Covid-19 Vaccines: Sanwo-Olu ní ìpínlẹ̀ Eko yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa fáwọn èèyàn lábẹ́rẹ́ àjẹsára láìpẹ́

Oríṣun àwòrán, facebook/okikionline
Ninu awọn to ti ri abẹrẹ naa gba la ti ri ipinlẹ bi Eko ti ọwọja arun naa ti peleke ju lọ.
Eko
Ipinlẹ Eko ri abẹrẹ 507,000 Astra-Zeneca gba labẹ eto abẹrẹ ajẹsara ọfẹ ti Covax ṣeto.
Ni nkan bi ago marun un aarọ ọjọ Iṣẹgun ni abẹrẹ naa balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Babajide Sanwo-Olu
Ìpínlẹ̀ Eko yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa fáwọn èèyàn lábẹ́rẹ́ àjẹsára covid-19 láìpẹ́- Sanwo-Olu
Abẹrẹ ajẹsara Oxford-AstraZeneca ti balẹ bagẹ si ipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keṣan an oṣu kẹta ọdun 2021 yii.
Gomina Babajide Sanwo-Olu kede loju opo Twitter rẹ pe oun ti gba agbẹrẹ ajẹsara coronavirus lati ọwọ ijọba apapọ.
Sanwo-Olu ni idunnu lo jẹ fun oun pe abẹrẹ naa ti wọ ipinlẹ Eko.
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC tó mú Wakili ti gba òmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Iyakangu
- Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams
- Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje
- Nkán ìbànújẹ ni bí ọlọ́pàá ṣé ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC mọ́lé nítorí Wakili- Adari OPC
- Áwa Hausa tá a wà l'Ogbomoṣọ ti di Yorùbá- Oba Haruna Sabo Ogbomoso
- Ọ̀rọ̀ aàbò ní Nàìjíríà ti di kí olórí dorí ẹ mú- Femi Falana
Gomina ipinlẹ Eko ṣalaye pe gbogbo ilana ati fawọn olugbe ipinlẹ ni abẹrẹ ọhun ni ijọba yoo tẹ le.
Sanwo-Olu ko ṣai rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati maa tẹle ilana ati gbogun ti ajakalẹ arun covid-19 nipa wiwọ ibomu, fifọwọ ni gbogbo igba ati tita kete si ara ẹni.
Ijọba ipinlẹ Ogun lo kọkọ gba abẹrẹ naa lọjọ Aje ki o to de si ipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO lo ṣagbatẹru abẹrẹ naa labẹ eto COVAX.
Kwara
Ni ipinlẹ Kwara awọn naa gba abẹrẹ wọn lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
Oxford AstraZeneca Vaccine naa balẹ̀ bagẹ si papakọ ofurufu ilu Ilorin ni nkan bii ago mẹjọ abọ alẹ ọjọ Isẹgun nibi ti ikọ ti ijọba ipinlẹ yan ti tẹwọ gba a labẹ idari akọwe agba ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, facebook/okikionline
Ondo
Ijọba ipinlẹ Ondo naa ti tẹwọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 to le ni ẹgbẹrun marunlelaadọrin abọ (75,570).
Alẹ ọjọ Iṣẹgun lo balẹ si papakọ ofurufu ipinlẹ naa ti awọn oṣiṣẹ eleto ilera alabọde ipinlẹ naa si tẹwọ gba a.

Oríṣun àwòrán, facebook/okikionline
Ekiti
Lowurọ Ọjọru ni ipinlẹ Ekiti naa darapọ mọ awọn ipinlẹ akẹgbẹ rẹ to ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Loju opo Twitter gomina ipinlẹ naa lo ti hande pe Gomina Fayemi ati igbakeji rẹ Otunba Bisi Egbeyemi ni yoo maa dari awọn ara ipinlẹ naa lati tẹwọ gba a nita gbangba.
Ìpínlẹ̀ Ogun ló kọ́kọ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19, bí gómìnà wọn ṣe tẹ̀ ẹ́ s'ápá rèé

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun
Ijọba ipinlẹ Ogun ti gba abẹrẹ ajẹsara ẹgbẹrun lọna aadọta lati dena itankalẹ aarun Coronavirus ni ipinlẹ Ogun.
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ni ileeṣẹ ijọba to ti gba abẹrẹ ajẹsara naa wọle ni awọn ṣi n reti ẹgbẹrun lọna aadọta miran.
Gomina naa ni awọn yoo tẹlẹ ilana aṣẹ Ajọ to n risi eto ilera awọn ọmọ Naijiria lati pin awọn abẹrẹ ajẹsara naa fun awọn eniyan to yẹ ki o gba a.
Bakan naa ni gomina naa fikun wi pe awọn ti ṣe ilana awọn ileewosan gbogboogbo, aladani kaakiri ipinlẹ naa to fi mọ ijọba ibilẹ ti yoo pin awọn abẹrẹ ajẹsara naa.
Saaju ni gomina naa ti ni awọn eleto ilera, awọn agbalagba ni yoo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara naa gẹgẹ bi aṣẹ Ajọ NPHCDA.
Gomina Abiodun ni abẹrẹ ajẹsara naa mu ọna abayọ de si igbeaye awọn eniyan ti arun Coronavirus daru lati bi Oṣu mẹtala sẹyin.
'A o kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara akọkọ, a tun wa gba eleekeji ti yoo mu ki eroja ara to n gbogun ti arun jipepe si'.
Amọ, gomina ipinlẹ Ogun ni awọn yoo ṣi ma a tẹle awọn ilana ofin to de arun Coronavirus, nitori abẹrẹ aarun Coronavirus ko ni jẹ ki arun naa ni agbara lara awọn eniyan.
Ipinlẹ Ogun ni wọn ti kọkọ kede arun Coronavirus ni Naijiria, lẹyin ti arakunrin ọmọ ilẹ Italy de si Naijiria ni Ọjọ Kẹtadinlọgbọn, Oṣu Keji, ọdun 2020.
Iyatọ iye abẹrẹ tawọn ipinlẹ kọọkan n gba ko sẹyin bi ọwọja arun naa ba ti ṣe peleke si ni ipinlẹ kọọkan.
Labala labala ni wọn yoo maa pin abẹrẹ yi to siṣe wi pe lọpọ igba, awọn oṣiṣẹ ilera, agbalagba ati awọn eekan ijọba lo ti n kọkọ gba abẹrẹ naa.
Fawọn araalu mii to ba fẹ gba ijọba ti ṣeto iforukọsilẹ loju opo ayelujara.
Miliionu mẹrin abẹrẹ ajẹsara yi ni Naijiria kọkọ ri gba labẹ eto abẹrẹ ọfẹ ti igbimọ COVAX ṣe fawọn orileede agbaye.Kwara, Eko, Osun ati Nassarawa, awọn ipinlẹ to ti ri abẹrẹ Covid-19 gba

Oríṣun àwòrán, facebook/okikionline












