Wakili Arrest: Wakili ti wa nilé ìwòsàn sùgbọ́n àwọn méjì tókù àti ọmọ ẹgbẹ́ OPC wà ni àhámọ́ wa- Ọlọ́pàá

Aworan Wakil ati ti Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams

Yatọ fun awọn ẹlẹgbẹ n jẹgbẹ Yoruba to n gboriyin fun ẹgbẹ Oodua Progressive Congress (OPC) pe wọn ṣe iṣẹ takun takun lati mu ẹni ti wọn pe ni ogbontarigi adunkukulaja mọni, Iskilu Wakil.

Awọn eekan oloṣelu ọmọ Yoruba naa ti n da si ọrọ naa. Lara wọn ni minisita irina ofurufu tẹlẹ ri, Femi Fani-Kayode naa kan sara si bi wọn ṣe mu adari Fulani naa.

"Mo ki ọrẹ mi ati ọmọ iya mi, Iba Gani Adams, Aare Ona Kakanfo ilẹ Yoruba ati ẹgẹ OPC ku oriire fun bi wọn ṣe ri ọkan lara awọn Fulani adunkoko mọni ati apaayan to ti wa tipẹ ninu igbo ilu Oyo, Wakili mu".

Fani Kayode fi sori ayelujara pe eyi gaan ni ọna lati tẹsiwaju.

Atẹjade Femi Fani-Kayode

Wakili ti wa nilé ìwòsàn ùgbọ́n àwọn méjì tókù àti ọmọ ẹgbẹ́ OPC wà ni àhámọ́ wa- Ọlọ́pàá

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Oyo ti sàlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ ni ìlú Kajọla ni agbègbè Ibarapa.

Nínú àtẹ̀jáde ti agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ náà, Fadeyi Olugbnga fi síta lo ti sàlàyé pé, ni dédé ààgò mẹ́sàn òwúrọ̀ òní, ọjọ́ keje, ṣù kẹta ọdún 2021 ti àwọn gbọ́ pé àwọn kan ya wọ ìlú Kajola ní ìjọba ìbílẹ̀ Ibarapá nípìńlẹ̀ Oyo.

Ọlọ́pàá ni yíya wọ ìlú náà ni láti mú Wakili to jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Fulani ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó jẹ́ bàbá ìsàlẹ̀ fún àwọn ajínígbé, afipabánilòpọ̀ àti àwọn tó n gbéni pa ni àdúgbò náà tọ fi ma ìjà tó n wáyé láàrìn àwọn Fulani àti àwọn àgbẹ̀ Yorùbá.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

O ní kété ti ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹ̀lẹ̀ ni kọmísọ́nà ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, tí ìwádìí sì fi hàn pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Oduduwa People's Congress (OPC) lo lọ si ìlú kajola, Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ wọ́n dána sun ilé Wakili náà ti wọ́n ti obìnrìn kan tí wan ko ti mọ̀ sì jọ́ná mọ́lé, wọ́n gbé Wakili afọ́jú tí ọja orí rẹ̀ si wá bi ọmọ ọdún márùnléláàdọ́rín àti àwọn ènìyàn méjì míràn.

Ní báyìí àwọn mẹ́tẹta ti wà ni àkàtà ọlọ́pàá, sùgban nítorí bi ìlera Wakili ṣe ri, kọmísọ́nà ọlọ́pàá ti ni kí wọ́n máagbe lọ sí ilé ìwòsàn, nígbà ti wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wá àwọn méjì tókù lẹ́nu wò. Bákan náà ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ń lọ fún àwọn ọmọ OPC náà pẹ̀lú nítori bi wọ́n se dáná súlé àti ẹ̀sùn ìpànìyàn.

Olugbenga ni, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Oyo ń fi àsìkò yìí rọ ara ìpínlẹ̀ Oyo lójú pé, ọlọ́pàá kò ni fi ojúṣe wọ́n sílẹ̀ láti maa fọ́wọ́ òfin mú ẹnikẹni to ba hùwà ọdaran.

Ile iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ̀ ará ìlú láti maa fi gbogbo ǹkan to bá lọ tó ilé iṣk ọlọ́pàá léti láti le fọ ìlú mọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀bàyé jẹ́.

Bákan náà ni wọ́n kéde pé, ẹnikẹ́ni tó bá nio ẹjọ́ pẹ̀lú Iskilu Wakili kó lọ si ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá agbègbè Iyagangu ẹ̀ka CID fun ìwádìí tó péye

Ó yẹ kí ọlọ́pàá gba ọdànran lọ́wọ́ OPC ni kí ṣe ki wọ́n tún ma wa ọ̀nà láti fi panpẹ́ ọba mú wọ́n- Afẹnifẹre

Ẹgbẹ́ Afenifere ti gbé sàdánkátà káre fún ẹgbẹ́ Oduduwa People's Congress (OPC) lábẹ̀ Iba Gani Adams fún ìgbésẹ̀ akin ti wọ́n gbé láti mú Wakili.

Wọ́n ni Wakili jẹ́ ògbóntarigi ògbójú ọ̀daràn tó ti n dá ilẹ̀ Ibarapa láàmú nípa, ìjínígbé, ìpànìyàn, gbígba oko olóko, àti fifi ipá bá àwọn ènìyàn lòpọ̀ lágbègbè náà.

Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ Afénifẹrẹ gbóríyìn fẹ́gbẹ́ OPC lórí bí wọ́n se mú Wakili.

Afẹnifẹre ninu àtẹjade ti akọwé ìpòlóngo ẹgbẹ́ náà fọwọ́ si Yinka Odumakin sàlàyé pé gbogbo ìgbìyànjú ọlọ́pàá ló ti já sí pàbó láti ìgbà tó ti n da ìlú láàmú.

Bákan náà ni ọlọ́pàá ti fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé, àwọn OPC àti ẹgbẹ fijilante to ku ti jọ pawọ́pọ̀ mú Iskilu Wakili ti wọ́n ni ó n da ìlú rú.

Nínú ọ̀rọ̀ agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Fadeyi Olugbenga sọ fun BBC Yoruba pe lóòtọ́ ni wan ti mú Iskilu Wakili àti pé ó ti wà ni àkàtà ọlọ́pàá lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.

Fadeyi ni ẹkúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀rọ̀ náà yóò jáde láìpẹ́.

Wọ́n ni irú iṣẹ́ ìrọ̀rùn ti OPC ṣe láti mú lówùrọ̀ òní ṣe àfihan bi ètò abò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ ṣe wúlò tó, èyí yóò sì túbọ̀ ran ètò ààbò orílẹ̀èdè yí lọ́wọ́.

Bákan náà ni Afenifẹre ni o sàn ki àwọn ọlọ́pàá gba ọ̀daran lọ́wọ́ àwọn ọmọ OPC ti wọ́n mú kàkà ti wọ́n fi n gbíyànju láti fi pànpẹ́ ọlọ́pàá mú àwọn ti ṣe iṣẹ́ akin náà.

Tani Iskilu Wakili tí wọ́n ló ń da ilẹ̀ Ibarapa láàmú?

Ọwọ́ tẹ Wakili tí wọ́n ló n dá ilẹ̀ Ibarapa láàmú.

Oríṣun àwòrán, Omoodua

Lọ́sàn òní ni fọ́ran kan jẹyọ lójú òpó Facebook pé ẹrùjẹ̀jẹ̀ tí wọ́n lò wà nídìí ìjínígbé àti àwọn ìpànìyàn tó n lọ nilẹ̀ Ibarapa ni ọwọ́ ti tẹ̀.

Nínú fọ́ràn náà ni ọikùnrin kan ṣe àfìhàn ẹni ti wọn pè ni Wakikli ọhun tó sì ń bèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ sùgbọn ti kò fèsì, nínú ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà ó fi yé ni pé ikọ̀ ẹgbẹ́ Oduduwa People's Congress (OPC) lábẹ̀ ìdári Iba Gani Adams ló mu ọkùnrin ọ̀hún.

Ó ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe ti fi ọkàn àrá ìlú bálẹ̀ pé àwọn yóò rí i mú láì ta ẹjẹ̀ sílẹ̀. O ní inú ìgbó Igangan ni àwọn ti lọ mú àwọn sì ṣetan láti fà á lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.

Àkọlé fídíò, Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC yìí ni ó ń sálọ ni àwọn ri nígbà ti àwọn de ibí ti wọn ti mú u ni òwúrọ̀ òní.

Níńu fọnran náà ni a ri bàbá àgbàlágbà kan tí wọn pè ni Wakilí, ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀rọ̀ ti wọ́n ń bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ kò fèsì bẹ́ẹ̀ ni kò lá ojú láti wo ẹnikẹni.

Wọ́n ni Igbó-ọrà ni àwọn yóò mú u lọ láti lọ fi le ọlọ́pàá lọ́wọ́, wọ́n ni ààyè ni àwọn mú u, láì sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kànkan, àti pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àgbàlagbà ni ẹni ti gbogbo ènìyàn ń pariwo pé ó ń dá wàhálà sílẹ̀ nílu Ibarapa.

Ìhà wo ni ẹgbẹ́ Myetti Allah kọ si mímú ọkùnrin náà?

Lásìkò tí ilé iṣẹ́ BBC Yoruba kan si ọkàn lára ọmọ ẹgbẹ́ Myetti Allah, Suleiman Mohammed tó tún jẹ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ Myetti Allah ni Nàìjíríà ṣàlàyé pé lóòtọ́ ni òun gbọ́ pé wọ́n mú Wakili lasàn òní.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sàlàyé pé wan pe òun pé àwọn OPC àti Amotẹkun lọ si ilé rẹ̀ ti wọn sì pa ọmọ rẹ̀ àti àti àwọn ènìyàn méjì míràn, ó ni Sunday Igboho náà wà nínú àwọn tó lọ mu Wakili ni ìlú Igangan.

Ó tún ni ọ̀pọ̀ ilé àti Màálú ni wọ́n sun níná àti pé gẹ́gẹ́ bi ìròyìn tó tẹ̀ òun lọ́wọ́, wọ́n ni Sunday Igboho pẹ̀lú wà níbẹ̀.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Agbẹ̀nusọ Miyetti Allah ni gbogbo ǹkan to bá wà ni ìkáwọ́ àwọn ni àwọn yóò ṣe láti tú Wàkílí sílẹ̀, nitori ó jẹ́ ọkàn lára àgbà ẹgbẹ́ to si ni oye nílùú Oyo.

Suleiman ni kò dájú pé ó lọ́wọ́ ninu gbogbo ẹsùn ti wọ́n fi kàn-án nítori pé ó ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nílùú Igangan ti wàhálà kànkan ko s]i sẹll títí di ìgbà ti Sunday Igboho bẹ̀rẹ̀ Wàhàlá yìí.

Ẹ̀wẹ̀, Ikọ̀ Amọtẹ́kùn nípìńlẹ̀ Oyo lábẹ́ àkóso Olayinka Togun sàlàyé fún BBC pé, àwọn kò mọ ǹkankan nípa mímú Wakili àti pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn kò sí níbẹ̀.

Títí dí àsìkò yìí, à sì n gbìyànjú láti kàn sí ìhà ti Sunday Igboho lati sàlàyé ìpa tiwọn nínú ọ̀rọ̀ náà sùgbọ́n ìpè kò tíì wọle sórí ẹ̀rọ iléwọ́ rẹ̀.