MC Oluomo: Baba tó dàbí MC Oluomo láyé yìí kòsí, ẹni tó bá ní, ó ní ohun gbogbo- Ọmọ MC Oluọmọ

MC Oluomo ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọmọ MC Oluomo ti sapejuwe Baba rẹ, Musiliu Ayinde Adesanya ti inagijẹ rẹ n jẹ MC Oluomo gẹgẹ bi ẹni to mu iwuri ba oun ni gbogbo ọna.

Ni Oju opo ikansiraẹni Instagram ni o ti sọ ọrọ iwuri nipa baba rẹ.

O ni ọdun marun un ṣẹyin ni MC Oluomo pe awọn ọmọ si ijoko to si sọ iriri rẹ fun wọn nipa bi oun ṣe di ẹni ti oun da loni.

MC oluomo ni oun ti ṣe gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lori wọn gẹgẹ bi baba, ti oun ko si jẹ wọn ni gbese mọ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

''Ohun ti mo jẹ yin ni eto ẹkọ, eleyii ti mo si ti fun yin gẹgẹ bi ọmọ,ti ọpọ yin si ti kẹkọ jade''

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

M C Oluọmọ ni: ''E lo ẹkọ yin ati fi di eniyan nla ni ẹyinwa ọla, ki e si le e daduro fun ara yin laiwo oju baba yin''

''Nitori mi o ni ile tabi ilẹ ti ẹ fẹjogun lati ọwọ mi, mo ti fun un yin ni ogun to yẹ fun yin''

MC Oluomo ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram

Inu mi dun pe mo jẹ ọmọ Adesanya, iyẹn MC Oluomo, bi o tilẹ jẹpe ọpọlọpọ eniyan lo ma n sọrọ abuku si baba mi''

''Eniyan nla ni to n gbadura, to si ni ifẹ awọn ọmọ rẹ daradara.''

''Ẹni to ba ni MC Oluomo ni baba, ni ohun gbogbo.''

O ni ohun to ba wu awọn eeyna ki wọn maa sọ laidara nipa baba oun MC Olu ọmọ

MC Oluomo ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Google

Tani MC oluomo?

Musiliu Ayinde ti inagijẹ rẹ jẹ MC Oluomo ni Alaga ẹgbẹ awọn awakọ NURTW ni ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ojọ Kẹrinla, Ọdun 1975 ni wọn bi MC Oluomo to si fẹ iyawo mẹrin ati ọmọ mẹsan.

Laipẹ yii ni o kọ iwe to sọ nipa igbeaye rẹ, to si pe orukọ rẹ ni iṣẹ mi fun ọmọniyan, "My Service to Humanity".

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Olùkọ́ Olajide láti Ẹdẹ ló ṣàlàyé nípa Awẹ́ Gbólóhùn fún wa ní kíkún