Life expectancy in Nigeria: Gbèdéke ẹ̀mí gígùn àwọn ọmọ ilẹ̀ Togo, Ghana àti South Africa dára ju ti Naijiria lọ - Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà

Lagos

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ode ṣe ri ati ibi ti eto ọrọ aje n dorikọ ti sun gbedeke ẹmi gigun awọn eeyan si ọdun mẹrinlelaadọta ni Naijiria.

Ẹgbẹ awọn Dọkita ijọba ati aladani, AGMPN, lo fidi ọrọ naa mulẹ nibi ipade awọn akọroyin kan to waye niluu Abuja.

AGMPN sọ pe igbeaye awọn eeyan orilẹ-ede bii Togo, Ghana ati South Africa ni iye lori ju ti Naijiria lọ.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Nigba to n sọrọ naa, Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Dọkita Iyke Odo sọ pe ẹnikẹni to be le rekọja iye ọdun naa ni Naijiria ti ṣe oriire.

Dokita ọhun fikun un pe ọna abayọ wa fun Naijiria ti ijọba apapọ ba le ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ti ọrọ kan lati tun Naijiria ṣe.

Lagos

Oríṣun àwòrán, @eniola_opeyemi

O ni o ṣeni laanu pe nnkan ti dẹnukọle ni Naijiria to bẹẹ to fi jẹ pe orilẹ-ede Saudi Arabia ati India lawọn ara ilu ti lọ n gba itọju ti wọn ba n ṣaisan.

Odo ṣalaye pe "gbogbo ibi ti ẹ ba de lagbeye ni iwadiiti fi han pe gbendeke ẹmi gigun awọn ọmọ Naijiria ko ju ọdun mẹrinlelaadọta lọ."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

"Ti eeyan ba le gbiyanju lati rekọja ọdun mẹrinlelaadọta gẹgẹ bii ọmọ Naijiria, o n tumọ si pe ori lo ko irufẹ ẹni bẹẹ yọ, ati pe o ti lo ju akoko to ṣeeṣe ko lo laye gẹgẹ bii ọmọ Naijiria."

Dokita naa sọ siwaju si pe gbendeke ẹmi gigun awọn ọmọ orilẹ-ede Togo ju ti Naijiria lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "gbendeke ẹmi gigun pọ ni Togo ati Ghana ju ti Naijiria lọ, bẹẹ naa lo ri ni South Africa, eyii si jẹ ibanujẹ ọkan fun awa dokita."

Lẹyin naa ni Dokita naa sọ pe ẹgbẹ awọn ti bẹrẹ eto kan lati ko biliọnu mẹwaa naira jọ lati doola ẹka eto ilera Naijiria, o si rọ awọn ara ilu lati lọwọ si eto naa.

Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy