Wakili Arrest: "Nnkan ibanujẹ ni bi ọlọpaa ṣe ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mọle nitori Wakili"- Adari ẹgbẹ́ OPC

Adari ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC nipinlẹ Ọyọ, Arakunrin Rotimi Olumọ ti gbarata wi pe nnkan ibanujẹ gbaa ni bi ọlọpaa ṣe sọ awọn ọmọ ẹgbe OPC kan si atimọle lori ẹsun wi pe wọn mu Iskilu Wakili, ẹni ti iroyin rẹ gbode kan wi pe o n yọ awọn eeyan Ibarapa lẹnu.
Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ l'ọjọ Aje, Olumọ ni lati ọjọ pipẹ wa ni awọn eeyan agbegbe naa ti fi ẹsun kan wi pe Wakili n yọ wọn lẹnu ti ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ologun ati ijọba ko si ri nnkan ṣe sii.
O tẹsiwaju wi pe ikọ Amọtẹkun naa ti gbiyanju lati ẹni afurasi naa, ṣugbọn pabo lo jasi.
- Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje
- Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Báwo láwọn ọmọ kékèéké méjìla ṣé kú s'odò lẹ́ẹ̀kàn náà?
- A mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nípa Iskilu Wakili àti ìgbésẹ̀ àwọn ọlọ́pàá, ìfẹ́ ẹ̀yin ará ìlú ni yóò ṣẹ - Makinde
- Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé owó orí ni wọ́n fi n san owó oṣù àwọn olùkọ́ ilé ìwé náà, àwọn ọmọ lẹ́tọ̀ọ́- IEDPU
O ni, "Bi ijọba ko ba le gba wa, ti ọlọpaa ko le ba wa mu un, ti ileeṣẹ ologun ko le wa ba wa mu un.Awọn Amọtẹkun lọ sibẹ wọn ko ri Wakili mu."

"Eyii lo mu ki OPC sọ pe ki wa ni ohun ti awọn n tori ẹ ṣe ẹgbẹ yii?
Nitori ki eeyan ma baa jiya ni eeyan ṣe n ya majiya l'Ọffa".
O ni irora ti awọn eeyan agbegbe naa n ke lori awọn ọkanọjọkan ẹsun ọdaran bi i ijinigbe-gba-owo, ṣiṣe dukiya lofo ati iṣekupani ti wọn fi kan Wakili lo mu ki ẹgbẹ OPC gbe igbese lati faa le ijọba lọwọ, ṣugbọn dipo ki ijọba gboṣuba kare fun wọn, o ni atimọle ni ọlọpaa sọ awọn eeyan to mu Wakili si.
O ṣe alaye wi pe ajinigbe kan ti ọwọ ẹgbẹ naa tẹ lo mu wọn de ibi ti Wakili ti wọn n ṣiṣẹ fun n gbe.
O ni awọn ọmọ lẹyin Wakili doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ki ọwọ palaba wọn to segi ninu igbo ti wọn fi ori pamọ si.
O tẹsiwaju wi pe Wakili gan an ti fẹ salọ ki wọn ti gbaa mu. Lẹyin ti wọn si ri i mu tan lo bẹrẹ sini dibọn gẹgẹ bi ẹni ti ko riran ti ko si le sọrọ.
O parọwa si ijọba lati tu awọn ọmọ ẹgbẹ mẹrin to n bẹ ni atimọle sile lati dena rogbodiyan. O ni ko bojumu ki eeyan ṣoore daran.
O ni, "Ṣe eeyan maa ṣe oore ko di ibi ni? Ṣe eeyan maa n gba iran rẹ silẹ lọwọ iya ki o tun di ogun ni?"
Lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to n bẹ ni atimọle bayii ni Hassan Rahaman ati awọn mẹta mii.
Nibayii ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti fesi lori ọrọ naa ninu atejade kan ti wọn fi lede lati ọwọ alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Fadeyi Olugbenga.
Ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun kan wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC dana sun ile Wakili ẹni ọdun marundinlọgọrin ti wọn fi ẹsun kan, bẹẹ sini wọn tun ṣekupa obirinrin kan ninu ile naa.
Ṣugbọn gbogbo ẹsun yii ni ẹgbẹ OPC jiyan rẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.
Gomina Ṣeyi Makinde naa ti ọrọ lede lori iṣẹlẹ naa l'ọjọ Ajẹ.
Ninu Ikede ti o ṣe lori opo ikansira ẹni Twitter, Makinde ni gbogbo iṣẹlẹ naa lo han si ijọba ipinlẹ Ọyọ.
O ni, "A mọ ohun to ṣẹlẹ nipa Iskilu Wakili ati ọwọ ti ọlọpaa fi mu ọrọ naa. Mo fẹ fi daa yin loju pe a n sa gbogbo ipa wa lati ja fun ẹtọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ naa."
A mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nípa Iskilu Wakili àti ìgbésẹ̀ àwọn ọlọ́pàá, ìfẹ́ ẹ̀yin ará ìlú ni yóò ṣẹ - Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọrọ lẹyin ti ọwọ ikọ alabo OPC tẹ afurasi kan ti wọn fẹsun kan pe o jẹ baba isalẹ awọn ajinigbe lagbegbe Ibarapa nipinlẹ naa, iyẹn Iskilu Wakili.
Makinde sọ pe ifẹ awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni yoo ṣẹ lori ọrọ naa.
Nigba to n sọrọ loju opo Twitter rẹ, Makinde ni "a mọ gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nipa Iskilu Wakili ni Kajola, lagbegbe ijọba ibilẹ Ibarapa ati ọwọ ti awọn ọlọpaa fi mu iṣẹlẹ naa."
"Mo fẹ fi da yin loju pe gbogbo igbẹsẹ to yẹ ni a n gbe ki abo le wa fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo, ki ifẹ wọn si le ṣẹ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Gomina ọhun wa rọ awọn olugbe ipinlẹ Oyo ki wọn maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya rara, ki wọn ma si da ofin ṣe lọwọ ara wọn.
Lẹyin naa lo fi nọmba ipe pajawiri "615" lede ti awọn eeyan ọhun le maa pe ni gbogbo igba ti wọn ba fẹ fi ọrọ eto abo to awọn ẹṣọ alabo leti.
Ni kete ti Makinde sọrọ naa tan ni awọn eeyan bẹrẹ si n fesi, ti wọn si n fi erongba wọn lede lori ọrọ to sọ.
Bi awọn kan ṣe n kilọ fun gomina ọhun pe ko ma ti ọrọ oṣeku bọ eto abo awọn eeyan ipinlẹ Oyo lawọn miran n bu ẹnu ẹtẹ lu iṣejọba rẹ.
Bẹẹ naa lawọn miran n sọ pe ko lọ gba awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn wa ni ahamọ ọlọpaa lẹyin ti wọn mu afurari naa.
Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ jade lori ayelujara eyii to ṣafihan awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ọhun lẹyin ti wọn mu Wakili tan.
Pupọ ninu awọn aṣiwaju nilẹ Yoruba, bii Iba Gani Adams to jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, lo gboṣuba kare fun awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ọhun fun iṣẹ akin ti wọn ṣe lati mu afurasi naa.




















