Kí ló fàá tí Toyin Abraham fi pariwo síta pé òun ṣe tán láti kú?

Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham ti pariwo sita pe oun setan lati ku nitori oun ko se ohunkohun lati ta abuku ofin lẹyin ti eeyan lati ori ayelujara fẹsun kan pe o fi ọlọpaa mu iya rẹ.
Abraham nigba to n sọrọ lori itakun ayelujara rẹ ṣalaye oun ko tẹ oju ẹnikẹni mọlẹ ati pe oun ko fi ọlọpaa mu iya ẹnikẹni gẹgẹ bii o ṣe n tan kaakiri ori ayelujara.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe, eeyan kan lati ori ayelujara sọ pe Toyin Abraham fi ọlọpaa mu iya oun ni sọọbu iya naa to wa ni Panti niluu Eko.
Nigba to n fesi si ọrọ naa, Toyin Abraham ni irọ to jina sotọ ni ọrọ naa ati pe oun ko fi ọlọpaa mu iya kankan.
“Mo sọ pe n ko ni sọ ohunkohun mọ sugbọn o ni awọn nnkan ti o kan le fi parọ mọ mi, ti wa si reti pe ki ma sọrọ.
“Mi o le fi ọlọpaa mu iya ẹnikẹni nitori iya ni emi naa. N ko di da ẹsẹ kankan, ohun ti mo se ni ohun to jẹ ẹtọ mi, wọn dẹ n dunkoko mọ mi.
“ Mo wa sori ayelujara lati wa bẹ gbogbo eeyan pe ki wọn fi silẹ.
“Bi o se wa , mo fẹ ku. Mo setan lati ku sugbọn ki n to ku, gbogbo awọn to n dunkoko mọ mi yoo ku pẹlu mi.
“Awọn eeyin yii ti ti mi kan ogiri, ti wọn si fẹ yami ni were. Ni bayii mo fẹ ku; O wu mi lati ku; N ko da ẹsẹ kankan; Mo wa lati wa bẹ iyin ati lati sọ fun iyin pe n ko gba owo lọwọ ẹnikẹni.
“O ti su mi de gogongo nitori ẹ se epe fun ọmọ mi, sugbọn n ko fi ọlọpaa mu ẹnikeni
“Ohun ti mo se ni mo kọ lẹta pe wọn parọ mi”
Toyin ni igbesẹ ti oun gbe ko ju pe oun gba ileeṣẹ lọ lati sọ fun wọn ẹnikan wa to parọ mọ oun lori ayelujara, to si kọ iwe si ileeṣẹ ọlọpaa.
“Mo kan kọ lẹta, wọn ni ki n lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n si iwa ọdaran ori ayelujara, ti mo si se, mo kọ iwe naa.
“Idi ti n ko fi orukọ Anthony si ni pe ko parọ mọ mi, o bu mi, emi naa bu pada. Otitọ ko ni pẹ jade sita.”
Toyin Abraham fikun pe awọn kan ti gba owo lati ba aye rẹ jẹ sugbọn ẹru ko ba nitori o gbagbọ pe o da sẹ ẹsẹ kankan.
“Wọn ti san owo fun awọn eeyan yii lati ba iṣẹ ati aye mi jẹ sugbọn n ko dẹ ẹsẹ fun idi eyi ẹru ko ba mi.
“Mo setan lati ku sugbọn ki n to ku, mo setan lati ri daju pe n ko ni mu ni suuru fun ẹnikẹni to ba dunkoko mọ mi.”















