Access Bank: Babaláwo ní òun yóò t'ọwọ́ Ifá bọ̀ọ́, tí Access Bank kò bá dá owó ìyá òun pádà

Oluwo Jogbopdo Orunmila

Oríṣun àwòrán, Instagram/Oluwu Jogbodo Orunmila

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ṣe kii ṣe pe ile ifowopamọ Access bank n fi ori ọka họ imu bayii?

Babalawo kan to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe, Oluwo Jọgbọdọ Orunmila ti sọ fun ile ifowopamọ naa pe, ti ko ba ẹgbẹrun lọna igba le mẹfa (₦206,000) owo mama oun to yọ pada, titi aago mẹrin irọle ọjọ Ẹti ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ yii, oun yoo ti ọwọ Ifa bọ ọ.

Oluwo Jọgbọdọ ni ti wọn ba kọ lati ṣe atunṣe, oun atawọn awo mii yoo lọ fi idan han wọn ni ẹka Access bank ti wọn ti yọ owo mama oun.

O ṣalaye pe, Ifa lo n ka oun lọwọ ko tẹlẹ lori ọrọ naa, bi bẹẹ kọọ, oun mọ ohun ti oun le ṣe lati wa owo naa rii ni kiakia.

L'Ọjọbọ ni Oluwo fun ile ifowopamọ Access Bank ni ọjọ kan pere, lati ṣe awari oṣiṣẹ rẹ to ṣ'okunfa bi ẹgbẹlẹgbẹ owo fi ranṣẹ si mama rẹ ṣe poora, ki wọn si da owo naa pada ni kiakia.

Oluwo ṣalaye pe, ẹgbẹrun lọna ọgọsan owo naira loun kọkọ fi ranṣẹ si mama oun lọjọ ibi rẹ laipẹ yii, ki oun to tun ṣe afikun owo naa pẹlu ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta mii.

Jọgbọdọ Orunmila sọ pe, nigba ti mama oun fẹ gba ninu owo ọhun ni ẹka ile ifowopamọ Access Bank kan ni o bẹrẹ si ni awọn idojukọ kan eleyi ti ko jẹ ko ri owo gba.

Oluwo wa gba mọmọ rẹ ni imọran lati lọ sọ ohun to ṣẹlẹ ni ẹka banki naa, mọmọ ko beṣu bẹgba, o lọ sibẹ, nibẹ gan an ni wọn ti sọ fun mama pe kaadi ATM ko ṣiṣẹ daadaa wi pe o nilo omiiran.

Oluwo ni lẹyin ti mọmọ gbiyanju lo kaadi ATM tuntun to ṣẹṣẹ gba fi gba owo ni o bẹrẹ sii ri awọn atẹjiṣẹ ajeji pe o ti gba owo, eleyi ti ko si rii bẹẹ.

''Lẹyin naa ni mo sọ fun mọmọ mi lati lọ si ẹka ile ifowopamọ naa lẹẹkan sii pẹlu aburo mi ki wọn si mu ẹri bi banki naa ṣe jawo ninu apo ikowosi rẹ lọwọ,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.

Jọgbọdọ Orunmila ni ''ohun ti a ri nipe ileeṣẹ ifowopamọ Access Bank ti yọ ẹgbẹrun lọna o le mẹfa naira ninu apo ikowosi mama mi lasiko ti wọn fun un ni kaadi ATM mii.''

O fikun ọrọ rẹ pe Banki Access tun sọ fun mama oun pe ki o buwọ luwe pe oun lo gba owo naa, bo tilẹ jẹ ko mọ bi eeyan ṣe le gba owo lori aapu to wa lori foonu.

Oluwo ni lẹyin naa loun pe ile ifowopamọ Access lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, ṣugbọn o ni wọn ko tii ṣe ohun kan lori rẹ.

Ẹwẹ, ile ifowopamọ Access Bank pada fesi si ọrọ ti Oluwo fi lede loju opo Twitter rẹ, wọn dupẹ lọwọ rẹ wọn si tọrọ aforijin lori ohun ti oju mama rẹ ti ri.

Access Bank beere fun nọmba apo ikowosi mama ati ẹka ileeṣẹ wọn ti iya naa lọ, ki awọn le sẹ iwadii to peye lori ohun to ṣẹlẹ.