Takoradi girls: Iléẹjọ́ ti pàṣẹ pé kí wọ́n yẹgi fún ọmọ Nàìjíríà méjì tó mọ̀ nípa ikú àwọn ọmọbìnrin Ghana mẹ́rin

Oríṣun àwòrán, Ghana Police
Awọn ọmọ Naijiria meji kan ni wọn ti ni ki wọn yẹgi fun ni Ghana bi wọn ba kọ lati tako idajọ ile ẹjọ lẹyin ọgbọn ọjọ.
Ile ẹjọ giga to wa ni Sekondi ni idajọ yi ti ṣaaju waye pe ki wọn yẹgi fun Samuel Udoetuk Wills ati John Oji lori awọn ọmọbinrin Takoradi kan ti wọn di awati.
Adajọ Richard Adjei-Frimpong ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun tubọ fẹsẹ idajọ ile ẹjọ rinlẹ lọjọ Karun un, oṣu Kẹta, ọdun 2021.
Igbimọ adajọ ẹlẹnimeje to gbe idajọ yi kalẹ ni awọn arakunrin yi jẹbi ijinigbe ati iṣekupani awọn ọmọbinrin Takoradi mẹrin naa.
- Ọmọ ọdún kan póòrá! Àwọn èèyàn fi ìtara ba ilé ìjọsìn jẹ́
- Ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére tí wọ́n dá fún Wòlíì Sotitobire, àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ yarí
- Ọpẹ́lọpẹ́ àjẹsára, ó yẹ kí n ti kú lẹ́yìn tí àwọn jàǹdúkú ṣá mi ní àdá - Oyinkansola Elebuibon
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọlọ́mọ mẹ́jọ ká nítorí pé ọkọ rí àwọn òbí ìyàwó fín
- Gbèǹdéke ẹ̀mí gígùn àwọn ọmọ Naijiria kò ju ọdún 54 lọ - Ẹgbẹ́ àwọn dókítà
- Ta ni Ousmane Sonko, tí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ ní Senegal lẹ́yìn tí ìjọba fòfin mú u?
Bawo ni ọrọ yii ṣe ṣẹlẹ?
Iṣẹlẹ bi awọn ọmọbinrin yi ṣe di awati ni Takoradi kan araalu lominu pupọ lẹyin tawọn obi wọn fẹjọ sun lagọ ọlọpaa pe awọn n wa wọn.
Niṣe ni iwọde bẹrẹ ti awọn ileeṣẹ iroyin Ghana naa si m'ọrọ yi bẹnu lati le ri wi pe awọn ọmọ ti wọn jigbe wọn yi di awati.

Oríṣun àwòrán, Ghana Police
Lẹyin ọpọ iwadii awọn ọlọpaa ri eegun awọn ọmọ yi ninu 'soak-away'.
Ayẹwo ti wọn ṣe nipa DNA fi han pe loṣu Kẹwaa, ọdun 2020 pe aṣẹku eegun yi jẹ ti awọn ọmọbinrin ti wọn n wa ọhun.
- Fayemi: Àfàìmọ̀ kí ìjọba má bá àwọn jàndùkù ajínigbé sọ̀rọ̀, àmọ́ onímọ̀ nípa ètò àbò ní ...
- Arábìnrin lẹ̀dì àpò pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pé kó ó jí òun gbe, ọ̀rẹ́kùnrin gba 700k tán ló bá sálọ
- Ọwọ́ tẹ afurasí méjì tó nííṣe pẹ̀lú ìjínígbe Ọgá panápaná l'Eko
- Ó ṣòro púpọ̀ láti mọ ayédèrú òṣìṣẹ́ LASTMA ní ìpínlẹ̀ Eko, ṣùgbọ́n..-Agbenusọ àjọ LASTMA
- Àwọn òsìṣẹ́ ètò ìlera ti bẹ̀rẹ̀ sí ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní Naijiria, wo ìgbà tí yóò kàn ọ́
- Lọ́ọ̀tọ́ ní Sunday Igboho wá sí igbó Ire-Ekiti láti bọ Ogun lákáyé!- Akọ̀wé ìpínlẹ̀ Ekiti














