Wo àwọn ètùtù àti ètò tí yóò wáyé fún Olubadan tuntun kí ó tó tẹ́rí gba adé

Aworan Ọba Ọlakulẹyin ati aafin olubadan tuntun

Oríṣun àwòrán, others

Olubadan ikẹtalelogoji yoo jẹ lọjọ kejila oṣu yii ni gbagede Mapo nilẹ Ibadan, ṣugbọn awọn ọkanojọkan etutu ati eto gbọdọ kọkọ waye na saaju ayẹyẹ ifinijoye Olubadan tuntun.

Oluwo Afọbajẹ ilẹ Ibadan, Oloye Wahab Popoọla Mosadogun ṣe alaye pe bi gbogbo ilu kii ba ṣe etutu ki awọn ọba tuntun to jẹ, iruẹ ko gbọdọ ṣẹlẹ nilẹ Ibadan.

Lasiko to n kopa lori eto 'Agbami Oṣelu' nileeṣẹ redio Fresh Fm lọjọ Aiku, Oloye Mosadogun ṣe alaye wi pe lati ọjọ ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọnimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti kede Olubadan tuntun ni ọkanojọkan eto ati etutu ti bẹrẹ.

Ki lawọn igbesẹ ti yoo waye?

Aafin tuntun fun Olubadan

Oríṣun àwòrán, others

Ohun akọkọ ti wọn ṣe ni lati lọ gbe ọpa iṣẹgun ti o wa ni akata Ọba Ọlakulẹhin lasiko ti o jẹ Balogun. Ọdọ ẹni ti oye Balogun ba kan ni wọn o tun gbe ọpa naa lọ lẹyin ti etutu ba pari ni iledi.

Ọpa iṣẹgun yii ni wọn fi n ṣe ami oye ti Balogun n jẹ nilẹ Ibadan.

Bakan naa ni Olubadan tuntun ti lọ bọ ọpa nile awọn afọbajẹ, saaju ọjọ ti yoo lọ fun iṣile lati wọ ipẹbi. Ipẹbi yii ni Ọba tuntun yoo waye fun ọjọ meloo kan ki asiko ifinijoye to de.

Ọba Ọlakulẹhin

Oríṣun àwòrán, others

Awọn etutu mii yoo tun waye ni ikọkọ ki Ọlubadan tuntun to ni anfani lati gun ori aleefa.

Lara awọn eto mii ti wọn ti piyamọ silẹ ni bi Gomina ipinlẹ Ọyọ yoo ṣe ṣi aafin Olubadan tuntun to n bẹ ni Oke Aremọ l'Ọjọru ọjọ kẹwaa oṣu keje ọdun yii, saaju eto ifinijoye ti yoo waye ni gbagede Mapo lọjọ Ẹti.

Ayẹyẹ ọdun aṣa ilẹ Ibadan yoo waye lọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinọgbọn oṣu keje ọdun yii ni papa iṣere Liberty Stadium, bakan naa sini ajọyọ ọdun Amala yoo waye laarin ọjọ Aje ọjọ kejilelogun si ọjọ Aiku ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keje ọdun yii labẹ agbekalẹ agbarijọpọ gbogbo ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Ibadan, CCII.

Ọjọ mọkanlelogun lẹyin ipapoda Olubadan ana lo ti yẹ ki omii ti gun ori aleefa, ṣugbọn awọn awuyewuye to rọ mọ iyansipo Olubadan tuntun lo mu ifasẹyin ba eto naa. Oluwo Afọbajẹ ṣe alaye siwaju sii pe Ọba tuntun ko ni pẹ ni ipẹbi bi awọn ọba isaaju nitori asiko ti lọ ki ọrọ iyansipo rẹ to ni iyanju.