No-fly zone: Garba Shehu ṣàlàyé ìdí tí Aàrẹ Buhari ṣe kéde pé kí ọkọ̀ òfurufú má fò ní Zamfara mọ́

Buari ati oko ofurufu

Oríṣun àwòrán, others

Lọjọ Iṣẹgun ni aarẹ Muhammadu Buhari kede pe ki ọkọ ofurufu ma fo mọ lori afẹfẹ ni ipinlẹ Zamfara.

O ni oun gbe igbesẹ yii lati mojuto eto aabo ẹkun naa.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Kini itumọ 'No-Fly Zone" ?

Eyi ni ikede nipa agbegbe kan ti ijọba ma paṣẹ waa le lori pe wọn ko ni le fo lori rẹ.

Eyi ja si pe ọkọ ofurufu kankan ko ni le gba ibẹ koja ni igba gbendeke asiko naa.

Awọn ologun lo maa n ni agbara lori irufẹ agbegbe bayii.

Wọn ko ni faaye gba gbogbo ọkọ ofurufu yoowu ko jẹ lati fo nibẹ.

Iru agbegbe yii maa n saaba jẹ nigba ogun tabi ti ilu tabi agbegbe naa ko ba fararọ.

Garba Shehu ṣàlàyé ìdí tí Aàrẹ Buhari ṣe kéde pé kí ọkọ̀ òfurufú má fò ní Zamfara mọ́

Olubadamọran si aarẹ Buhari lori eto iroyin, Garba Shehu ti ṣalaye idi ti Buhari fi kede pe ọkọ ofurufu ko gbọdọ fo mọ ni Zamfara.

O ni ọpọlọpọ ọkọ ofurufu aladani ni awọn kan fi maa n ko ẹru iwakusa kuro ni agbegbe yii.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Koda, O ni wọn n lo ọkọ ofurufu wọnyii lati fi ko nkan ogun ati ohun eelo iṣọṣẹ bii ibọn.

Garba Shehu tun ni wọn n fi ọkọ ofurufu aladani yii ti wọn tun fi n ji goolu ko lọ si Dubai lati ipinlẹ Zamfara.

Se iru rẹ ti ṣẹlẹ ri ni Naijiria?

Saaju asiko yii ni Olubadamọran fun eto aabo ni Naijiria nigba kan ri, Ogagun agba to ti fẹyinti Babagana Monguro kede iru ikede yii.

O ni eyi ko ṣẹyin alami ti ijọba igba naa gbọ alami pe awọn kan fẹ ṣọṣẹ ni eyi ti wọn fi kede nigba naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Olùkọ́ Olajide láti Ẹdẹ ló ṣàlàyé nípa Awẹ́ Gbólóhùn fún wa ní kíkún

Lọdun 2017 ni Baba=gana Munguno kede pe ọkọ ofurufu kankan ko gbọdọ fo kọja ni Abuja nigba naa.

Koda, o tun ti ilekun papakọ ofurufu Abuja nigba naa pa.

Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Kò sí ìwakùsà àti ìrìnàjò ọkọ̀ òfurufú mọ́ ní ìpínlẹ̀ Zamfara- Aàrẹ Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fofin de irinajo ọkọ ofurufu ni ipinlẹ Zamfara nitori ipo ti eto abo ipinlẹ naa wa lasiko yii.

Buahri

Oríṣun àwòrán, Nig Govt

Bẹẹ naa ni Aarẹ Buhari tun gbẹsẹle gbogbo ohun to jọ mọ iwakusa ni ipinlẹ ọhun.

Olubadamọran fu Aarẹ lori eto abo, ajagunfẹyinti Babagana Monguno lo fin ọrọ naa lede lẹyij ipade awọn adari ijọba to waye nile ijọba apapọ niluu Abuja.

Eyii n tumọ si pe baalu ileeṣẹ awọn ọmọ ogun nikan lo lẹtọ labẹ ofin lati fo ni ofurufu ipijlẹ naa.

Ọgagun Monguno sọ pe oju awọn wa lara gbogbo awọn ti kii ṣe oṣiṣẹ ologun nipinlẹ naa, ati pe gbogbo ohun ti yoo gba ni awọn yoo fun ki alaafia le pada si agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, #EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi

O sọ siwaju si pe gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba apapọ to n ṣiṣẹ ifimufinlẹ lo ti gbaradi lati ri pe awọn kọlọrọsi kankan ko sọ Naijiria sinu idamu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun awọn ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun lati gba iṣakoso gbogbo awọn agbegbe ti awọn oniṣẹ ibi ti n ṣọṣẹ.

Aarẹ Buhari atawọn olori ologun ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad/twitter

Àwọn aṣòfin àgbà buwọ́lu orúkọ àwọn olórí ológun tuntun

Service chiefs: Àwọn aṣòfin àgbà buwọ́lu orúkọ àwọn olórí ológun tuntun

Ileegbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti buwọlu orukọ awọn ọga agba ileeṣẹ ologun tuntun ni Naijiria.

Wọn buwọlu orukọ wọn lẹyin ti igbimọ tẹẹkoto nile naa gbe wọn kalẹ pe wọn ti wẹ yan kainkain lati jẹ aṣaaju fun awọn ẹka ileeṣẹ ọmọ ogun lorilẹede Naijiria.

Ni Ọjọru to kọja ni aarẹ ile naa, Sẹnetọ Ahmad Lawan gbe iwe ti aarẹ kọ lati fi orukọ wọn ṣọwọ si awọn aṣofin agba ka iwaju ile naa to si fun igbimọ tẹẹkoto lori aabo ni ile naa ni gbendeke ọsẹ meji lati fi ṣe ayẹwo wọn fun igbọwọle.

Àkọlé fídíò, Regent Ondo: Láti 1978 tí Bàbá mi ti jẹ Oba ni mo ti ms pé máà jẹ adelé- Magaret Omonije I

Awọn olori ileeṣẹ ologun tuntun naa niwọnyii:

Ọgagun agba (Major General) Lucky Eluonye Onyenuchea lrabor - Ọgagun agba patapata

Ọgagun agba (Major General) Ibrahim Attahiru - Olori ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Ọgagun agba oju omi (Rear Admiral) Awwal Zubairu Gambo- Olori ileeṣẹ ọmọogun ojuomi.

Ọgagun agba ofurufu (Air Vice Marshal) Isiaka O. Amao- Olori ileeṣẹ ọmọogun ofurufu.

Sẹnetọ Lawan to jẹ aarẹ ile aṣofin agba ke sawọn olori ileeṣẹ ologun naa lati tubo kara masiki gbigbogun ti igbesunmọmi ki wọn si jẹ awọn ibuba wọn run.