Wo bí inú ààfin tuntun ìlú Ibadan ṣe rí àti àwọn ọ̀nà tí kíkọ́ rẹ̀ gbà wáyé

Àkọlé fídíò, Wo bí inú ààfin tuntun ìlú Ibadan ṣe rí àti àwọn ọ̀nà tí kíkọ́ rẹ̀ gbà wáyé
Wo bí inú ààfin tuntun ìlú Ibadan ṣe rí àti àwọn ọ̀nà tí kíkọ́ rẹ̀ gbà wáyé

Láti ọdún 1993, láyé Olubadan Yesufu Oloyede Asanike ni Olubadan ti rí ààfin tó jẹ́ ti ìlú lò gbẹ̀yìn.

Ìdí nìyí tí ìgbìmọ̀ àwọn ọmọ bíbí ìlú Ibadan fi dìde láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fí ṣàdá, tí wọ́n sì sáré káàkiri láti kọ́ ààfin tó jojú ní gbèsè fún oyè Olubadan.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Aarẹ agba ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Ibadan, CCII Amofin Wọle Ajewọle ṣe alaye lori ohun to pilẹ aini aafin ilẹ Ibadan lati igba ipilẹ wa, ohun to ṣokunfa kikọ aafin akọkọ ati idi ti wọn fi pa aafin akọkọ naa ti.

Bakan naa lo ṣalaye bi wọn ṣe bẹrẹ kikọ aafin tuntun yii ati awọn ipenija ti wọn koju.

Amofin Ajewọle ni aini aafin Ibadan lati iwasẹ ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe jagunjagun lo tẹ ilu Ibadan do ni. O ni ile olukaluku to jẹ Baalẹ ni wọn to lo.

O ni igba to ya ni wọn ko ara jọ pe ki wọn kọ aafin, eleyi ni wọn si kọ si agbegbe Ọjaaba nilu Ibadan nitori pe aaringbungbun ilẹ Ibadan ni wọn fẹ ko wa nigba naa. Amọṣa o ni aisi aaye pupọ nibẹ jẹ idiwọ fun Ọba Ashankẹ to jẹ nigba naa, to si ṣe okunfa bi awọn ọba to tẹle ṣe yẹra fun lilo aafin naa.