Sasa market crisis: Ìjọba àpapọ̀ kó nkan ìdẹ̀rùn fún àwọn tó kàgbákò nínú rògbòdìyàn ọjà Sasa

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Ijọba apapọ Naijiria ti fi awọn nkan amayedẹrun ranṣẹ si awọn eeyan to padaanu dukia wọn lasiko rogbodiyan to waye ni Shasha nilu Ibadan.
Minisita to wa fun amojuto ajalu, itọju ọmọniyan ati idagbasoke awujọ, Sadiya Umar Farouq, lo ko awọn nkan naa fun ijọba ipinlẹ Oyo lorukọ ijọba apapọ.
Ileeṣẹ ijọba ti minisita naa n dari fi ikede naa sita lori ayelujara Twitter rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Ileeṣẹ iroyin abẹle, Voice of Nigeria sọ pe idile 928 ati eeyan 5,568 to ti di alainilelori ni agbegbe Sabo, Ojoo ati Akinyele nijọba ibilẹ Akinyele.
- A fẹ́ kí ìjọba fòfin de àwọn darandaran tó máa ń fi ìbọn Ak47 da málúù láàrín ìlú- MURIC
- Ìjà tó wáyé ní Sasa ní Ibadan kìí ṣe ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà- Agbẹnusọ ọlọ́pàá
- Àbẹ̀wò wa si ọjà Ṣàsá rèé lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn tó wáyé nílùú Ibadan
- Ilé ẹjọ́ sọ àwọn afurasí méje sí àtìmọ́lé lóríi rògbòdìyàn tó wáyé ní ọjà Ṣaṣa
- Aáwọ̀ ọ̀dọ́ Yorùbá àti Hausa ló dá wàhálà sílẹ̀ ní Ṣásá, Ibadan - Ṣeriki Hausa
Lara awọn nkan ti wọn ko fun ijọba ipinlẹ Oyo ni apo irẹsi ati gari ẹẹdẹgbẹrun le mejidinlọgbọn (o ni kilogiraamu mẹwaa).
O ni iye kan naa fun apo ẹwa (o ni kilogiraamu mẹẹdọgbọn), kẹẹgi ororo (o ni lita ogun) mẹrindinlaadọta.
Awọn nkan mii to tun wa nibẹ ni apo iyọ mẹrindinlaadọta (oni kilogiramu ogun), apo pelebe isebẹ onihoro marundinlọgọjọ, ati paali tomato alagolo mọkanlelaadọrin.

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Oṣu Keji ni ija ẹlẹyamẹya naa waye.
- Ààrẹ Buhari àti Osinbajo nàá ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ti AstraZeneca
- Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin láhàmọ́, ọlọ́pàá Osun dóòlà ẹ̀mí arìnrìnàjò méje
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọlọ́mọ mẹ́jọ ká nítorí pé ọkọ rí àwọn òbí ìyàwó fín
- Ọpẹ́lọpẹ́ àjẹsára, ó yẹ kí n ti kú lẹ́yìn tí àwọn jàǹdúkú ṣá mi ní àdá - Oyinkansola Elebuibon
- Wọn yóò yẹgi fún àwọn ọmọ Nàìjíríà méjì lórí ikú ọmọbìnrin Takoradi tó dàwátì ní Ghana













