Naked Stage Appearance: Corinne Masiero fi ìhòhò ọmọlúàbí lọ sí àmi ẹ̀yẹ bíi ti Oscar

Corinne

Oríṣun àwòrán, EPA

Gbajugbaja oṣere kan fi honu han nibi ayẹyẹ ami ẹyẹ César eyi to jẹ pe ijọba n lo gẹgẹ bi akitiyan rẹ lati ṣe igbelarugẹ aṣa paapaa lasiko ajakalẹ arun Coronavirus yii.

Oṣere ẹya Faranse naa, Corinne Masiero to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta wọ aṣọ ti wọn fi awọ ẹranko rakunmi ṣe, ko to wa di pe o bọ ara rẹ sihoho lori itage idije Ami Ẹyẹ Orilẹede Faranse kan to jẹ ẹlẹgbẹẹ Ami Ẹyẹ Agbaye Oscar.

O ti le loṣu mẹta ti wọn ti gbe awọn ile iworan sinima ti pa ni ilẹ Faranse.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Nibi ami ẹyẹ ọhun, fiimu to jawe olubori ni "Dark Comedy Adieu Les Cons (Goodby Morons) ti Albert Dupontel ṣe.

Fiimu to ṣafihan bi iya to n ṣaarẹ gidi gidi ṣi ṣe n wa ọmọ rẹ to sọnu lo gba ami ẹyẹ César meje to si tun gba ami yẹ fun ọkan lara awọn oludari ere to dangajia ju.

Ni wọn ba pe arabinrin naa, Corinne Masiero si ipele ti itakete siraẹni nibi ayẹyẹ naa lọjọ Ẹti ko wa fun ẹni ti aṣọ wiwọ rẹ gbegba oroke ju ni ami ẹyẹ.

Corinne

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Bi Corinne ṣe kọkọ mura rèé

Afi to ya awọn to wa wa ninu gbọngan lẹnu pẹlu bo ṣe bọ aṣọ to si wa ni ihoho kolongo lori itage lati ṣalaye ọrọ to kọ si ara pe "bi ko ba si aṣa, ko sí jọ iwaju" eyi to kọ si bẹbẹrẹ idi.

Bakan naa ni Masiero tun fi ọrọ ranṣẹ si olootu ijọba ilẹ Faranse, Jean Castex, to kọ ọ̀rọ̀ si ẹyin rẹ pe "Ẹ fun wa ni iṣẹ ọnà pada, Jean."

Corinne

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn oṣere ẹgbẹ rẹ to ku atawọn oludari fiimu naa ti pe fun awọn nkan yii kan naa lasiko ti eto n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ jijà ní ọmọ ọdún méjì, inú mi dùn pé bàbá mi fi mí sí ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ jíjà - Tijani Azeez

"Awọn ọmọ mi le lọ si Zara ṣugbọn wọn o le lọ si ile fiimu sinima... ko ye mi," eyi ni oṣere kan Stephane Demoustier sọ ni bo ṣe n gba ami ẹyẹ tirẹ.

O n sọrọ nipa gbagede itaja aṣọ nla kan ti awn eeyan ma n lọ loore koore ṣugbọn lati igba ti ijba ti gbe awọn ile fiimu tipa lo ti n kan awọn araalu lara.

Corinne

Oríṣun àwòrán, EPA

Torinaa, wọn ri ibi ayẹyẹ ami ẹyẹ ti ijọba n ṣe agbatẹru rẹ yii lati sọrọ soke ni gbogbo ọna amọ ọna ti Corinne gba gbe tirẹ yọ yatọ.

Inu oṣu kejila ọdun to kja ni ọgọọrọ awọn oṣere, oludari ere itage, awọn olorin to fi mọ awọn ololufẹ wọn lagbo idanilaraya ati aṣa tu jade lati fi ẹhonu han ni Paris atawọn ilu nla nla mii lodi si bi ijọba ṣe ti awọn gbagede aṣa pa.