Shoprite : Ìfẹ̀hónúhàn bẹ̀rẹ̀ nílé ìtàjà ìgbàlódé ní Ibadan, Akure, Eko àtàwọn ìlú ńlá míràn

Shoperite

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic

Awọn oṣiṣẹ ile itaja igbalode, Shoprite, ti bẹrẹ ifẹhonuhan kaakiri awọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

Wọn bẹrẹ ifẹhonuhan naa lẹyin ti wọn fẹsun kan awọn adari ileeṣẹ naa pe wọn n gbe igbesẹ lati fa iṣakoso ileeṣẹ naa fun awọn adari miran lai jẹ ki wọn mọ bo ṣe n lọ, ati pe wọn ko san awọn ẹtọ kan fun wọn.

Awọn oṣiṣẹ naa gbe oriṣiriṣi akọle lọwọ, eyii ti wọn kọ awọn ẹdun ọkan wọn si, ti wọn si n bere pe ki awọn adari ileeṣẹ ọhun wa ṣalaye fun wọn bi ọjọ ọla wọn yoo ṣe ri ni ileeṣẹ ọhun.

Ni Eko, Ibadan, Akure atawọn ẹka Shoprite miran kaakiri Naijiria ni iwọde naa ti n waye.

Niluu Ibadan, awọn oṣiṣẹ Shoprite to wa nibẹ kọ awọn akọle bii "ọdun marun un si mẹwaa lai si igbega lẹnu iṣẹ, a gbọdọ gba owo wa ki Shoperite to salọ," ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ile itaja

Oríṣun àwòrán, Giditraffic

Lara awọn akọle ti awọn oṣiṣẹ Shoperite ilu Akure kọ ni pe o ti su wọn ki wọn maa ṣiṣe bi ẹru.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Bẹẹ naa ni wọn sọ pe ko bojumu to ki wọn ṣiṣẹ fun ọdun mẹwaa lai gba owo ajẹmọnu kankan.

Ẹwẹ, nigba to n da si ọrọ naa, alaga awọn oniṣowo ni Dugbe, iyẹn niluu Ibadan, Ọgbẹni Silvanus Obisha ni gbogbo ẹka Shoperite to wa ni Naijiria ni ifẹhonuhan naa ti n waye.

Shoperite

Oríṣun àwòrán, oyoaffairs

O ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ọhun ti gbe agagodo si ẹnu ọna Shoperite ni Ibadan ati gbogbo ẹka Shoperite miran ni Naijiria lori ẹtọ wọn ti wọn n bere fun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, gbogbo akitiyan awọn oṣiṣẹ naa lati ni gbolohun pẹlu awọn alaṣẹ ile itaja igbalode ọhun lo ja si pabo nitori wọn ko ṣetan lati ni ijiroro kankan pẹlu awọn oṣiṣẹ naa.

Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ sọ pe awọn alaṣẹ ile itaja naa ti bẹrẹ igbesẹ lati fa ileeṣẹ ọhun le awọn alaṣẹ miran lọwọ ninu oṣu Kẹrin ọdun yii.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn