Àwọn obnìrin ilẹ̀ Gẹẹṣi ń fẹ́ kí ìjọba máa fún wọn ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wọn lára

tokotaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn obinri kan nilẹ Gẹẹsi ti ke si ijọba ilẹ naa lati fun wọn ni aye isinnmi lẹnu iṣẹ ti oyun ba bajẹ mo wọn lara ki oyun ọhun to pe oṣu mẹfa.

Lara awọn obinrin naa to ba BBC sọrọ ṣalaye pe kii ṣe ohun to rọgbọ fun awọn lati tẹsiwaju lẹnu iṣẹ wọn lẹyin ti wọn ba padanu ọmọ to wa ninu oyun.

Ọkan lara irufẹ obinrin bẹẹ, Sally Thompson sọ fun BBC pe: "Ọga mi ti mo n ba ṣiṣẹ tẹlẹ ko kọbi ara si idojukọ mi lẹyin ti mo padanu oyun mi tan."

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Bo tilẹ jẹ pe mo kọkọ maa n sunkun fun nnkan bii ogun iṣẹju ki n to wọ inu ọọfisi mi, iyẹn ko kan ọga mi, ohun to jẹ ọga mi logun ni ki n ṣaa ti ṣiṣẹ lọjọ naa ni."

Sally yii, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun ṣe igbeyawo lọdun 2017, o si ti loyun nigba mẹsan an ọtọtọ, ṣugbọn gbogbo oyun naa lo bajẹ mọ lara.

tokotay

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin gbogbo igba ti awọn oyun naa n bajẹ ni Sally n gba isinnmi lẹnu iṣẹ gẹgẹ bo ṣe yẹ ko ri, amọ isinimi naa ko to nkan.

Bẹẹ ibi gbogbo la ti n dan alẹ, ọbẹ lo kan dun ju ara wọn lọ

Àkọlé fídíò, Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Nitori ọrọ yii, ọkan lara awọn aṣofin lorilẹ-ede naa, Angela Crawley ti ṣagbatẹru abadofin kan nile igbimọ ilẹ naa to sọ pe o yẹ ki ijọba ilẹ Gẹẹsi ri oyun to bajẹ lara obinrin gẹgẹ bii adanu nla, dipo ki wọn ri bii aisan ranpẹ.

Àkọlé fídíò, Female Driver: Sokunbi ni obìnrin àwakọ̀ Dáńfó l‘Eko, tó ń lọ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíì

Crawley sọ pe "Mo ti gba oniruru lẹta lati ọdọ awọn lọkọlaya kaakiri orilẹ-ede yii lẹyin ti wọn padanu oyun tan, wọn si sọ fun mi pe kii ṣe ohun to rọrun rara."

obinrin meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Loṣu Kẹrin ọdun 2020, ijọba ilẹ naa kede isinimi fun awọn obinrin to ba padanu oyun ki oyun naa to pe oṣu mẹfa, wọn yoo si tun fun wọn lowo pẹlu.

Àkọlé fídíò, Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

Ẹwẹ, ijọba ilẹ naa ti sọ pe awọn yoo padanu owo gọbọi lati fun awọn oṣiṣẹ ni irufẹ isinnmi bẹẹ, ti awọn yoo si tun san owo fu wọn lẹyin pẹlu.

Ṣugbọn awọn ọga ileeṣẹ aladani kan ti pinnnu lati maa fun awọn oṣiṣẹ wọn to ba padanu oyun ni isinnmi, ti wọn yoo si tun san owo fun wọn fun isinnmi naa pẹlu.

Àkọlé fídíò, Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

Pupọ ninu awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi lo ṣi n reti igbesẹ ti ijọba ilẹ naa yoo gbe lori ọrọ ọhun.