Woman, Morning sex benefits: Genevieve sọ ánfáàní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù

Oríṣun àwòrán, @Genevieve
Yoruba maa n sọ pe ifẹ lakoja ofin.
Otitọ kuku ni, ko si irọ n'bẹ. Koda, ifẹ naa lo mu eeyan meji gbe inu ile kan naa.
Amọ, ọpọ gbagbọ pe Ibalopọ jẹ ọkan gboogi lara eroja ifẹ.
Eyi lo jẹ ki gbajugbaja osere tiata, Genevieve Nnaji sọ nipa anfaani to wa ninu Ibalopọ aarọ kutu loju opo Facebook rẹ.
Wọnyii ni awọn anfaani Ibalopọ aarọ kutu gẹgẹ bi Genevieve ṣe fi idi rẹ mulẹ loju opo Facebook rẹ.
- Ibi tí wóͅn ń kó oͅpoͅloͅ àwoͅn ènìyàn tó lé ní 10,000 sí rèé láti sͅewádìí ààrùn oͅpoͅloͅ
- Àwọn dókìtà tún fún ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní gbèdéke tuntun, tàbí kí wọ́n gùn lé ìyanṣẹ́lódì
- Timothy Adegoke- 'Ẹ da ẹjọ́ nù', agbẹjọ́rò Adedoyin sọ fún ilé ẹjọ́
- Oͅkùnrin kan sͅosͅo ti mo yó ìféͅ rèͅ ní Naijiria ni Wizkid - Bobrisky
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
1. Ibalopọ aarọ maa n fidi ifẹ mulẹ:
Oṣere tiata, Genevieve sọ pe lara awọn ọna lati fi ifẹ han si ọkọ tabi iyawo ẹni ni ibasun owurọ.
O ni irufẹ Ibalopọ yii lo maa n fi da tọkọ taya loju pe wọn nifẹ ara wọn.
2. Ibalopọ owurọ maa n jẹ ki ara ya gágá:
Genevieve ni ti ọkọ ati iyawo ba ni Ibalopọ laarọ ki wọn to jade nile, ara iru awọn lọkọ laya bẹẹ maa n ya gaga sulẹ ọjọ naa ni.
3. Ere idaraya to dara ni Ibalopọ aarọ kutu:
Genevieve ni idaraya to maa n jẹ ki ara gba yiga yiga ni ibasun idaji.
4. Ibalopọ maa n jẹ ki inu eeyan dun lati aarọ di alẹ
Oṣere tiata naa ni ibalopọ aarọ maa n jẹ ki awọn "hormone" to n jẹ ki ara ṣe daadaa lati aarọ di alẹ jade.
5. Ibalopọ owurọ maa jẹ ki eeyan gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin:
Genevieve ṣalaye pe Ibalopọ owurọ kutukutu kii jẹ ki eeyan ranti ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin nitori igbadun to wa níbẹ.





















