Ebi ń pawá, ẹ san owó oṣù tí ẹ jẹ wá - SSANU, NASU rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síjọba àpapọ̀

Àwọn olùfẹhonuhan

Ẹgbẹ́ àwọn àgbà òṣìṣẹ́ tí kìí ṣe olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, SSANU àti NASU ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì imọ ọgbin Abẹ́òkúta, FUNAB, lonii darapọ mọ àwọn akẹgbẹ́ wọn kaakiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ṣe ifẹhonuhan ọlọjọ kan lórí àìsan owó oṣù mẹrin tí ìjọba apapọ jẹ wọn.

Gẹ́gẹ́ bí alaga ẹgbẹ́ SSANU ti ilẹ́ ẹ̀kọ́ FUNAB, Olurotimi Asunwon àti Edife Samson Idowu to jẹ alaga NASU ṣe sọ, iwode ifehonuhan alágbára miiran yoo gbinaya ni Abuja lọ́jọ́ kejidinlogun, oṣù Keje tí ìjọba ko ba tete wa iyanju si owo naa.

Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà n fẹsun kan ìjọba apapọ pe ijọba n fari apa kan dapa kan sì bí wọ́n ṣe san owó oṣù náà fún àwọn ẹgbẹ ASUU tí àwọn jijọ gunle iyanṣẹlodi náà ni ọdun 2022 ṣùgbọ́n tí wọ́n ko san tí èyíkéyìí nínú ọmọ ẹgbẹ́ SSANU àti NASU.

Ọdún 2022 ni ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ SSANU, NASU àti ASUU gùnlé iyanṣẹlodi lórí aigbọra ẹni ye lórí àdéhùn ọdún 2009 tí ijoba apapọ ṣe fún wọn.

Eto iwọde ifẹhonuhàn ọlọjọ kan ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ SSANU àti NASU ṣe idiwọ fún eto iforukọsilẹ àti àwọn ètò ikẹkọọ mìíràn ni ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásiti FUNAB.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fẹ́ lo yara ikowepamọsi àti àwọn tí wọ́n fẹ́ lo àwọn ibiṣẹ àkànṣe ikẹkọọ àti iforukọsilẹ fún eto ẹ̀kọ́ mìíràn ni ìrètí wọn ja si pàbó bí àwọn òṣìṣẹ́ SSANU àti NASU ṣe faake kọri lai ṣe iṣẹ wọn.

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU nibi iwọde wọn

Ọpọ wọn lo lọ darapo pẹlu awọn akẹgbẹ wọn to n ṣe ifẹhonuhan nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì náà tí ó wà ní Alabata, Abeokuta, ipinlẹ Ogun.

Akọroyin BBC News Yoruba ti o wa nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì náà jabọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eto iwọde ifẹhonuhan náà kò di eto ikẹkọọ lọwọ pẹ̀lú bí àwọn olùkọ́ fasiti ASUU ṣe ń bá iṣẹ wọn lọ nípa kíkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ síbẹ̀ àwọn ètò ẹ̀ka ikẹkọọ kan polukurumusu bíi yàrá ikowepamosika (Library), yàrá ayẹwo àwọn aláìsàn àti ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ń gba oko “farm allocation center” bí kò ṣe sí òṣìṣẹ́ tí yóò dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lohun.

Ọkan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá Akoroyin BBC News Yoruba ti ko fe dárúkọ rẹ fi aidunu rẹ hàn lórí iwọde ẹgbẹ́ SSANU àti NASU náà.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ SSANU àti NASU ní fásitì ìmọ̀ ẹ̀rọ FUTA nílù’Àkúrẹ́ darapọ́ àwọn ojugba wọn láti ṣe Ifehonuhan lórí àwọn ẹ̀tọ́ tí wọn bèrè lọ́wọ́ ìjọba Àpapọ̀.

Àwọn òṣìṣẹ́ NASU ní ìpínlẹ̀ Ondo náà darapọ̀ mọ́ ìfẹ̀hònúhàn

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU nibi iwọde wọn ni fasiti Ibadan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa ni ọmọ ṣori pẹlu bi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ SSANU ati NASU tẹka ile ẹkọ gíga fásiti, Federal University Of Technology Akure, (FUTA) ti darapọ mọ awọn ojugba wọn jakejado orilẹ ede yii lati ṣe ifehonuhan lórí owo oṣu mẹrin ti ijọba àpapọ̀ jẹ awọn oṣiṣẹ naa.

Awọn oṣiṣẹ ọhun pejọ pọ si ẹnu ọna abawọle North Gate fasiti naa ni opopona Marosẹ Akure si Ilesa lati owurọ titi di ọsan bi wọn ṣe n ke si ijọba apapọ pe awọn ko ni sinmi titi ti ijọba yoo fi ṣe amuṣẹ awọn ileri ti wọn ṣe fun awọn ẹgbẹ naa.

Alaga ẹgbẹ SSANU ni fasiti FUTA, ọgbẹni Felix Akanbi ṣalaye pe ṣeni ijọba apapọ fari apa kan dapa kan si bi wọn ṣe san owo ti ẹgbẹ awọn ASUU ninu oṣu keji ọdun yii ti wọn si kọ jalẹ lati san owo awọn ẹgbẹ to ku titi di asiko yii.

Alaga naa rawọ-ẹbẹ si Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lati ṣe amuṣẹ afikun owo oṣu to kere julọ eyi ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ n beere fun ki inira le dopin laarin awọn oṣiṣẹ orilẹ ede yii.

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa fi aidunu wọn han lori ọwọ ti ijọba fi mu wọn ati iwa ko kan mi ti Aarẹ Tinubu kọ si awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Wọn rawọ-ẹbẹ si Aarẹ lati san owo ti wọn n beere fun ki ara le tu wọn.

Kí lọ̀bọ fi ṣorí tí ìnàkí ò ṣe, ẹ san owó táwa náà bí ẹ ṣe san ti ASUU - Ẹgbẹ́ SSANU, NASU Fásitì Ilorin

Ẹgbẹ osisẹ SSANU ati NASU ẹka ti ile-ẹkọ giga fasiti Ilorin (Unilorin), ipinlẹ Kwara ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati san owo ti o tọ si awọn gẹgẹ bi wọn ṣe san ti ẹgbẹ ASUU.

Awọn ẹgbẹ mejeeji yii sọ pe ipa ti awọn n ko ni ile-ẹkọ ṣe pataki pupọ, ko si yẹ ki ijọba ro ile apa kan da ekeji si nitori laisi awọn, eto ẹkọ ko lee gun rege ninu ọgba ile-ẹkọ.

Wọn sọ eyi di mimọ nibi ifẹhonuhan ti wọn se ni inu ọgba ile-ẹkọ naa ni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹsan-an, oṣu Keje, ọdun 2024.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ SSANU, Ọgbeni Falọwọ Olushola ni ohun ti o ṣe pataki fun ijọba ni pe ki o mu adehun ti awọn jọ tọwọ bọwe lori ṣẹ.

O ni lọdun 2009 ni ijọba ba gbogbo fasiti ṣadehun lati maa sagbeyẹwo ohun gbogbo to jẹ ẹtọ, ajẹmonu, ati awọn eto koriya, bii ṣẹmina fun awọn lọdun mẹta mẹta.

O sọ pe ijọba n gbiyanju lori tawọn ASUU lori awọn adehun yii sugbọn wọn ko ya si ẹgbẹ SSANU ati NASU rara.

O fi kun-un pe, lotitọ ni ijọba ana paṣẹ ko siṣẹ, ko sowo latari iyansẹlodi gbọọrọ ọdun 2022 ṣugbọn ijọba oni ti fagile, wọn si ti san owo oṣu mẹrin awọn ẹgbẹ olukọ, ASUU, wọn ko si san ti awọn.

O ni o jẹ ohun to kọnilominu nitori ijọba kọ lati ya si ẹgbẹ SSANU ati NASU ti wọn si n fi ẹtọ wọn dun awọn.

Ọgbẹni Falọwọ ni idi ti awọn fi n ṣe ifẹhonuhan yii ni pe awọn o ri ohun kan gbamu wi pe ijọba n gbero lati san owo yii.

O wa sọ ọ pẹlu igboya pe laisi ẹgbẹ awọn, ko si fasiti ọhun lagbaye to le ṣe aṣeyọri nitori awọn lo wa nidii ohun gbogbo to le maye rọrun fun awọn akẹkọọ ninu ọgba ile-ẹkọ.

O rọ ijọba ki wọn mu ọrọ awọn naa ni pataki gẹgẹ bi awọn ṣe jẹ pataki, wi pe laiṣe eyi awọn yoo gunle iyansẹlodi.

Eto ifẹhonuhan naa bẹrẹ lati ago mẹjọ titi di ago mọkanla owurọ ti wọn si ṣewọde kaakiri ọgba ile-ẹkọ naa.

Lẹyin iwọde yii ni alaga naa ba awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ sọrọ ninu gbọngan fasiti naa, o si rọ wọn ki wọn pada sẹnu isẹ lẹsẹkẹsẹ lati ma ba a ṣe idiwọ fun awọn akẹkọọ ti wọn n ṣe idanwo lọwọ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fásitì SSANU àti NASU bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn wọn jákèjádò Nàìjíríà

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU nibi iwọde wọn ni fasiti FUNAAB Abẹokuta

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọ, NASU, ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ agba ni awọn fasiti ijọba jakejado Naijiria, SSANU, ẹka ti fasiti ilẹ Ibadan, UI naa darapọ mọ awọn akẹgbe wọn lati fi ẹhonu han lori awọn ẹtọ ti wọn beere lọwọ ijọba apapọ.

Lọjọ Aiku ni awọn alakoso ẹgbẹ naa lati ilu Abuja kede wi pe ifẹhonuhan yoo waye ni awọn fasiti ijọba jakejado orilẹede yii l'owurọ ọjọ kẹsan an oṣu keje ọdun yii, bẹẹ sini aṣekagba ifẹhonuan naa yoo waye ni ọna ara ọtọ niluu Abuja lọjọ kejidinlogun oṣu yii.

Awọn aṣoju ẹgbẹ naa to ba akọroyin wa sọrọ ṣe alaye wi pe ọpọlọpọ adehun ti ijọba apapọ ṣe fun awọn ẹgbẹ naa ni o kuna lati mu ṣẹ. Lara wọn ni ajẹẹlẹ owo oṣu mẹrin ọtọọtọ ati awọn ẹtọ mii ti ẹgbẹ naa n beere fun.

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU nibi iwọde wọn ni fasiti Ibadan

Ọkanojọkan akọle ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa gbe lọwọ lọwurọ oni, gẹgẹ bi wọn ṣe n kọ orin ọtẹ ti wọn si di ẹnu ọna abawọle fasiti ilẹ Ibadan pa.

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU nibi iwọde wọn ni fasiti FUNAAB Abẹokuta

Ìrújú lórí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ SSANU àti NASU fẹ́ gùnlè lónìí

Aworan awon olufẹhinuhan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn olori ẹgbẹ awọn olukọ agba ni awọn ile ẹkọ giga fasiti to n bẹ loriẹede yii labẹ asia SSANU ati awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ, NASU ti gba lati fopin si ifẹhonuhan ati iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gunle.

Ikede yii waye lẹyin ti ipade kan waye laarin ẹgbẹ naa ati Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Tahir Mamman.

Ninu ọrọ ti Ọjọgbọn Mamman gbe sori ayelujara X, oni awọn olori ẹgbẹ mejeeji ti gba lati juwọlẹ ninu ero lati se ifẹhonuhan, ti wọn si n reti esi gidi lati ọwọ ijọba apapọ.

Minisita fun eto ẹkọ ni ouin ati Minisita fun eto ẹkọ ipinlẹ,Yusuf Sununu pẹlu awọn oṣiṣẹ agba ni ẹka ijọba ni awọn se ipade naa pẹlu SSANU ati NASU.

Mamman ni oun n gbinyanju lati ọna abayọ si iṣoro owo oṣu naa.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Bo ti lẹ je pe Minisita fun eto ẹkọ sọ pe awọn ẹgbẹ mejeeji ti gba lati wọgile ifẹhonuhan ati iyanṣẹlodi, Aarẹ ẹgbẹ NASU, Makolo Hassan, nigba to n ba Channels TV sọrọ, sọ pe ko si nnkan ti yoo yi wọn lọkan pada.

Lọjọ karun un oṣu keje ni ẹgbẹ awọn olukọ agba ni awọn ile ẹkọ giga fasiti to n bẹ loriẹede yii labẹ asia SSANU ati awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ, NASU kede sita pe ko si nnkan ti yoo yi ero wọn pada lori ifẹhonuhan ti wọn fẹ gunle.

“Rara, lẹyin ti ipade wa lulẹ lọsẹ to kọja, a ko ti gbọ nkankan lati ọdọ ẹnikẹni , ti awọn ọmọ ẹgbẹ kaakiri orilẹede yoo parapọ lati se ifẹhonuhan.” Makolo sọ fun ileeṣẹ iroyin Channels

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ijọba apapọ kuna lati wa ojutu si nnkan ti awọn ẹgbẹ naa n bẹrẹ lẹyin ti wọn gunle iyanṣẹlodi ni oṣu diẹ sẹyin.

O tẹsiwaju pe lẹyin ifẹhonuhan to ba waye ti awọn yoo tun gbe ifẹhonuhan lọ si ilu Abuja.

“To ba di ọjọ kejidinlogun, a yoo se ifẹhonuhan ni olu ilu Abuja, lẹyin eyi , ti ijọba ko ba wa nnkan se si, a yoo pada sori tabile ijororo wa.

“Awọn ẹgbẹ mejeeji yoo jiroro lori igbesẹ to kan ,”

Ni oṣu kẹta ọdun yii ni ẹgbẹ SSANU ati NASU ti kọkọ gunle iyanṣẹlodi sugbọn sibẹsibẹ ọrọ naa ko ni iyanju.

Ni oṣu kẹfa bakan naa, NASU ati SSANU fun ijọba apapọ ni gbe deke ọsẹ meji lati san owo ti wọn awọn ọmọ ẹgbẹ, ti wọn si dunkoko pe awọn yoo ti awọn ile ẹkọ ti ijọba ba kọ.

“A n bẹrẹ pe ki ijọba san owo oṣu mẹrin ti wọn jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ laarin ọsẹ meji.

“Ti ijọba ba kuna, a ko ni ero mi ju pe ka ti ilẹkun awọn ile ẹkọ lorilẹede Naijiria,” Peter Adeyemi akọwe ẹgbẹ NASU ninu lẹta ti Aarẹ SSANU ka sita.