Osun bank robbery: Ọlọ́pàá ní àwọn olè jí N600,000 nínú ATM l'Osun, àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti lé wọn wọ inú igbó

Aworan banki b ti ole ja ATM

Oríṣun àwòrán, Agunbe Voice

Ọrọ ti jẹyọ lati ọdọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun lori awọn eeyan meji to padanu ẹmi wọn nigba tawọn ole yabo ile ifowopamọ kan ni Okuku.

Alukoro ọlọpaa arabinrin Yemisi Opalola to ba BBC sọrọ ni ọkunrin ọlọlkada kan ati baba agbalagba to ni ipenija arun ọpọlọ lawọn ole naa pa.

Awọn eeyan meji ni wọn yinbọn pa.Wọn sọ fun wa pe baba agbalagba alagana kan ati ọlọkada ni wọn pa''

Yemisi tẹsiwaju pe kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Osun Olawale Olokode ti ni kawọn agbofinro ṣe awari awọn ole naa laifasiko ṣofo.

Ilu Okuku ni ilu Gomina tẹlẹri Olagunsoye Oyinlola.

Adigunjale

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti ṣalaye fun BBC Yoruba awọn adigunjale to yabo ile ifowopamọ WEMA ati Micro Finance niluu Okuku ko ri awọn banki naa wọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa fun ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola sọ pe owo to to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira ni wọn ri ko ninu ẹrọ igbowo(ATM machine) lẹyin ti wọn ko raye wọle nitori banki naa ti pari iṣẹ ti awọn oṣiṣẹ si ti lọ sile.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni oṣiṣẹ banki WEMA kan ti ko tii lọọle lawọn janduku naa ni ko ṣi ẹrọ ATM fun wọn nibi ti wọn ti ji owo naa ko lọ.

Àkọlé fídíò, Mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ jijà ní ọmọ ọdún méjì, inú mi dùn pé bàbá mi fi mí sí ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ jíjà - Tijani Azeez

''Awọn adigunjale naa fẹsẹ fẹẹ lẹyin ti wọn ri awọn ọlọpaa to n bọ lati ọọkan.

Ẹwẹ, Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Osun fun ra rẹ lo ṣaaju awọn ọlọpaa kogberegbe lọ bawọn ọdaran naa.

Amọ, awọn ọlọpaa ti le awọn ole naa wọn inu igbo lọ pẹlu igbagbọ pe, wọn si le ri wọn mu nibẹ,'' Opalola lo sọ bẹẹ.

Àwọn adigunjalè yabo báńkì l'Osun, ọ̀gá ọlọ́pàá kojú wọn pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá kògbérègbéè

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Osun lo sọ pe awọn adigunjale ti yabo ile ifowopamọ kan niluu Okuku nipinlẹ Osun lọsan Ọjọbọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun to ba BBC Yoruba sọrọ, Yemisi Opaola lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Adigunjale

Oríṣun àwòrán, OTHER

Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye pe Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Osun fun ra rẹ lo ṣaaju awọn ọlọpaa kogberegbe lọ si banki naa lati mu awọn ọdaran ọhun.