Singer Barry Jhay: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa olórin tàkasúfé, Barry Jhay

Oríṣun àwòrán, Barry Jhay
Wọn bi Oluwakayode Junior Balogun, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Barry Jhay lọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 1993.
Ilu Ibadan ni Barry Jhay ti wa, lati idile Alhaji Sikiru Ayinde Barrister, to jẹ ọkan pataki lara awọn gbajumọ ninu orin Fuji ati were nilẹ Yoruba ati kaakiri agbaye.
Ọkan ninu orin baba rẹ lo kọ yii, afi bii pe Alayinde Barrister gangan lo n kọrin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Iya rẹ jẹ akọbi ọmọbinrin gbajugbaja olorin Naijiria, Ik Dairo torinaa ẹjẹ orin kikọ n ṣan ninu idile wọn ni bi aṣa Yoruba.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Barry Jhay funrarẹ sọ ninu fidio kan to fi sita pe idile olorin meji tan yanyan loun ti jade.

"Ile orin meji mo ti jade wa, ile orin Fuji ati ile orin Juju. Iya mi ni akọbi ọmọbinrin gbajugbaja olorin I.K Dairo, eekan olorin naa si ni baba to bi mi".
Oluwakayode ni lati ọmọ ọdun meje loun ti bẹrẹ bo tilẹ jẹ pe oun ko kọkọ fẹ fi orin kikọ ṣe iṣẹ pẹlu bi oun ṣe ni ẹbun rẹ amọ lẹyin iku baba rẹ, ni oun mọ pe afi ki oun ṣaa bẹrẹ orin kikọ.
Barry Jhay gbagbọ pe awọn orin kan ti oun n kọ kii ṣe oun gangan lo n kọ, latọdọ baba oun lo ti n wa.
Ọpọlọpọ igba lo maa n ṣaaro baba rẹ to jẹ gbajugbaja agba ọjẹ olorin ọmọ Yoruba, oloogbe Alhaji Sikiru Ayinde Barrister.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2

Oríṣun àwòrán, Barry Jhay
Ni 2018, Barry Jhay jawe olubori gẹgẹ bii akorin to ṣẹṣẹ jade lọdun naa ninu ami ẹyẹ City People.
Bẹẹ naa ni wọn tun fa Barry Jhay kalẹ fun ami ẹyẹ ẹni ti irawọ rẹ tan ju lọdun naa lọhun.
Lọdun to tẹle, Barry Jhay gba ami ẹyẹ gẹgẹ bii akọrin ti irawọ rẹ tan julọ nibi ami ẹyẹ Headies Award, iyẹn lọdun 2019.
Lẹyin ti Barry Jhay bẹrẹ si n gba awọn ami ẹyẹ wọnyii lo bẹrẹ si n gbajumọ si, bẹẹ lawọn ololufẹ rẹ bẹrẹ si n pọ si.
Bi awọn eeyan ṣe n fẹ tirẹ loju aye naa wọn n gba tirẹ lori ayelujara, koda, iye eeyan to n tẹle loju opo Instagram rẹ ku diẹ ko pe ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ.
Bakan naa ni ileeṣẹ Instagram tun fi ountẹ lu oju opo Barry Jhay gẹgẹ bii eyi to dantọ.
Loju opo Instagram rẹ ọhun ni Barry Jhay ti kede pe oun jẹ ọka lara awọn to n gbe orin jade labẹ asia ileeṣẹ CashNation Entertainment.
Gẹgẹ bii ohun to fi soju opo Instagtram rẹ ọhun, oun tun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ to n ṣe aṣọ, iyẹn, XVI-XII-X.
Lọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2021 ni iroyin kan gbode pe ọkan lara awọn oludari ileeṣẹ CashNation Entertainment naa, Kashy Godson dagbere faye lorilẹ-ede Ghana.
Barry Jhay jẹ ọkan Pataki lara awọn olorin ti ileeṣẹ CashNation Entertainment n gbe jade ti irawọ rẹ si ti tan.
















