Covid-19 prevention: NAFDAC buwọ́lu lílò abẹ́rẹ́ àjẹsára Oxford-AstraZeneca

vaccine

Oríṣun àwòrán, @PulseNigeria247

Ajọ to n mojuto lilo ati akoso ounjẹ ati oogun ni Naijiria, NAFDAC, ti kede pe ijọba ti buwọlu lilo abẹrẹ ajẹsara Oxford-AstraZeneca fun kikoju aarun Covid-19.

Ọga agba ajọ naa Dokita Mojisola Adeyeye lo kede ọrọ yii, to si ni awọn ti ni ikapa lati gbe abẹrẹ naa pamọ saaye to tutu niwọn to yẹ, iyẹn "2 to 8 degree centigrade."

Arabinrin Adeyeye sọ pe awọn si n sayẹwo abẹrẹ ajẹsara mii sugbọn abẹrẹ ajẹsara Oxford Astra-Zeneca ti awọn yẹ wọ fi han pe yoo koju ẹda arun Covid-19 ilẹ Gẹẹsi to wọ Naijiria.

O fikun pe titi di asiko taa n sọrọ yii, awọn ko ti ri ẹda arun Covid-19 to ṣẹyọ lati orileede South Africa wa.

Awọn ijọba Naijiria ko tii sọ igba t'awọn araalu yoo bẹrẹ si ni gba abẹrẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Oladele Ogbeyemi Albert: Irin tí mò ń lò máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀mí kí ń tó gbẹ́ wọn sóh

Ohun tawọn alasẹ sọ ni pe ipenija gbigbe abẹrẹ ajẹsara naa lo se idiwọ fabẹrẹ ajẹsara ẹgbẹrun lọna ọgọrun tawọn n reti losu yii.

Laipẹ yi ni ajọ ilera agbaye, WHO, faṣẹ si lilo abẹrẹ ajẹsara yii fun lilo pajawiri.

Awọn onimọ sayẹnsi to se agbekalẹ abẹrẹ yii ni a gbọ pe wọn peelo rẹ ki o ba le koju kokoro arun Covid-19 lara awọn eeyan.