Sunday Igboho: Àwọn ọmọ ogun, ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS àtawọn òṣìṣẹ́ NSCDC ló dá mi lọ́nà

Igboho

Oríṣun àwòrán, sundayigbohonews

Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọ pe igbiyanju ajọ ọtẹlẹmuyẹ ijọba apapọ, DSS, lati mu ohun ni ọna marose Ibadan si Eko jẹ akitiyan lati pa ohun.

Ajijagbara naa ni oun bọ asọ oun lẹyin ti ọkan lara awọn ọtẹmuyẹ naa lọ aṣo naa mọ oun lọrun.

Igboho lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ọgbẹni Reuben Abati lori eto kan lori redio.

O ṣalaye pe "idi ti mo ṣe bọ aṣo mi ni pe ọkan lara awọn DSS yẹn di aṣo naa mu, mo si bọ, ti mo si fi le lọwọ."

"Wọn bẹrẹ si n yinbọn nigba ti a bẹrẹ si n fa ọrọ naa, koda ohun itiju ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ yẹn jẹ fun mi."

ighoho

Oríṣun àwòrán, Oyo insight

Igboho tẹsiwaju pe ẹni iyi ni oun, ọmọ Yoruba si ni oun pẹlu, o ni ẹtọ awọn ọmọ Yoruba ni oun n ja fun, nitori naa ko yẹn ki wọn wu iru iwa bẹẹ si oun.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Sunday Igboho ni "Oniṣowo ni mi mo si n san owo ori fun ijọba loorekoore, ṣe o bojumu ki n maa lọ laarin igboro ki awọn kan si gbiyanju lati pa mi?

"Fun kinni? Kilode ti wọn ṣe fẹ gbẹmi mi?"

Ajafẹọmọniyan naa sọ siwaju si pe eto abo Naijiria ti mẹhẹ nitori bi awọn ọdaran darandaran ṣe n pa awọn eeyan ti wọn si n fi ipa ba awọn obinrin lajọṣepọ ṣugbọn ijọba ko ri nnkankan ṣe si.

O ni kaka ki ijọba da seria fun apaayan atawọn ajinigbe ni Naijiria, ni ṣe lo n fun wọn lowo to si n dun mọhurumọhuru mọ awọn awọn eeyan ilu ti ko ṣẹ.

Igboho ni akojọpọ awọn ọmọ ogun, ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS atawọn ẹṣọ NSCDC lo gbiyanju lati mu oun, to ko si ọlọpaa ninu wọn.

Bo tilẹ jẹ ajọ DSS ti sọ pe awọn ko mọwọ mẹsẹ ninu ẹsun ti Igboho fi kan awọn, ọpọ awọn ọmọ Naijiria bii ẹgbẹ Afẹnifẹre ati ati agba ọjẹ ninu imọ ofin, Femi Falana lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu igbeṣẹ naa.

Okiki Sunday igboho milẹ titi kaakiri agbaye ni ibẹrẹ ọdun yii lẹyin to fun awọn Fulani kan ni gbedeke ọjọ meje lati fi ilu Igangan silẹ lẹyin ti ọpọ eeyan ti fi ẹsun ipaniyan ati ijinigbe kan wọn.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro