AstraZeneca vaccine: Ìdí tí orílẹ̀èdè Denmark àti Norway ṣe wọ́gilé abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Naijiria sì ń gbà rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn orilẹ-ede kan ti dawọ lilo abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti Oxford-AstraZeneca ṣe duro lẹyin iroyin to sọ pe abẹrẹ naa maa n fa ẹjẹ didi.
Lara awọn orilẹ-ede naa ni Denmark ati Norway.
Abẹrẹ ọhun ti Oxford-AstraZeneca ṣe ni wọn ko wọle si Naijiria labẹ eto Covax, ninu eyii ti Aarẹ Muhammadu Buhari, igbakeji rẹ, Yemi Osibajo, atawọn gomina ipinlẹ kan pẹlu awọn oṣiṣẹ wọn ti gba.
Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin Reuters ti kọkọ jabọ pe ọkunrin kan dero ọrun lẹyin to gba abẹrẹ ọhun ni Sicily, ni Italy.
Ṣugbọn oriṣiriṣi ajọ eleto ilera kaakiri agbaye lo ti n sọ pe abẹrẹ naa ko mu ewu kankan lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun apẹre, ajọ European Medicines Agency, EMA, sọ pe "ko si ẹri aridaju kankan pe abẹrẹ naa n fa ẹjẹ didi gẹgẹ bii awọn kan ṣe sọ."
"Anfani to wa ninu gbigba abẹrẹ ọhun pọ ju ewu to wa ninu rẹ lọ, nitori naa, awọn eeyan le tẹsiwaju lati maa gba a."
Nilẹ Gẹẹsi, ajọ Medicines and Healthcare products Regulatory Agency, MHRA, sọ pe ko si ẹri pe abẹrẹ ọhun lewu ati pe eeyan le ni ẹjẹ didi funra rẹ lai ṣe pe o gba abẹrẹ naa ṣaaju.
Ẹwẹ, ijọba orilẹ-ede Thailand ti sun akoko ti wọn yoo bẹrẹ si n fun awọn eeyan ilẹ wọn labẹrẹ ọhun nitori awọn iroyin to n jade nipa rẹ.
Olori ijọba ilẹ naa lo yẹ ko kọkọ gba abẹrẹ ọhun loju gbogbo ara ilu lọjọ Ẹti, ṣugbọn o ti sun akoko gbigb rẹ siwaju.
Nnkan bii miliọnu marun eeyan nilẹ Yuroopu lo ti gba abẹrẹ naaa ti Oxford-AstraZeneca ṣe, ṣugbọn nnkan bii ọgbọn eeyan lo n pariwo ẹjẹ didi.
Ni Naijiria, bo tilẹ jẹ pe Aarẹ, igbakeji rẹ, awọn gomina kan, awọn alabaṣiṣẹ wọn atawọn lọbalọba kan ti gba abẹrẹ naa, ọpọ ara ilu lo n sọ pe awọn ko tii ṣetan lati gba abẹrẹ ti wọn ayafi ti wọn ba ri ẹri aridaju pe abẹrẹ naa ko mu ewu lọwọ.
Idi ree ti ileeṣẹ to n ri si eto ilera alabọde ṣe sọ ninu atejade kan pe abala abẹrẹ Oxford-AstraZeneca ti Naijiria gba kii ṣe eyii to ni kọnunkọhọ ninu.
Alukoro ileeṣẹ ọhun, Mohammad Ohitoto sọ pe awọn to ti gba abẹrẹ naa ni Naijiria ko ṣafihan ami pe o mu ewu lọwọ.
Ati pe awọn orilẹ-ede bii Spain ati United Kingdom ni awọn n tẹle, lẹyin ti wọn gbe oṣuba kare fun abẹrẹ naa.















