FRSC sí àwọn awakọ̀: Ẹ kó àwọn ọkọ̀ yín tó ti dẹnukọlẹ̀ kúrò lójú popo tàbí kí a gbẹ́sẹ̀lé wọn

Oríṣun àwòrán, @DsilentG
Ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto irina oju popo, FRSC, ẹka ti ipinlẹ Anambra ti bẹrẹ si n ko awọn ọkọ ti ko dara kuro loju awọn opopona ipinlẹ naa.
Adari ileeṣẹ naa nipinlẹ ọhun, Andrew Kumapayi lo sọ ọrọ naa nibi ipade kanm pẹlu awọn akọroyin.
O ni awọn gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti wọn gba aṣẹ lati olu ileeṣẹ naa niluu Abuja pe ki wọn ko gbogbo awọn ọkọ to ti n dẹnukọlẹ kuro loju popo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ohun itiju ni irufẹ awọn ọkọ bẹẹ jẹ loju popo, nitori naa ki awọn to ba ni iru ọkọ bẹẹ ko wọn kuro loju popo tabi ki FRSC gbẹsẹle irufẹ ọkọ bẹẹ.
O ṣalaye pe "iru awọn ọkọ naa ko yẹ oju popo mọ, koda ohun itiju ni wọn jẹ."

Oríṣun àwòrán, @blueprintafric
"Lọpọ igba, awọn ọkọ bẹẹ maa n da ijamba silẹ loju popo, ti o si maa n mu ẹmi awọn eeyan lọ, ileeṣẹ wa ko ni ṣai gbẹsẹle irufẹ ọkọ bẹẹ ti a ba foju ganni wọn loju popo."
Kumapayi sọ siwaju si pe ileeṣẹ awọn yoo maa ṣe idanillẹkọọ loorekoore fun awọn awakọ kẹkẹ Maruwa.
O fi kun pe ofin to ni ṣe pẹlu Kẹkẹ Maruwa ṣi wa nilẹ ni ipinlẹ ọhun.
Lẹyin naa lo gboriyin fun ijọba ipinlẹ naa lori akitiyan rẹ lati ṣe idanilẹkọ fun awọn awakọ Maruwa ọhun.
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
- A kò san owó ìtanràn kankan látí gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin yìí- Gomina Zamfara
- Ẹ wo èrò àwọn ènìyàn lórí bí Gòmìná Akeredolu ṣe fòfin de NURTW, RTEAN nípínlẹ̀ Ondo
- Ọkùnrin méjì dèrò àhámọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀

















