati jiya ẹṣẹ rẹ, eyi ti yoo jẹ ko le kẹkọọ lori iwa to ti hu ṣẹyin, ati pe lọjọ iwaju, yoo maa bọwọ fun iru ẹni ti aarẹ jẹ, aya rẹ ati akọbi ọmọ rẹ lọkunrin.”

Ẹwọn ọdun mẹfa-mẹfa ni ile-ẹjọ ju si lori ẹsun mẹrẹẹrin kọọkan ti wọn fi kan an, ti yoo si ṣe gbogbo rẹ papọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ti bu ẹnu atẹ lu iṣakoso ilẹ Uganda lori titapa si ẹtọ ọmọniyan ati aifi aaye gba awọn eeyan lati sọ ẹdun ọkan wọn.

Lọdun 2022, gbajugbaja onkọwe ilẹ Uganda to ti gba aami ẹyẹ nni, Kakwenza Rukirabashaija ni wọn fi ẹsun meji ọtọọtọ kan pe oun naa sọrọ abuku, lẹyin to sọ awọn ọrọ kan nipa aarẹ ati ọmọ rẹ lori ikanni ayelujara Twitter.

O sa kuro lorileede naa lọ si Germany lẹyin to lo oṣu kan gbako lẹwọn, nibi to ti fẹsun kan wi pe wọn fiya buruku jẹ oun.

Gbajugbaja onsọrọ ati onkọwe nni, Stella Nyanzi, toun naa ti na papa bora,. Ni wọn ti kọkọ ju sẹwọn lori wi pe o gbe apilẹkọ kan jade nipa Museveni, eyi ti wọn lo lagbara gidi.

Lati ọdun 1986 ni Aarẹ Museveni ti wa ni ijọba - ọdun mẹrinla ko to di pe o bi Awebwa.

Lọdun 2022, Museveni buwọ lu iwe abadofin kan to tako sisọrọ pataki to nii ṣe pẹlu ijọba, eyi ti awọn ajafẹtọ bu ẹnu atẹ lu, ti wọn si ni ofin naa wa lati tako sisọ ẹdun ọkan ẹni lori ayelujara.

Bẹẹ lọdun to kọja, ile-ẹjọ kan paṣẹ pe apa kan ninu iwe ofin wọn nipa ọrọ abuku ko ba iwe ofin mu.

Agbẹjọro ajafẹtọ-ọmọniyan ilẹ Uganda nni, Michael Aboneka sọ pe abala iwe ofin yii ni wọn lo lati fẹsun kan Awebwa, eyi to lawọn ṣi tun n gbe lọ sile-ẹjọ.

O sọ fun BBC pe ki aarẹ ati mọlẹbi rẹ ṣi tubọ maa gbaradi lati gbọ awọn ọrọ bibu ẹnu atẹ lu ijọba rẹ leyikeyi ẹka

“Ayafi to ba jẹ ohun ti wọn n sọ ni pe gbogbo ọmọ Uganda to ba n bu ẹnu atẹ lu ijọba wọn lawọn yoo fi kele ofin gbe,” o sọ eyi di mimọ.