Lórí ìwọ́de Endsars, Ilé ẹjọ́ ECOWAS pàṣẹ fún ìjọba Naijiria láti san owó ìtanràn fún DJ Switch àtàwọn olùwọ́de méjì míràn

Ileẹjọ ajọ awọn orilẹede to wa lẹkun iwọ oorun Afrika, Ecowas ti paṣẹ fun ijọba orilẹede NAijiria pe ko san owo gba maabinu fun Obiannju Udeh ti ọpọ mọ si DJ Switch ati awọn meji miran fun titẹ ẹtọ wọn mọlẹ.
Ile ẹjọ ajọ Ecowas gbọ ẹjọ ẹsun titẹ ẹtọ ẹni loju mọlẹ ti DJ Switch ati awọn meji pe tako ijọba Naijiria fun titẹ ẹtọ wọn mọlẹ lasiko iwọde EndSARS to waye loṣu kẹwaa ọdun 2020.
Ileẹjọ naa ni ihuwasi ijọba orilẹede Naijiria lasiko iwọde EndSars naa tako ofin ajọ ECOWAS pẹlu awọn iwa bii idunkoko mọni, ifiyajẹni, aipese aabo to peye ati awọn ẹsun miran.
Awọn olupẹjọ naa - Obianuju Udeh, Perpetual Kamsi ati Dabiraoluwa Adeyinka gbe ẹjọ naa tọ ile ẹjọ lọ pẹlu ifisun pe ijọba kọlu awọn eeyan kan lasiko iwọde alaafia EndSARS to waye ni Lekki nipinlẹ Eko ni Ogunjọ ati ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Adajọ to gbe idajọ naa kalẹ, Koroma Sengu paa lasẹ fun ijọba orilẹede Naijria pe ki wọn san owo itanran ti apapọ rẹ jẹ milọnu mẹwaa naira fun gbogbo awọn to farakasa isẹlẹ naa ti wọn darukọ ninu iwe ẹjọ.
Bakan ni ile ẹjọ tun pasẹ fun ijọba orilẹede Naijria pe, yatọ si pe wọn gbọdọ tẹle aṣẹ ileẹjọ, ki wọn se iwadii awọn oṣiṣẹ agbofinro to lọwọ ninu ikọlu naa, ki wọn si fa wọn le ileẹjọ lọwọ laarin oṣu mẹfa si asiko yii.
Ki lawọn olujẹjọ ati olupẹjọ sọ fun ileẹjọ ECOWAS?
Awọn olupẹjọ sọ fun ile ẹjọ pe lasiko iwọde alaafia naa lati tako idunkoko SARSm ẹka ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni Lekki Toll Gate niluu Eko ni Ogunjọ ati ọjọ kọkanlelogun ọdun 2020 ti olujẹjọ si tẹ ẹtọ ọmọ niyan pupọ mọlẹ.
Iwọde naa lo waye lati tako idunkoko ati ifiyajẹni ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria.
Olupẹjọ alakọkọ sọ fun ileẹjọ pe awọn soja yin ibọn fun awọn eeyan to fẹhonuhan, eyi to jasi iku fun ọpọlọpọ, ti awọn mii si farapa, eyi to gbe sori ayelujara, to si n gba ipe, eyi to mu sa asala fun ẹmi ara rẹ, ko di pe o saa kuro ni orilẹede Naijiria.
Olupẹjọ keji, to si igbayegbadun awọn olufẹhonuhan naa tẹnu bọ ọrọ, to si sọ fun ileẹjọ bi awọn ọmọ ologun se sina bolẹ lẹyin ti wọn pa ina, ti oun naa si dero ile iwosan.
Olupẹjọ kẹta sọ fun ileẹjọ bi o se rapala kuro nibi iṣẹlẹ nigba ti awọn ọmọ ologun sina bolẹ, to si ri bi awọn ile iwosan kan se kọjalẹ lati se itọju awọn to farapa ni ilana to tọ.
O fikun pe oun ati awọn akẹgbẹ rẹ ni wọn bẹrẹ si ni ma se itọju awọn eeyan to farapa naa.
Awọn olupẹjọ wa sọ ileẹjọ pe awọn gba owo itanran fun eeyan to lugbadi isẹlẹ buruku lasiko iwọde naa.
Olujẹjọ ni irọ gbogbo ẹsun ti wọn ka silẹ, to si tẹnumọ pe awọn olufẹhonuhan korawọnjọ ni ilana ti ko ba ofin mu lati dibọ pe wọn se iwọde lati tako idunkoko SARS ni Lekki Toll Gate niluu Eko.
Bakan naa ni olujẹjọ fikun pe aṣẹ ni awọn agbofinro to wa ni bi iṣẹlẹ n tẹle, ti wọn ko si yinbọn fun ẹnikẹni lasiko iwọde.
Olujẹjọ ṣalaye pe olupẹjọ akọkọ n lo orin kikọ ati opo ayelujara rẹ lati mu inu bi awọn oṣiṣẹ agbofinro to n wa awọn ọmọ ogun to salọ.
Olujẹjọ tun wọgile ipe olupẹjọ keji, to si ni o lọwọ ninu pipese ohun iranwọ fun iwọde ti ko ba ofin mu.
O fikun pe awọn ọmọ ogun to wa ni bi ti iṣẹlẹ naa ti waye lo wa ni bẹ lati ri daju pe alaafia jọba.
Ki lo sẹlẹ ni Ogunjọ Oṣu kẹwaa ọdun 2020?
Iwọde Endsars lo bẹrẹ sinu oṣu kẹwaa ọdun 2020 sugbọn ti eyi to fa rogbodiyan waye ni Ogunjọ oṣu kẹwaa.
Ọpọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ni iwọde ti waye, ti awọn ọdọ si korawọnjọ lati fẹhonuhan lori bi Ileeṣẹ ọlọpaa se n dunkoko mọ wọn.
Ohun ti awọn ọdọ naa n pariwo soke lasiko naa ni pe awọn ọlọpaa n lo ọna ẹburu lati ko awọn ọdọ ni ilana ti ko ba ofin, ti ọpọ ọdọ si ti padanu ẹmi nitori iwa yii.
Igbesẹ yii lo jẹ ki Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijria wọgile ohun to n jẹ SARS lorilẹede Naijiria lati le pẹtu si awọn ọdọ lọkan.















