Ibadan Oloolu Masquerade: Ojúmitó kan ní ìbọn kò ran Oloolu àmọ́ ọpẹ́ ọlọ́pàá tó kojú jàǹdùkú, ọ̀rọ̀ kò bá bẹ́yìn yọ

Oríṣun àwòrán, Twitter
Rogbodiyan bẹ silẹ ni ilu Ibadan ni igba ti awọn agbẹbọn ṣe ikọlu si egungun to gbajugbaja julọ, ti wọn n pe ni Oloolu ni ipinlẹ Oyo.
Iroyin naa ni wi pe Ọga Ileeṣẹ ọlọpaa ni Agugu lo gba egungun ọhun silẹ lọwọ awọn jaduku naa.
Iroyin ọhun ni Oloolu ti orukọ rẹ n jẹ Oloye Kazeem Omotoso Ifasuyi n lọ ṣe etutu lati bẹ awọn agba wi pe ki ojo le rọ, ni awọn janduku ṣe ikọlu si loju ọna, ti wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn laibikita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Ẹ fi ilẹ̀ tí a kò lò hááyà fáwọn darandaran bíi ibùdó ọ̀sìn màálù - Tinubu
- Ondo ló lékè nínú ìpínlẹ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus júlọ ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
- Ìhòhò ọmọlúàbí ní òṣèrébìnrin yìí fi lọ sí àmi ẹ̀yẹ tí wọ́n pè é sí
Oloolu naa ni wọn sọ wi pe ibọn ko ba amọ ibọn ba alatilẹyin rẹ kan.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn gba egungun naa silẹ lọwọ awọn to gbe ibọn, ti wọn gbe ada naa.
''Baba n gbe ẹbọ lọ nitori awọn araalu Ibadan ki ojo le bẹrẹ si ni rọ, amọ awọn eniyan ko gba ki o gbe ẹbọ ọhun silẹ nibẹ.
''Lẹyin naa ni awọn janduku naa wa pẹlu ibọn, ti wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn ni gbogbo agbegbe naa.
''Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa agbegbe Agugu to ṣiṣẹ takuntakun lati koju awọn janduku naa''
''Amọ, ọpọlọpọ eniyan ni wọn ṣeṣe ninu rogbodiyan naa, ti eniyan kan lara awọn ololufẹ Oloolu si ba iṣẹlẹ naa lọ.''

Oríṣun àwòrán, Twitter
Amọ, iroyin miran sọ wi pe, o to eniyan meji si mẹta ti o ku ninu iṣẹlẹ naa, ti awọn aladugbo si bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn nitori iro ibọn kaakiri.
Awọn eniyan farapamọ, ti awọn eniyan si yẹra fun agbegbe naa, titi ọlọpaa fi de ibi iṣẹlẹ naa
Amọ, igbiyanju wa lati ba Oloolu tabi ọlọpaa sọrọ ka le mọ ẹkunrẹrẹ iroyin nipa rogbodiyan naa lo jasi pabo nitori wọn ko gbe ẹrọ ilewọ lasiko ti a pe wọn.















